Ginimbi Genius Kadungure: Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ìsìnkú Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó tó kú lẹ́ni ọdún 36

Eto isinku Ginibri

Ginimbi Genius Kadungure, ọdọmọde olowo to di oloogbe ti wọ kaa ilẹ lọ niluu abinibi rẹ, Domboshava, lorilẹede Zimbabwe.

Ẹbi atawọn ọrẹ rẹ lo peju pesẹ sibẹ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun Kadungure.

Ọjọ kẹjọ oṣu kọkanla ọdun 2020 yii ni gbajugbaja oniṣowo naa kagbako iku ninu ijamba ọkọ lopopona Liberation Legacy nibi teeyan mẹta mii ti jẹ Ọlọrun ni pe.

Àkọlé fídíò, Àṣírí tú! Ikọ̀ ìwádìí BBC ṣí àwọn tó ń jí ìkókó gbé sí gbangba

Ijamba ọhun ṣẹlẹ lẹyin ti ọkọ Kadungure lẹyin ti ọkọ rẹ kọlu awọn ọkọ mii eyi to mu ki ọkọ rẹ gbina lẹsẹkẹsẹ.

Aago mẹsan an aarọ ọjọ Abamẹta ni eto isinku rẹ bẹrẹ gẹgẹ bi ohun tawọn tawọn to wa nibẹ ṣe sọ.

Eto isinku Ginibri

Awọn eeyan wọnyii lo sọrọ nini eto isinku naa nibi ti wọn ti sọ nipa iabṣepọ wọn pẹlu Kadungure nigba aye rẹ.

Baba Ginimbi ati ẹgbọn baba rẹ, Sekuru Ginimbi wa lara awọn to sọrọ nibi isinku rẹ.

Ambuya to jẹ mama mama rẹ nitori mama rẹ gangan ti ku loṣu kinni ọdun to lọ, ati Amai to jẹ aburo mama rẹ naa sọrọ nini isinku rẹ.

Eto isinku Ginibri

Ẹgbọn lobinrin, Tete naa wa nibẹ, Mwana, Munkuru, Mukwesha, Muroora lawọn eeyan mii to tun wa nibi isinku Kadungure.

Wo iye obìnrin tó bá Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó kú àti obìnrin to ṣeéṣe kó jogún rẹ̀

Iroyin ti jade sori ayelujara nipa obinrin kan, to ṣe e ṣe ko jẹ iyawo oloogbe Ginimbi Genius Kadungure.

Gbajugbaja ọdọmọde olowo ni Kadungure, to ku ninu ijamba ọkọ kan to waye l'orilẹ-ede Zimbabwe lọjọ Aiku lẹni ọdun mẹrindinlogoji.

Ginimbi Genius Kadungure

Oríṣun àwòrán, Instagram/ginimbi

Obinrin naa, Zodwa Mkandla, ni iroyin sọ pe oun ati Ginimbi fẹ ara wọn bii lọkọ laya amọ ti wọn kọ ara wọn silẹ ki Ginimbi to jade laye.

Gbajugbaja oniṣowo ni Mkandla, to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ abaniṣeto irinajo Traverse. Ọmọ orilẹ-ede Zimbabwe ni se pẹlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin sọ pe, igbeyawo Zodwa ati Ginimbi ko han sita fun aye, titi di igba ti Zodwa duro gẹgẹ bi ẹlẹri fun Ginimbi, lasiko igbẹjọ ẹsun kan ti wọn fi kan nibẹrẹ ọdun 2020.

Iyawo Ginimbi

Oríṣun àwòrán, Instagram/zozomkandlaofficial

Àkọlé àwòrán, Amọ awọn kan tun sọ pe ọrẹbinrin rẹ lasan ni, amọ wọn jọ gbepọ ni asiko kan.

Amọ awọn kan tun sọ pe, ọrẹbinrin rẹ lasan ni, wọn ni awọn mejeeji jọ gbepọ ni asiko kan ni.

O ṣe e ṣe ki obinrin naa ju Ginimbi lọ lọjọ ori, nitori pe o ni ọmọ obinrin kan to ti pe ẹni ọdun marundinlọgbọn.

Ginibi ati Zodwa

Oríṣun àwòrán, Iharare.com

Obinrin naa ti n ṣọfọ Ginimbi lori ayelujara Instagram rẹ, pẹlu awọn fidio igbe aye ọkunrin naa.

O ni "ọrun re rẹ, ololufẹ ọkan mi. Ko si ẹnikẹni to le ni òye nkan to da wa pọ. Bẹẹni ko si ẹni to le rọpo rẹ."

Iyawo Ginimbi daro iku rẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/zozomkandlaofficial

O tun kọ sori fidio mii pe "o nira lati gbe iroyin iku rẹ mi. Ta a ni ma ma ko iṣoro mi lọ ba bayii?"

" O faramọ gbogbo kudiẹ-kudiẹ to wa ninu aye mi."

Iroyin ti a ko si le fidi rẹ mulẹ sọ pe, Zodwa Mkandla lo se e eṣe ko jogun gbogbo dukia Ginimbi, "nitori ofin ile ẹjọ to so wọn pọ lasiko igbeyawo".

Ginimbi nikan kọ lo ku ninu ijamba naa:

Kii ṣe gbajugbaja ọdọmọde olowo, Ginibi Genius Kadungure, nikan lo ku ninu ijamba ọkọ lọjọ Aiku.

Oun ati gbajugbaja arinrin-oge kan ni Zimbabwe, Michelle Moana Amuli, ati awọn meji miran lo jọ kagbako iku ojiji ninu ijamba naa.

Moana ati eeyan meji mii lo jona ninu ijamba naa.

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/MOANA_TY22

Àkọlé àwòrán, Mitchell Moana Amuli ati eeyan meji mii lo jona ninu ijamba naa.

Koda, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe, ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kẹrindinlọgbọn Moana ni wọn lọ ṣe ariya rẹ, ki wọn o to ni ijamba ọkọ.

Ile ijo 'Dreams Night Club' ti wọn ti lọ ṣe ariya ayẹyẹ ọjọ ibi Moana ni wọn ti n bọ, ki ijamba naa to waye. Gbogbo wọn lo si ku lẹsẹkẹsẹ.

Ajonaku ọkọ Rolls Royce Ginimbi Kadungure

Oríṣun àwòrán, Iharare.com

Àkọlé àwòrán, Ajonaku ọkọ Rolls Royce Ginimbi Kadungure

Awọn meji miran to tun wa pẹlu wọn ninu ọkọ Rolls Royce Wraith naa, gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Harere News ṣe sọ, ni ọmọ orilẹ-ede Malawi kan, ti wọn n wa fun ẹsun jibiti lorilẹ-ede rẹ, Limumba Karim.

Bakan naa ni obinrin kan to jẹ ọmọ orilẹ-ede Mozambique, Alichia Adams naa wa lara awọn to lugbadi iku ojiji pẹlu Ginimbi ninu ọkọ naa.

Iru eeyan wo ni Michelle 'Moana' Amuli:

Arinrin-oge 'model' ati elere idaraya ni Moana. O si jẹ gbajumọ nigboro orilẹ-ede Zimbabwe.

Moana

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/MOANA_TY22

Ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 1994, ni wọn bi. Eyi to tumọ si pe ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ni lakoko iku rẹ.

O ti fi igba kan sọ pe ọmọ atẹrọfọ dide ni oun.

Yatọ si eyi, Moana ma n jo fun olorin. Lẹyin to jo ninu awo orin gbajugbaja akọrin, Jah Prayzah, ninu oṣu Karun-un ọdun 2020, lo di ilumọọka.

O si tun farahan ninu awọn fidio fun Takura Zvemoyo, Enzo-Mwenje ati Freeman Miridzo.

Lọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ni Moana fi fidio kan sita lori Instagram rẹ, lati ṣafihan oruka edidi ifẹ olowo-iyebiye kan, pe oun ti di ẹni ọkunrin kan.

Amọ ko sọ ololufẹ ọkan rẹ, to fun ni oruka naa.

Wo bi ijamba to pa Ginimbi ati Moana ṣe waye:

Iroyin sọ pe wọn ti fi Lucky Chikwanda, ẹni to wa ọkọ ti oun ati ọkọ Ginimbi jọ kọlu ara wọn, silẹ nileewosan.

Ọkọ ayọkẹlẹ Honda yii lo fi origbari pẹlu Rolls Royce Ginimbi

Oríṣun àwòrán, Iharare.com

Àkọlé àwòrán, Ọkọ ayọkẹlẹ Honda yii lo fi origbari pẹlu Rolls Royce Ginimbi, amọ ẹni to wa ninu rẹ ye

Ibatan Lucky to ba awọn oniroyin sọrọ ni, "ere asapajude ni Ginimbi n sa, to si jẹ pe lasiko to n gbiyanju lati sare kọja ọkọ mẹta to wa niwaju, ni ọkọ kan deede duro laarin ọna, ti ọkọ Roll Royce Ginimbi si kọlu.

Oju ẹsẹ ni ọkọ Rolls Royce naa gbina.

Awọn ẹsun jibiti ti wọn fi kan Ginimbi nigba aye rẹ:

Ninu oṣu Karun-un, ọdun 2014, awọn agbofinro mu Ginimbi fun ẹsun lilu jibiti. Wọn ni o lu asofin kan, to jẹ ọmọ ẹgbẹ osẹlu Zanu-PF, Dexter Nduna, to tun jẹ oniṣowo, ni jibiti R1,581,890.

Laarin oṣu Keji, ọdun 2009 si oṣu Karun-un, ọdun 2016, wọn tun fi ẹsun jibiti mii kan Ginimbi Kadungure.

Wọn ni ileeṣẹ rẹ kan, Piko Trading Limited, parọ fun ijọba orilẹ-ede Zimbabwe lori iye to n pa wọle. O ni $2,777,678, ni oun pa wọle, amọ to jẹ pe ileesẹ naa pa ju $9,092,951.

Ginimbi

Oríṣun àwòrán, Instagram/ginimbi

Bakan naa, ninu oṣu Keji, ọdun 2018, Ginimbi sọ pe irọ ni iroyin kan to n lọ nigba naa pe, oun jẹ ọkunrin oniṣowo kan ni South Africa, Mutumwa Mawere, ni R340, 000.

Aawọ waye laarin awọn mejeeji, ti wọn si jọ tahun si ara wọn lori ayelujara idọrẹpọ Twitter, lẹyin ti Mawere sọ fun Kadungure pe, ko san nkan to jẹ oun.