Lekki Tollgate Killing: Agbẹjọ́rò kan fẹ́ kí Babajide Sanwo-Olu farahàn níwájí ìgbìmọ̀ olùwádìí láti wẹ ara rẹ̀ mọ́

Gomina Sanwo-olu lasiko abẹwo sawọn to fara gbọgbẹ nibi iṣẹlẹ Lekki Tollgate

Oríṣun àwòrán, Twitter/ babajidesanwo-olu

Gomina Babajide Sanwo-Olu gbọdọ foju han niwaju igbimọ oluwadi lori ẹhonu awọn oluwọde #EndSARS ati iṣẹlẹ ibọn yinyin lu awọn oluwọde to waye lagbegbe Lekki Tollgate l'Eko.

Agbẹjọro fun diẹ lara awọn oluwọde naa kan, Adesina Ogunlana lo sọ bẹẹ.

Amofin Ogunlana ni ileeṣẹ ologun ti ṣalaye niwaju igbimo naa pe gomina lo ranṣẹ pe awọn wa si iloro Lekki Tollgate; nitorinaa yoo ṣe pataki ki gomina naa wa wi tẹnurẹ.

Àkọlé fídíò, Tí mo ba ti múra bí ọkùnrin fi kọrin, kò sí ọ̀dọ̀ ààrẹ́ tí mi ò lè wọ̀- Erelu, ọmọ Elemure Ekiti

Labẹ ofin orilẹede Naijiria, aarẹ, igbakeji aarẹ, gomina atawọn igbakeji wọn ko lee farahan niwaju ile ẹjọ kankan tabi igbimọ to ba ni ojuṣe ile ẹjọ ninu.

Olori ọwọ kọkanlelọgọrin ileeṣẹ ọmọogun Naijiria, Ọgagun Ahmed Taiwo ṣalaye pe gomina Sanwo-Olu lo kan si ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ, Tukur Buratai pe ko ko ọmọogun lọ si Lekki Tollgate.

Amofin naa ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin kan pe o ṣe pataki ki gomina ipinlẹ Eko naa foju han o lati fihan pe lootọ lo duro ṣinṣin ninu ibọwọ fun ofin.

Amọṣa titi di bayii, gomina ko tii sọ boya yoo farahan niwaju igbimọ naa.