Queen Ereba Psoriasis: Níṣe ló dàbíi pé mo wà nínú àhámọ́ tí mi ò ṣẹ̀dá fúnra mi
Ṣe lo kan dede bẹrẹ si ni ri nkan kurukuru lara rẹ. Amọ ko si bi wọn ṣe lo gbogbo ipara ati ogun apakokoro ara to wa ni Naijiria to, ko ran an. Igba yẹn gaan lo ṣẹṣẹ wa mọ pe o ju agbara oun lọ.
Àfi ṣuuuu ti gbogbo ẹ bo ara rẹ latori de ọmọ ika ẹsẹ.
Aarun ipẹpẹ gbigbẹ lara eyi ti awọn dokita pe ni Psoriasis lo kọlu Queen Ereba.
Eyi si fa irẹwẹsi si aye rẹ tori ko si agọ ara rẹ kankan ti aarun yii ko lẹ mọ.
- Genesis Global: Ṣé lóòtọ́ ni pásítò ìjọ Celestial, Israel Oladele Ogundipe rẹ́wọ̀n hẹ?
- Adájọ́ ní Seun Egbegbe ṣì lẹ́jọ́ láti jẹ́ lórí ẹ̀sùn gbájúẹ̀
- Kíní ìtumọ̀ ''Sọ̀rọ̀ Sókè'' tí àwọn afẹ̀họ́núhàn EndSars ń lò káàkiri
- Ẹ̀mí ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò lọ tí ààrẹ Trump kò bá gbé ìpò sílẹ̀ - Joe Biden
- Báwo làwọn agbébọn ṣe rí ASP Ọlọ́pàá méjìlá jígbé lójú ìbọn?
- Ilé-ẹjọ́ yí ẹjọ́ DPO ọlọ́pàá tó ju télọ̀ sátìmọ́lé torí ó ba aṣọ rẹ̀ jẹ́ dànù
- Ìtàn ayé Abiola Peller, ọlọ́wọ́ idán tó fi ọ̀bẹ gé ìyàwó rẹ̀ sí méjì
O ro pe o ti tan fun oun laye koda wipe ala oun ko lee laye di mimuṣẹ.
Ko lee ṣe ohun gbogbo bo ṣe wu u, ko lee wọ iru aṣọ to ba yan laayo lati wọ.
Koda o ni lati pa ileewe ti nigba kan nitori aisan yii.
Queen Ereba pada di onkọwe ati ololufẹ ohun meremere. Nibi ti aarun yii ba a finra de, o ti ṣe iwe jade ti akọle rẹ n jẹ "Psoriasi, finding your light".


