Mohammed Fawehinmi's burial: Òní ni èto ìsìnkú Mohammed ọmọ Gani Fawehinmi ní Akure

Pooropo lomije n ṣan loju awọn ero to bawọn peju sibi ti ara Mohammed Fawehinmi, to jẹ akọbi oloogbe ajafẹtọ ọmọniyan, Gani Fawehinmi, ti wọ kaa ilẹ sun nilu Ondo to jẹ ilu abinibi rẹ nipinlẹ Ondo.
Ara oloogbe ọun ni wọn bo mọlẹ lẹgbẹ aye ti wọn sinku baba ati iya-baba rẹ si nile oloogbe Gani Fawehinmi nipinlẹ Ondo.
Gomina ana nipinlẹ Ondo, Dokita Olusegun Mimiko ati alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu National Conscience Party, Tanko Yinusa, lo ṣaaju awọn eekan ilu, to fi mọ awọn ajafẹtọ ọmọniyan loriṣiriṣi, paapaa julọ awọn ọmọ igbimọ to n daabo bo ẹtọ taa mọ si CDHR nibi isinku naa.

Ninu iwaasu rẹ, Alufa Robert Steven juwe oloogbe Mohammed Fawehinmi bi ẹni to nifẹ Ọlọrun, to korira titẹ ẹtọ araalu mọlẹ, to si tun sa gbogbo ipa rẹ lati ṣe igbesoke awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ.
Dokita Olusegun Mimiko wipe oloogbe naa lo ko ipa tirẹ lati ripe idajọ ododo fẹsẹ rinlẹ lawujọ, o si ṣee ladura pe ki Ọlọrun tẹẹ safẹfẹ rere.
Idiat Fawehinmi, to jẹ aburo Mohammed lo n wami loju nibi wọn ṣe sọ ara oloogbe naa kalẹ sinu saare, to si juwe ẹgbọn rẹ bii akanda ẹda.

Ṣaaju ki wọn too sin Mohammed ni awọn ọbakan rẹ, awọn ẹbi ati awọn ọmọ igbimọ CDHR ti yipo posi oloogbe naa lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un.
Oloogbe Mohammed Fawehinmi to jẹ ọmọ ọdun mejilelaadọta lo dagbere faye lọjọ kọkanlala oṣu kẹjọ ọdun yi lẹyin to lugbadi arun Covid-19.
Gbogbo eto ti to silẹ nipinlẹ Ondo bayii lati sinku oloogbe Mohammed Fawehinmi to jẹ ọmọ Gani Fawehinmi.'O dùn mí pé Gani kò sí láyé láti gba GCON'
Ajakalẹ arun coronavirus lo ṣe iku pa ajijangbara naa.

Lana ni wọn ti kọkọ sẹ alẹ ọjọ ẹyẹ fun oloogbe naa nile ijọsin Archbishop Vining Cathedral ni Ikeja ni ilu Eko.
- Kò sí ọmọ Zambia kan tó má sùn pẹ̀lú ebi mọ́ lásìkò tèmi gẹ́gẹ́ bíi Aàrẹ- Hichilema ṣèlérí
- Báyìí tí Osun pé ọgbọ̀n ọdún, a máa yi ǹkan padà- Gomina Oyetola
- Channels TV sọ̀rọ̀ sókè lórí ìròyǹ pé DSS ti gbé òṣìṣẹ́ wọn lórí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú Ortom
- Adigunjalè kọlu ''bullion van'' tó gbówó l'Ondo fún ìgbà kẹ́rin lóṣù méjì, èèyàn méjì tún kú
- Wo ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn márùn ún tí àwọn èèyàn ilú Eko fi kan àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé ẹjọ́ sọ pé kí Lizzy Anjorin san 9.5m fún ẹni tó pé lẹ́jọ́ nítorí ọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀?
Ninu atẹjade ti mọlẹbi oloogbe fi sita ni wọn ti kilọ pe ki koowa lasiko itankalẹ ajakalẹ arun coronavirus yii.
Bakan na ni wọn gabijọba Naijiria nimọran lati mojuto eto ilera Naijiria.Ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé yóò wáyé ní Eko, Oyo, Ogun, Ondo àti ìpínlẹ̀ 30 míì láàrín ọjọ́ mẹ́ta- NiMet
Mohammed Fawehinmi jade laye lẹni ọdun mejilelaadọta.
O jẹ agbajẹrọ bii baba rẹ.
O kawe nilu Oba, leyin naa lo gba oye LLB ni 1991, 1998.
Oun ni oludari ileeṣẹ Mohammed Fawehinmi's Chambers; Director, Nigerian Law Publications Limited.
Lodun 2003 lo ni ijamba ọkọ to kan eegun ẹyin rẹ to si di ero ori kẹkẹ.
- Ẹgbẹ́ ọmọ bíbí gúúsù Kaduna tún ti sọ̀rọ̀ pé ìkọlù sí iléeṣẹ́ ológun NDA kò jẹ́ ìyàlẹ́nu
- Wo ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn márùn ún tí àwọn èèyàn ilú Eko fi kan àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA
- Ogúnlọ́gọ̀ àwọn dókítà bẹr̀ẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ l'Abuja lọ́nà àti sálọ sí Saudi Arabia
- Ẹ ṣọ́ra fún "Crate challenge" nítorí ó lè sọ yín di èrò ilé ìwòsàn- àwọn dókítà kìlọ̀
- Ìkọlù tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ ológun ní Kaduna le jẹ́ ète láti fi ìjọba Buhari ṣe ẹlẹ́yà - Garba Shehu
- Nǹkan tí a mọ̀ nípa ìkọlù tó wáyé ni Kabul















