Ẹlẹ́wọ̀n méjìlá sálọ, wọ́dà kan gbẹ́mìí mì ní Kogi

Ọgba ẹwọn

Oríṣun àwòrán, Chiduben/X

Àkọlé àwòrán, Aworan yii jẹ ti ọgba ẹwọn ilu Suleja, eyi ti awọn ẹlẹwọn kan fọ lọdun 2024
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹlẹwọn mejila ni o ti ṣa kuro lọgba ẹwọn Kotonkarfe to wa nipinlẹ Kogi lowurọ ọjọ Aje.

Bi awọn ẹlẹwọn naa se sa kuro lọgba ẹwọn ni a ko ti le fidi rẹ mulẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọggba ẹwọn lorilẹede Naijiria (NCoS), Abubakar Umar ni, awọn ẹlẹwọn to sa kuro naa lo n reti idajọ ni ile-ẹjọ.

O ṣalaye pe ọwọ ti tẹ meji ninu wọn, ti iṣẹ si ti bẹrẹ lati mu awọn yooku.

Umar ni, ẹsọ alabo kan padanu ẹmi rẹ lasiko ti awọn ẹlẹwọn naa fẹ salọ.

Ninu atẹjade kan, Kọmisana fun eto iroyin nipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ to si ṣapejuwe iṣẹlẹ gẹgẹ bii eyi ti ko bojumu rara.

Fanwo ni ijọba ipinlẹ Kogi ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ pẹlu awọn ẹsọ alaabo lati pese aabo to yẹ ki ki irufẹ iṣẹlẹ naa ma ba a waye mọ.

Gẹgẹ bi o ṣe wa loju opo ileeṣẹ iroyin abẹle, Channels TV, Fanwo ni ọwọ agbofinro ti tẹ ọkan lara awọn eeyan to ṣalọ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, GLENNA GORDON/AMNESTY INTERNATIONAL

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Nnkan to ṣẹlẹ ni awọn ẹlẹwọn lo gba ori aja kan lati ti ṣalo, ti wọn ko si ba nnkankan jẹ rara.

"A ni lati ṣe iwadii lati mọ ọgbọn ti awọn ẹlẹ wọn naa lo, ri daju pe a ri awọn ẹlẹwọn naa mu ati pe a ni lati mu awọn eeyan to ṣe iranlọwọ fun wọn."

Ọgbẹni Fanwo ṣalaye pe, Gomina Usman Ododo ti kesi awọn ẹsọ alaabo lati ri pe irufẹ iṣẹlẹ naa ko waye mọ nipinlẹ Kogi.

"A n kesi awọn araalu pe ki wọn ke si wa ti wọn ba kẹfin eeyagbn ti wọn ko damọ ni agbegbe wọn.

"Ẹnikẹni to ba fi ẹlẹwọn pamọ si ile rẹ yoo ri ija ofin.

"A ko ni lati bẹru lati foya. A rọ awọn araalu lati tẹsiwaju pẹlu iṣẹ wọn, ki wọn si fọkanbalẹ pe a o pese aabo to peye fun wọn.

Eyi kii ṣe igba akọkọ ti awọn ẹlẹwon yoo sa kuro lọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria.

Ni ọdun 2020, nipinlẹ Ondo awọn janduku ja ọgba ẹwọn Okitipupa.

Oludari eto iroyin nileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle ni Naijiria lasiko naa, Mohammed ni ẹlẹwọn ẹgbẹrun meji din meje lawọn ri ka pe wọn ríbi salọ kuro lẹwọn mejeeji to wa ni ipinlẹ Edo.

Ijọba ni, yatọ sí pe wọn tu awọn ẹlẹwọn silẹ, awọn to kọlu ogba ẹwọn wọnyi tun ji nnkan nibẹ to fi mọ ibon nibi ti wọn kọ wọn si.

Bakan naa ni ọdun 2022, ẹgbẹ̀ta ẹlẹwọn lo salọ kuro lọgba ẹwọn Kuje loru mọju.