In pictures: Wo bí àwọn ‘designer’ se yí kádàrá Ghana Must Go padà sí ohun àwòdamiẹnu

Oríṣun àwòrán, Obinna Obioma
Jakejado agbaye ni awọn eeyan ti mọ baagi bẹmidije alawọ omi aro ati awọ pupa taa n wi yi bi ẹni mọ owo.
Ko si fẹ si ọja to wa ni agbegbe iwọ oorun ilẹ Afrika ti wọn kii tii lo Ghana Must Go.
Isẹlẹ kan to jẹ ki o di gbajumọ ni igba ti ogunlọgọ awọn ọmọ ilẹ Ghana sa kuro ni Naijiria lẹyin ti ijọba pasẹ ki wọn pada si ilẹ wọn.
Isẹlẹ yi lo mu ki awọn eeyan sọ baagi naa ni orukọ Ghana Must Go.
- Àwọn ìwàásù akọnilẹ́nu hàà tí Prophet Israel Oladele CCC Genesis Global ti ṣe rèé
- Wòlíì míì, tún wọ gàù lẹ́yìn tó tàpá sí ìlànà béèlì tí wọ́n fún un nílé ẹjọ́
- Ṣé Sanwo-Olu, gómìnà Eko yóò farahàn níwájí ìgbìmọ̀ olùwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate?
- Wo àwọn èèkàn, ìlúmọ̀ọ́ka olórin tó ṣàbẹ̀wò sí ijọ Celestial Church ti Genesis Global

Oríṣun àwòrán, OBINNA OBIOMA
Baagi yi rọrun lati ka sapo bẹẹ naa ni o maa n gba ẹru daada.
Lati igba ti isẹlẹ yi ti waye to ti gba orukọ, awọn eeyan ko wulẹ pe lorukọ mii mọ.
Bi eeyan ba ti fẹ ra iru baagi yi lọja, "ẹ bami mu Ghana Must Go''ni wọn a maa fi juwe rẹ.
Kii si se Naijiria nikan ni wọn ti n pe baagi yi lorukọ naa.
Koda ni Ghana ti isẹlẹ yi jẹ ohun to fọwọ kan ọpọ lẹmi, Ghana Must Go ni wọn n pe.
- A kò tíì lè sọ pé ọmọ Ọba tuntun ni yóò jẹ Ooni lọ́jọ́ iwájú - Elebuibọn
- Ọkùnrin tó pe ìyàwó rẹ̀ lájẹ̀ẹ́ tì í mọ́lé fọ́dún mẹ́rin, fún un lóyún nígbà mẹ́ta!
- Èyí ni bí wọ́n ṣe pín fásitì LAUTECH láàrín ìpínlẹ̀ Oyo àti Osun
- CCC Genesis Global: Ǹkan mẹ́wàá tí ẹ ò gbọ́ rí nípa Israel Oladele, Woli ìjọ Genesis Global
Obioma to jẹ ransọ ransọ to fi New York se igbujoko sọ pe ''Mo ranti igba ti mo wa nii kekere, mo maa n beere lọwọ awọn mọlẹbi mi pe ki gan lo fa ti wọn fi n pe baagi yi lorukọ to n jẹ''
Ninu afihan isẹ ọwọ rẹ to pe ni Anyi N'Aga, to tumọ si A'n lọ lede Igbo, o tọka bi baagi yi ti se yipada kuro ni pe ka kan maa fi wọn kẹru nikan.
O ni wọn a maa fi wọn ko asa, isẹsẹ ati ajogunba itan to fi mọ isẹlẹ manigbagbe lọkan awọn to n lo.

Oríṣun àwòrán, Obinna Obioma
O darapọ pẹlu asaraloge miran torukọ rẹ njẹ Wuraola Oladapo lati peelo awọn asọ aranbara ti wọn sapejuwe wọn gẹgẹ bi adapọ aso ti ilẹ adulawọ ati toyinbo.
Ninu awọn asọ taa n wi ni a o ri ''sikẹti to jọ iro ilẹ alawọdudu wa to fi mọ gele to safihan pe awa gangan lalara gbayi da.''

Oríṣun àwòrán, Obinna Obioma
"Awọn baagi yi safihan pe ki eeyan maa se irinaja, sugbọn irinajo yi kii se ti nkan ki ko lẹmi."
O ni "bi arinrinajo ti se n re kọja ibode kan bẹẹ lo n mu nkan tuntun dani to si n fi ohun atijọ sẹyin''
Lorileede Naijiria ni wọn ti bi Obioma nibi ti baba rẹ ti kọ nipa aworan yiya pẹlu bo se n ya aworan ayẹyẹ ọjọ ibi ati awọn ode mii.

Oríṣun àwòrán, Obinna Obioma
Sugbọn lọdọ iya rẹ lo ti kọkọ gba ẹrọ ayaworan rẹ akọkọ nigba to pari ẹkọ nilẹ Gẹẹsi.
O ni ọdun toun lo nilẹ okere lo satọna bi oun ti se n fi ọgbọn ati oye ya aworan awodamiẹnu.
''Mo ri ara mi gẹgẹ bi ẹni to n fi aworan salaye iriri awọn eeyan paapa eleyi to ni se pẹlu asa, idanimọ ati ajogunba ilẹ Afrika.''

Oríṣun àwòrán, Obinna Obioma
Oju baagi Ghana Must Go ti ri to.
Lara iriri ti baagi yi farada ni pe lọdun 2017, ileesẹ ọkọ ofurufu KLM ati Air France gbegi di fifi baagi yi kẹru nitori pe yoo di aye ikẹrusi lọwọ ninu baalu.
Asẹ yii si fẹsẹ mulẹ, boti lẹ jẹ pe awọn alasẹ Ghana fajuro pe itabuku ba awọn eeyan alawọdudu to maa n fi di ẹru lọpọ igba ni igbegidina yii jẹ.

Oríṣun àwòrán, Obinna Obioma
Bẹẹ naa ni awọn eeyan ti mọ baagi Ghana Must Go mọ iwa jẹgudujẹra lasiko idibo ni Naijiria.
Bi wọn ba ni ọjẹlu kankan kowo jẹ tabi o fẹ pin owo, Ghana Must Go ni wọn maa n sọ pe wọn fi ko owo naa toun ti pe ọpọ ikowojẹ lawọn eeyan n se loju opo ayelujara ti eeyan ko si ni foju ri owo naa.

Oríṣun àwòrán, Obinna Obioma
Toun ti awọn alebu isọnu wọn yi, ọpọ ni iwọ oorun Afrika lo si n lo Ghana Must Go.
Orisirisi si ni awọ ti wọn a maa se baagi yi.
Owo ti wọn n ta baagi yii ko wọn pupọ, a si maa gba ẹru pupọ paapa nigba ti eeyan ba ti sọ ireti nu pe aye si le wa ninu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Obinna
Amọ sa Obioma lero pe o ti tasiko to yẹ ki inagijẹ Ghana Must Go yipada.
O sọ pe "Mo ni iogbagbọ pe orukọ Ghana Must Go jẹ eyi to tabuku ba awọn eeyan, kii si se awọn ọmọ ilẹ Ghana lọrọ yi kan.''
Ọrọ yi lo mu ki a wa maa beere pe orukọ wo lale pe baagi yi ti a ba yi orukọ rẹ pada abi ki a má lo baagi bẹmidije yi mọ ni?''












