Seun Egbegbe: Ipò wo ni Seun Egbegbe, Olóòtú eré wà báyìí lẹ́wọ̀n?

Oríṣun àwòrán, Nollywoodonline
Ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Eko ti fidi ọrọ mulẹ pe lootọ ni olootu ere sinima to tun jẹ gbajumọ nilu Eko, Olajide Kareem ni ẹjọ lati jẹ lori ẹsun tawọn ọlọpaa fi kan an.
Kareem ti gbogbo eeyan mọ si Seun Egbegbe loun ati awọn akẹgbẹ kan n jẹjọ niwaju adajo Oluremi Oguntoyinbo to fọwọ rọ ẹjọ ti wọn gbe wa pe awọn ọlọpaa ko lẹtọ lati fẹsun kan wọn.
Bayi adajọ ti sunjọ igbẹjọ si ọjọ kejila oṣu kini ọdun 2021 ki wọn wa bẹrẹ si ni wi awijare wọn lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Ẹsun ologoji opo ni wọn fi kan Egbegbe atawọn olujẹjọ bi tiẹ Oyekan Ayomide, Lawal Kareem, Olalekan Yusuf ati Muyideen Shoyombo.
- Seun Egbegbe lo ọdún méjì àti oṣù méje lẹ́wọ̀n láì tìí san béèlì rẹ̀
- Wo àwọn èèyàn jáńkán tó ṣe ọdún tuntun ní ọgbà ẹ̀wọ̀n
- Ilé-ẹjọ́ yí ẹjọ́ DPO ọlọ́pàá tó ju télọ̀ sátìmọ́lé torí ó ba aṣọ rẹ̀ jẹ́ dànù
- Ìtàn ayé Abiola Peller, ọlọ́wọ́ idán tó fi ọ̀bẹ gé ìyàwó rẹ̀ sí méjì
- Genesis Global: Ṣé lóòtọ́ ni pásítò ìjọ Celestial, Israel Oladele Ogundipe rẹ́wọ̀n hẹ?
Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa se sọ, awọn olujẹjọ naa lu o kere tan awọn ọgbọn eeyan to n se pasiparọ owo Bureau De Change ni gbajuẹ owo iyebiye laarin ọdun 2015 si 2017.
Agbẹjọro to lewaju ninu ifẹsun kan wọn yi Innocent Anyigor ni Egbegbe ati awọn ikọ rẹ lu awọn oni Bureau de Change ni gbajuẹ N39, 098,100, $90,000 ati £12,550 laarin ọdun meji taa n wi yi.
O ni nise ni wọn parọ fawọn wọn yi pe awọn ni owo tawọn fẹ paro tabi ti wọn fẹ ra lọwọ wọn.
Anyigor ni iwa ti wọn hu yi lodi si abala kẹjọ ofin ilẹ Naijiria ọdun 2006 eyi to nise pẹlu iwa gbajuẹ ati awọn ẹsẹ mi to farajọ to si se pe ofin yi la ijiya kalẹ fun ẹni ba tasẹ agẹrẹ sofin.
Awọn olujẹjọ naa sọ fun adajọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.















