Ipa wo ni ìpinnu Dangote láti má gba náírà fún epo rẹ̀ mọ́ yóò ní lára owó ilẹ̀ wa?

Aworan mọto ti wọn n ta epo sinuu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọjọruu, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta ọdun 2025 yii ni ileeṣẹ elepo Dangote kede pe oun ti dẹkun lati maa gba owo naira lori epo to n ti ileeṣẹ naa jade.

Oju opo X rẹ ni wọn ṣe ikede ọhun si, latigba naa lo si ti n mu oju iwoye oriṣiiriṣii jade.

Ikede yii lo n waye lasiko ti ede aiyede n lọ laaarin ileeṣẹ elepo Dangote ati NNPCL to jẹ ti orilẹede Naijiria.

Ninu alaye to ṣe, Dangote sọ pe oun gbe igbesẹ yii ko ma baa si ariyanjiyan laaarin èrè ti ileeṣẹ epo oun fẹẹ jẹ ati iye to n gba lọwọ awọn to n ra epo naa.

Wọn ni eyi ṣe pataki nigba to jẹ owo dọla ni ọpọ awọn to n ra epo Dangote fi n ra a.

Ileeṣẹ Dangote sọ pe o ṣe pataki lati yi iye tawọn n ta epo pada, ki iye tawọn n ra a lasiko kan le ba tita rẹ mu.

Tẹ o ba gbagbe, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 ni ileeṣẹ Dangote tọwọ bọwe adehun pẹlu NNPCL lati maa ta epo pẹlu owo naira.

Ṣugbọn nibẹrẹ oṣu Kẹta yii, NNPCL sọ pe adehun tawọn ṣe pẹlu Dangote ko ju oṣu mẹfa lọ.

Eyi tumọ si pe adehun naa yoo wa sopin nipari oṣu yii.

Eyi ni awọn awoye si ti sọ pe yoo mu dọla wọn si i ni Naijiria ni.

Kí ni yòó ṣẹlẹ̀ sí náírà?

BBC ba Ọjọgbọn Ahmed Adamu, onimọ nipa epo bẹntiroolu sọrọ, ni Yunifasiti Nile to wa niluu Abuja lori ohun ti yoo ṣẹlẹ si naira pẹlu ipinnu Dangote.

Gẹgẹ bo ṣe wi, Ọjọgbọn Ahmed Adamu sọ pe igbesẹ Dangote yoo gbe dọla ga, yoo si ja naira lulẹ.

" Bi naira ba ja walẹ, ọwọngogo ọja yoo de si i, bẹẹ naa si ni owo epo yoo ṣe wọn si i."

Ọjọgbọn Ahmed lo ṣalaye bẹẹ.

O ni ohun ti yoo sọ boya owo epo yoo wọn si i tabi ja walẹ si i ni owo naira.

Bi naira ba ja walẹ, owo epo yoo wọn si i nile epo ni Ahmed wi.

O fi kun un pe bi wọn ṣe n ra epo lati oke okun yoo tun pọ si i niyẹn, nitori Dangote naa yoo din iye ipo to n ra lati oke okun ku.

Bakan naa ni wọn yoo tun ṣi owo ọkọ to gbe epo ọhun delẹ yii mọ iye ti wọn yoo ta a, eyi ti yoo mu afikun ba iye ti wọn n ta jaala epo kan.

Ọjọgbọn Ahmed lo ṣalaye bẹẹ.

Ọnà àbáyọ?

Aworan awọn tanka epo

Oríṣun àwòrán, NNPC

Gẹgẹ bo ṣe wi, Ọjọgbọn Adamu sọ pe ọna abayọ to wa fun iṣoro yii ni pe ki Naijiria dẹkun lilo owo naira.

"Ohun to fa iṣubu naira naa ni a le lo lati fi ṣẹgun, iyẹn naa si ni didẹkun lilo dọla. Ẹ dẹkun dọla".

O ni bi wọn ba n ṣe epo bẹntiroolu ni Naijiria, ti wọn n fọ ọ ni Naijiria, ki lo fẹẹ kan dọla ninu ọrọ.

Ọjọgbọn Adamu sọ pe ohun to fa wahala yii naa ni pe owo dọla ni wọn fi n ra epo rọbi, nitori ọja agbaye ni.

O ni ko sẹni ti yoo lọ silẹ okeere ko waa sọ fun wọn pe ki wọn maa gba naira fun epo wọn.

" Dangote funra rẹ ko ni i jere lati ara naira, afi to ba jẹ Naijiria lo fi ra epo rẹ lo ku, to ba lọ si orilẹede mi-in, wọn o ni i gba a. Dandan ni dọla, bi dọla ba si ti jẹ dandan, naira yoo maa gunke, ja walẹ naa ni."

Ọjọgbọn Ahmed sọ pe:

"Ohun ti mo ri si i ni pe ki NNPCL ati Dangote parapọ, ki wọn fi imọ ṣọkan, eyi lo le gbe naira dide to si le ja owo epo walẹ, ati ọwọngogo gbogbo nnkan. "