Abẹ̀ṣẹ́kú-bí-òjò, George Foreman, jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abẹsẹku-bi-ojo, George Foreman ti jade laye ni ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin loke epẹ.
Idile Foreman lo kede ipapoda naa loju ọpọ ayelujara Instagram, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe ọkan wọn ku fun ọpọ ibanujẹ lasiko yii.
"Ọkan wa kun pupọ. Oni waasu rere, ọkọ, baba ati baba baba wa gbe igbaye rere to ni itumọ ko to jade laye.
"Ẹlẹyinju aanu, to gba ami ẹyẹ goolu, to tun gba ami ẹyẹ abẹsẹku-bi-ojo to da ju lagbaye ni igba meji jade laye .
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"O jẹ eeyan ti ọpọ bu ọwọ fun, ọkunrin rere ti ko ba orukọ mọlẹbi rẹ jẹ ni igbakugba."
Ọmọ orilẹede Amẹrika ni ọpọ mọ si Big George lo gbe igbeaye nla, to si se ọpọ aṣeyọri ninu iṣẹ ere idaraya Abẹsẹku-bi-ojo, to si tun gba ọpọ ami ẹyẹ bi ami ẹyẹ goolu ninu idije Olympic lọdun 1968, ami ẹyẹ abẹsẹku-bi-ojo to da ju lagbaye ni igba meji ọtọtọ- ikeji sọ di abẹsẹku-bi-ojo to dagba ju to gba ami ẹmi ẹyẹ naa ni ẹni ọdun marundinlaadọta.
O padanu ami ẹyẹ akọkọ rẹ si ọwọ Muhammad Ali ninu ija 'Rumble in the Junle' lọdun 1974.
Apapọ ija to bori jẹ mẹrindinlọgọrin, to si jẹ mejidinlaadọrun ninu wọn lo lu akẹgbẹ rẹ ni aludaku.
O fẹyin ni ọdun 1997
Ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ abẹsẹku-bi-ojo lo ransẹ ibanikẹdun si mọlẹbi, Mike Tyson ni Foreman jẹ mọnigbagbe abẹsẹku-bi-ojo ti ọpọ ko le gbegbe fun ipa ribiribi to ko lasiko to wa laye
Igba marun un ọtọtọ ni Foreman ṣe igbeyawo. O ni ọpọ ọmọ ti marun un ninu wọn si n jẹ orukọ rẹ, George.

Oríṣun àwòrán, Getty Images















