Mike Sonko: Gbogbo dúkìá Gómìnà àná náà ló jẹ́ wúrà

Mike Sonko

Oríṣun àwòrán, Instagram/mike.sonko

Yoruba ni ohun to ba wu olowo, lo n fi owo rẹ se, ara to ba si wu olowo, lo le fi owo rẹ da.

Bi igbe aye ọkunrin kan Mike Sonko se ri ree, ẹni to nifẹ wura puọ, ọpọ ohun alumọni rẹ si lo jẹ kikida goolu pọnbele.

Sonko, ti inagijẹ rẹ n jẹ Sonkoree, jẹ ọdọmọde olowo lati orilẹede Kenya, bakan naa lo si tun jẹ oloselu to gbajumọ bii isana ẹlẹta.

Ẹni ọdun marundinlaadọta ni Sonko, to si jẹ gomina keji ti yoo dari ilu Nairobi amọ ile asofin agba ilk naa yọ nipo gomina lori ẹsun iwa ọdaran ati asemase.

Mike Sonko

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Sonko

Bi o tilẹ jẹ pe ọkunrin yii lo ni owo rẹ amọ ọpọ eeyan ni ẹnu maa n ya nipa awọn dukia to jẹ kikida goolu olowo iyebiye to maa n ra.

Wọn ni isẹ, osi ati aini gogo nilẹ Afirika ati ni orilẹede rẹ pẹlu amọ ifẹ wura lo gba ookan aya rẹ.

Awọn dukia olowo iyebiye to jẹ ti Sonko ree:

Awọn mọto kiki goolu to jẹ ti Sonko

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Sonko

Àkọlé àwòrán, Mike Sonko nifẹ wura, koda ọkọ ayọkẹlẹ rẹ gan ko gbẹyin
Mike Sonko atawọn ọdọ

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Sonko

Àkọlé àwòrán, Gbogbo inu ọọfisi Sonko gan, kikida goolu ni
Mike Sonko ati ọdọ kan

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Sonko

Àkọlé àwòrán, Olowo ni yoo ku re, wura dara , o rẹwa ni ọọfisi Sonko
Mike Sonko ati obinrin kan

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Sonko

Àkọlé àwòrán, Ta lo le sọ pe wura ko rẹwa
Mike Sonko

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Sonko

Àkọlé àwòrán, Kii se obinrin nikan ni ọṣọ wura dara lara wọn, o dara lara ọkunrin pẹlu, Sonko lo fidi eyi mulẹ pẹlu ẹṣọ wura to rẹwa
Mike Sonko

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Sonko

Àkọlé àwòrán, Bi Ọba Oke ba ti fi ọkan ẹda balẹ, ẹrin ni yoo gba ẹnu rẹ
Mike Sonko

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Sonko

Àkọlé àwòrán, Ọpa to gbe asia orilẹede soke ni ọọfice Sonko gan, wura pọnbele ni
Mike Sonko

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Sonko

Àkọlé àwòrán, Ibi a ba jaye de ree o, eyi tun kasiara, Waini Sono, kiki wura ni igo rẹ
Mike Sonko atawọn eeyan kan n se ipade

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mike Sonko

Àkọlé àwòrán, Awọn ẹsọ ẹsin ti Sondo fi se ẹsọ ninu ọọfisi rẹ gan, goolu ni