flooding in Nigeria: NiMet kílọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ mẹ́rìnlélógún ní Naijiria

Flooding in Nigeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Naijiria, NiMet ti kilọ fun awọn ijọba ipinlẹ mẹrinlelọgbọn lati maa gbaradi fun iṣẹlẹ omiyale ti yoo waye laarin ọjọ mẹta si asiko yii.

NiMet ni o ṣeeṣe ki ojo bẹrẹ si n rọ lawọn ipinlẹ kan eyii ti ko ni da titi di ọla.

Ikede yii lo waye ninu atẹjade kan ti adari agba ajọ naa, Muntari Ibrahim, fi lede niluu Abuja.

Awọn ipinlẹ ti wọn ni iṣẹlẹ omiyale ti le waye ni Oyo, Eko, Ondo, Ogun, Edo Sokoto, Zamfara, Katsina, Kaduna, Kano, Jigawa, Bauchi, Gombe, Yobe, Kebbi.

Flooding in Nigeria

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency

Awọn ipinlẹ to ku ni Adamawa, Taraba, Kwara, , Delta, Bayelsa, Cross River, Akwa Ibom, Benue, Enugu, Ebonyi, Imo, Anambra, Abia, Rivers, Niger, to fi mọ Abuja.

NiMet ni ki ijọba awọn ipinlẹ wọnyii ṣeto itaniji fun awọn olugbe ipinlẹ wọn lori omiyale to ṣeeṣe ko waye, paapaa nipa awọn oko ti o le ba omi lọ atawọn afara to le da wo.

Àkọlé fídíò, Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell

Ajọ ọhun tun ke si awọn eeyan ilu lati ṣọra fun awọn iwa to le da kun iṣẹlẹ omiyale lagbegbe wọn.

NiMet wa parọwa si awọn ọmọ Naijiria lati maṣẹ dẹja lori ikilọ naa fun anfani ara wọn ati dukia wọn.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí