Àdó olóró ọmọ ogun Israeli pa olóri olóṣèlú Hamas ni Gaza

Oloogbe Salah al-Bardaweel ree laaarin

Oríṣun àwòrán, NurPhoto via Getty images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ado oloro ti ikọ ọmọ ogun Israeli ju lati inu ọkọ ofurufu ni Khan Younis, ti ṣeku pa olori oloṣelu Hamas ti wọn pe orukọ ẹ ni Salah al-Bardaweel.

Aṣoju kan lati ọdọ awọn Hamas lo fidi eyi mulẹ fun BBC laaarọ ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta ọdun 2025.

Awọn ara agbegbe naa ṣalaye pe yatọ si Bardaweel, ado oloro naa tun pa oloṣelu Hamas kan ati iyawo rẹ.

Awọn alaṣẹ Israeli ko ti i sọ nnkan kan lori iṣẹlẹ naa lasiko ti a n kọ iroyin yii.

Tẹ o ba gbagbe, alẹ ọjọ Iṣẹgun ni awọn ologun Israel tun bẹrẹ ikọlu to lagbara gidi si Gaza.

Wọn naka aleebu si Hamas, wọn ni awọn eeyan naa lo yi adehun jogun-o-sinmi tawọn jọ ṣe lọjọ kọkandinlogun oṣu Kin-in-ni pada, ti wọn tun nawọ gan bilisi lẹyin alaafia ti ko ti i pe oṣu meji.

Ṣugbọn Hamas naa da a pada pe ko sohun to jọ bẹẹ, awọn naa naka abuku si Isreali.

Hamas sọ pe Israeli lo yi adehun alaafia tawọn ṣe pada, eyi ti Qatar, Egypt ati US ṣe atọna rẹ, ti wọn si tun buwọlu bii olulaja fawọn.

Oṣiṣẹ kan lati ẹka ilera awọn Hamas, ṣalaye pe eeyan Palestine mejilelọgbọn ni wọn ti pa laaarin ọjọ kan kaakiri Gaza.

Ninu atẹjade kan lati ọdọ Hamas, wọn ni Bardaweel ati iyawo rẹ n ṣe adua lọwọ ni nigba ti ado oloro Israeli sọlẹ sori atibaba ti wọn wa labẹ rẹ.

Ẹka iroyin Reuters lo royin bẹẹ.

Ta a ni Bardaweel?

Oloogbe Bardaweel ti figba kan jẹ agbẹnusọ Hamas ri, o si maa n fara han lori awọn ẹka iroyin agbegbe wọn daadaa.

Ọkan lara awọn Hamas ti wọn to mẹwaa ti Isreali ti pa nigba ti ogun tun bẹrẹ pada ni Gaza lọjọ Iṣẹgun ni.

Ikọ ologun Isreali bẹrẹ ikede lati pa Hamas run latari ikọlu to ti waye lati ọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023.

Ninu ikọlu naa ni eeyan to to ẹgbẹrun kan ati igba ti padanu ẹmi, ti eeyan 251 si wa nigbekun

Gẹgẹ bi ẹka ilera Hamas ṣe wi, lapapọ, awọn Palestine to ti ba ogun yii lọ ni Gaza latigba to ti bẹrẹ, din diẹ ni ẹgbẹrun lọna aadọta (49,500).

Yatọ sawọn to ti ku, ọpọ ile lo ti di ahoro, ọpọ eeyan lo si ti di alarinkiri ni Gaza pẹlu.