Wo iye ìgbà tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti fọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Naijiria láàrin ọdún kan

Ọgba ẹwọn to wo lulẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ko din ni ẹgbẹrun marun un ẹlẹwọn to ti sa kuro ni awọn ọgba ẹwọn jakejado Naijiria lati ọdun 2020.

Eyi to waye laipẹ julọ ni ti ọgba ẹwọn Ẹlẹwọn mejila ni o ti ṣa kuro lọgba ẹwọn Kotonkarfe to wa nipinlẹ Kogi lowurọ ọjọ Aje.

Bi awọn ẹlẹwọn naa se sa kuro lọgba ẹwọn ni a ko ti le fidi rẹ mulẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọggba ẹwọn lorilẹede Naijiria (NCoS), Abubakar Umar ni, awọn ẹlẹwọn to sa kuro naa lo n reti idajọ ni ile-ẹjọ.

O ṣalaye pe ọwọ ti tẹ meji ninu wọn, ti iṣẹ si ti bẹrẹ lati mu awọn yooku.

Umar ni, ẹsọ alabo kan padanu ẹmi rẹ lasiko ti awọn ẹlẹwọn naa fẹ salọ.

Ninu atẹjade kan, Kọmisana fun eto iroyin nipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ to si ṣapejuwe iṣẹlẹ gẹgẹ bii eyi ti ko bojumu rara.

Fanwo ni ijọba ipinlẹ Kogi ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ pẹlu awọn ẹsọ alaabo lati pese aabo to yẹ ki ki irufẹ iṣẹlẹ naa ma ba a waye mọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Òjò àti ìjì líle wó ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n Suleja, ẹlẹ́wọ̀n 119 sálọ

Ko din ni ọgọrun un ẹlẹwọn to raaye salọ kuro ni ọgba ẹwọn kan to w ani ilu Suleja, nipinlẹ Niger lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024.

Awọn ẹlẹwọn naa raaye sa jade ni our mọju lasiko ti ojo nla kan rọ fun ọpọlọpọ wakati, to si wo odi ọgba ẹwọn naa.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn ni Naijiria, Adamu Duza, sọ fun awọn akọroyin nigba naa pe, ẹlẹwọn mejidinlaadọfa lo salọ.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe awọn pada ri mẹwaa ninu wọn mu pada, to si rọ awọn araalu lati fi to awọn alaṣẹ leti ti wọn ba kẹẹfin ẹnikẹni ninu awọn to salọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, asiko ti Naijiria wa labẹ isinru awọn alawọ funfun ni wọn kọ ọgba ẹwọn ọhun, awọn ogiri rẹ ko si lagbara bii ti atijọ mọ.

Minisita fun ọrọ abẹle, Olubunmi Tunji-Ojo sọ lasiko to ṣe abẹwo si ọgba ẹwọn naa pe, ẹlẹwọn mọkandinlẹẹdẹgbẹta lo wa lọgba ẹwọn naa dipo ọtalelugba o din mẹwaa ti wọn kọ ọ fun.

Ẹlẹ́wọ̀n 281 sálọ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ìlú Maiduguri

Ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024,ni ileeṣẹ to n ri si ọgba ẹwọn ni Naijiria, NCS, kede pe ẹlẹwọn 281 lawọn ṣi n wa lẹyin ti wọn salọ kuro lọgba ẹwọn ilu Maiduguri, nipinlẹ Borno.

NSC ni iṣẹlẹ naa lo waye nitori bi awọn ṣe ko awọn ẹlẹwọn kuro lọgba ẹwọn naa. Igbesẹ naa waye nitori iṣẹlẹ omiyale to mi ilu Maiduguri titi.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣe naa, Umar Abubakar fi sita lo ti sọ pe " o ṣeni laanu pe iṣẹlẹ yii ti da wahala silẹ ni bo ṣe wo ogiri ọgba ẹwọn naa, to fi mọ ile awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ọhun to wa niluu naa.

"Lẹyin ti a ko awọn ẹlẹwọn kuro ninu ọgba ẹwọn ọhun pẹlu iranlọwọ ileeṣẹ agbofinro mii, a ṣawari pe a ko ri ẹlẹwọn 281."

Abubakar fi kun pe ileeṣẹ ọhun ni gbogbo iroyin nipa awọn ẹlẹwọn naa lọwọ, eyii to fi lede ninu atẹjade naa.

Ẹlẹwọn bii 5000 lo ti sa kuro lọgba ẹwọn ni Naijiria lati ọdun 2020

Yatọ si awọn iṣẹlẹ fifọ ọgba ẹwọn to ti waye laarin ọdun kan si asiko yii, ẹ jẹ ka wo diẹ lara awọn eyi to ṣẹlẹ sẹyin.

Ọdun 2022 lo da bi ẹni pe awọn ẹlẹwọn raaye salọ ju ni ọgba ẹwọn. idi ni pe ko din ni ọgba ẹwọn marun un ti awọn ẹlẹwọn ti salọ.

Akọkọ ninu rẹ ni ọgba ẹwọn Kuje to wa niluu Abuja. Ọjọ karun un, oṣu Keje, ọdun 2022 ni eyi waye.

Ileeṣe ijọba apapọ to n risi ọrọ amojuto ọgba ẹwọn Naijiria sọ ninu atẹjade kan pe ado oloro ni Boko Haram fi fọ ẹnu ọna ọgba ẹwọn naa.

Ati pe, awọn osiṣẹ ọgba ẹwon mẹta lo farapa yatọ si ti osisẹ Civil Defence kan to ku.

O salaye pe apapọ ẹlẹwọn 879 lo salọ lẹyin ti wọn ka gbogbo ẹlẹwọn tan, ṣugbọn ọwọ ti tẹ ẹlẹwọn 443 pada.

Bakan naa nipinlẹ Delta, Kwara ati Imo, awọn ẹlẹwọn tun raaye salọ lọdun 2022.

Apọju awọn ẹlẹwọn ni ọgba ẹwọn kọọkan ni ọpọ gbagbọ pe o jẹ gboogi lara awọn iṣoro to n koju ọgba ni Naijiria.

Awọn ọgba ẹwọn mii ti ko yẹ ko gba ju ọọdunrun eeyan lọ, ni wọn n ko bii ida mẹta tabi mẹrin si bayii.

Lara awọn iṣoro ti awọn kan tun n tọka si ni bi pupọ ninu awọn ile ọgba ẹwọn ṣe ti pẹ, eyi to mu ki o rọrun fun awọn ẹlẹwọn to ba fẹ ẹ salọ lati fọ ogiri jade.