Pigeon: Wo ìdí tí wọ́n fi ta ẹyẹlé kan ṣoṣo ní ₦893,000,000

Eyele

Oríṣun àwòrán, Reuters

Elo ni ẹyin ro pe ẹ le ri ẹyẹle ra l'ọja? Ẹyin ni kii ṣe owo gọbọi.

Amọ, ẹyẹle kan ree ti orukọ rẹ n jẹ New Kim, miliọnu ₦893,000,000 ni wọn ta ẹyẹle naa.

Kinni idi abajọ ti ẹyẹle ṣe wọn to bẹẹ?

Ara ọtọ ni ti ẹyẹle New Kim to wa lati orilẹ-ede Belgium nitori o maa n dije ninu ere sisa.

Ẹnikan to wa lati China lo ra ẹyẹle New Kim to jẹ abo ti ko si ju ọdun meji lọ.

Kurt Van de Wouwer ti ẹbi rẹ wo ẹyẹle New Kim dagba ni iyalẹnu nla ni iye ti wọn ra ẹyẹle naa jẹ fawọn.

€1.25m ni wọn ta akọ ẹyẹle ti owo rẹ wọn julọ lagbaaye tẹlẹ.

Aṣiwaju ere awọn ẹyẹle tẹlẹ, ayara bi aṣa, Armando ti wọn sọ ni orúkọ agbaọjẹ F1, Lewis Hamilton ti fẹyin ti ki wọn to ta a lọdun 2019.

New Kim gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ lẹyin to kopa ninu awọn idije ereeje kan. Ṣugbọn ẹyẹle New Kim naa ti fẹyin ti bayii.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

Gẹgẹ bi Armando, New Kim di tita lẹyin ti awọn onibara meji lati orilẹ-ede China fi obibiti duna dura lori rẹ.

Lilo ẹyẹle fun idije ere sisa ti di gbajugbaja lorilẹede China.

Àkọlé fídíò, 'Mo ní àṣírí ìyá tó fẹ́ ọmọ rẹ̀ láya fún Boko Haram torí ẹbí rẹ̀'

Awọn ẹyẹle ti wọn n kopa ninu ereeje le bimọ titi ti wọn yoo fi pe ọdun mẹwaa.

O ṣeeṣe ki ẹni to ṣẹṣẹ ra New Kim lo lati bi ọpọlọpọ ọmọ.

Awọn onimọ nipa kata kara gan an jẹri pe owo ti ra New Kim ya agbado ha sawọn lẹnu.

Àkọlé fídíò, Àṣírí tú! Ikọ̀ ìwádìí BBC ṣí àwọn tó ń jí ìkókó gbé sí gbangba

Orilẹ-ede Belgium ti jẹ gbajugbaja fún awọn ọlọsin ẹyẹle at'awọn ololufẹ ẹyẹle.

Iroyin kan tiẹ sọ pe o le ni ẹgbẹrun lọna ogun awọn ọlọsin ẹyẹle lo wa

Àkọlé fídíò, Thyroid foundation: eéwo ni mo kọ́ka pè é àṣé gẹ̀gẹ̀ ọrùn tó lé ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ni mo n