Hakainde Hichilema: Aarẹ tuntun tó ṣe ìbúra ní Zambia ṣelérí oúnjẹ mẹ́ta lójúmọ́ fún ará ìlú

Zambia

Oríṣun àwòrán, EPA

Aarẹ tuntun tó ṣe ìbúra ní Zambia ṣelérí oúnjẹ mẹ́ta lójúmọ́ fún ará ìlú.

Aarẹ Hakainde Hichilema sọrọ yii lasiko ibura wọle sipo aarẹ nibẹ.

O ni ko si ọmọ Zambia ti a tun sun lebi mọ.

Ero kun papa iṣere ni Lusaka pupọ laisko ibura na.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Bakan naa lo seleri lati ma fi aaye gba ijekuje ati awọn oni jégudu jẹra ninu ijọba lasiko ré.

Ijoba rẹ ti gori aleefa bayii leyin to ti dije fun ọpọlọpọ igba.

Àkọlé fídíò, Unijos students victims: Àwọn Fulani yabo 'hostel' wa, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Sọ́jà tí gómìnà ìpí

Eekan gboogi lara awọn oloṣelu alatako ni Orilẹede Zambia, Hakainde Hichilema ti di aarẹ orilẹede naa bayii,

Wọn si ti ṣe eto ibura fun niwaju ọpọlọpọ ero ni papa iṣire nla kan ni Lusaka tii ṣe olu ilu orilẹede naa.

Ibo to gbe Hichilema wọlẹ sipo aarẹ lẹyin ọpọlọpọ ọdun gẹgẹbi asiwaju ẹgbẹ alatako ti fun ọpọlọpọ awọn oloṣelu alatako kaakiri ilẹ Afiriki ni ireti pe bo pẹ bo ya, ọsan yoo so didun fun awọn naa pẹlu.

Wo bí Ààrẹ tuntun ní Zambia ṣe di kóríyá fún gbogbo ẹgbẹ́ alátakò ní Áfíríkà

Lasiko to fi ṣe oṣelu alatako ninu eyi to ti gbe apoti ibo ni igba marun un ọtọtọ to si mi ki o to wa di aarẹ.

Hakainde Hichilema: Ààrẹ tuntun ní Zambia di kóríyá fún gbogbo olóṣèlú alátakò ní Áfíríkà

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọgbẹni Hichilema fi oju wina wahala, ati idojukọ, koda akaimọye igba ni wọn luu bii bara, ti wọn fẹ afẹfẹ tajutaju tia-gaasi sii loju, ti wọn tilẹ tun tii mọle lọdun 2017 pe o kuna lati yago lọna fun awọn ọkọ to kọwọrin pẹlu aarẹ to fipo silẹ bayii, Edgar Lungu.

Hakainde Hichilema: Ààrẹ tuntun ní Zambia di kóríyá fún gbogbo olóṣèlú alátakò ní Áfíríkà

Oríṣun àwòrán, AFP

Wọ́n búra fún Aarẹ tuntun ní Zambia, inú ará ìlú dùn fún ìlérí tó ṣe fún wọn

Ààrẹ tuntun ní Zambia di kóríyá fún gbogbo olóṣèlú alátakò ní Áfíríkà

Nibayii ti Eleduwa gbe ise rẹ de bayii, arakunrin ti wọn ti fi igbakan ri kede gẹgẹ ọta ilu ti di ẹni wọn bura fun gẹgẹ bi aarẹ ikeje fun Orilẹede Zambia lẹyin to fagba han Ọgbẹni Lungu ninu idibo to waye ni ojọ kejila oṣu kẹjọ.

Iwuri nla gbaa lo jẹ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ alatako lorilẹede Tanzania, Tundu Lissu ṣe sọ.

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí

Ori ko Lissu yọ lọwọ awọn agbenipa lọdun 2017 lẹyin ti awọn ti ọpọlọpọ gba pe wọn jẹ agbefọba yin in ni ibọn nigba mẹrindilogun.

Lissu ni awọn ọmọ orilẹede Zambia ti jẹ ko di mimọ pe ohun to ṣe é ṣe ni lainaani ohun ti ẹgbẹ to ba n ṣe ijọba le mu awọn alatako ba la kọja.

Ọgbẹni Lissu padanu idibo aarẹ to kọja ni Tanzani eyi ti aarẹ John Magufuli to pada wa di oloogbe bori.

Hakainde Hichilema: Ààrẹ tuntun ní Zambia di kóríyá fún gbogbo olóṣèlú alátakò ní Áfíríkà

Oríṣun àwòrán, AFP

Amọṣa, Lissu ni wọn ṣe eru ibo naa ni ki o to sa fi orilẹede naa sile nigba tawọn agbofinro n gbero lati mu si ahamọ.

Kii ṣe Tanzania nikan ni afẹfẹ ireti yii fẹ de, o fẹ de Zimbabwe nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako ti n dunnu.

Àkọlé fídíò, Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell

Ninu ọrọ ikini ku oriire to kọ si oju opo ayelujara, "Zimbabwe lo kan" ni olori ẹgbẹ alatako nibẹ, Leson Chamisa kọ.

Ni Kenya ẹwẹ, iṣẹlẹ naa ti mu awọn ọmọlẹyìn olori ẹgbẹ alatako nibẹ, Raila Odinga lọkan le pe ilẹ lee rọ fun awọn lati gbin ọka si nibi eto idibo ti wọn n gbaradi fun nibẹ.

Ọgbẹni Osinga ni esi idibo aarẹ lorilẹede Zambia naa ti "fihan gbogbo Afrika pe ko si ohun ti ko ṣeeṣe