Bàbá onílé yìnbọn mọ́ ọmọdé tó gbá bọ́ọ̀lù sínú ọgbà ilé rẹ̀, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ

Paul Victor tí Mbamah yìnbọn lù lórí ìbùsùn nílé ìwòsàn àti agbègbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Níṣe ni ọ̀rọ̀ di gbàmí gbàmí ní agbègbè World Bank area ní ìlú Owerri, olú ìlú ìpínlẹ̀ Imo, bí bàbá onílé kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Donald Mbamah ṣe ṣíná ìbọn bolẹ̀ fún ọmọkùnrin kan tó gbá bọ́ọ̀lù sínú ọgbà ilé rẹ̀.

Bàbá náà ni wọ́n ló yìnbọn mọ́ Paul Victor, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nítorí pé ọmọ náà wọ inú ọgbà ilé rẹ̀ láti lọ mú bọ́ọ̀lù rẹ̀ tó jábọ́ síbẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹta, ọdún 2025 ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Paul ti wà ní ilé ìwòsàn Imo State Specialist Hospital tó wà ní Umuguma, níbi tó ti ń gba ìtọ́jú àmọ́ tó wà ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run.

Kí ni àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ?

Ará àdúgbò tó wà ní agbègbè náà, Justin Madu sọ pé Paul ń gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà tí bọ́ọ̀lù rẹ̀ jábọ́ sínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ bàbá náà.

"Ilé ẹ̀kọ́ bàbá náà, Per Excellence Nursery and Primary School ni bọ́ọ̀lù Paul jábọ́ sí, tó sì wọ inú ọgbà náà láti lọ mu.

"Nígbà tí Paul lọ mú bọ́ọ̀lù rẹ̀ ni Mbamah ṣàdédé yìnbọn lù ú, tí wọ́n sì sáré gbe lọ sí ilé ìwòsàn Imo State Specialist Hospital ní Umuguma.

"Níṣe ni à ń gbàdúrà kí ọmọ náà má kù báyìí."

Madu fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá láti àgọ́ ọlọ́pàá New Owerri Police Division ti nawọ́ gán bàbá onílé náà.

Ará àdúgbò míì tó sọ̀rọ̀ sọ pé, Paul kò wọ inú ọgbà Mbamah bíkòṣe pé ó gun fẹ́ǹsì ọgbà ilé náà, tó sì sọ fún bàbá náà pé kó gbé bọ́ọ̀lù òun fún òun.

"Àmọ́ dípò kí Mbamah gbé bọ́ọ̀lù fún Paul, níṣe ló lọ fa ìbọn yọ láti inú yàrá rẹ̀ tó sì yìn ín mọ́ ọn."

Olórí àwọn ọ̀dọ́ tó wà ní agbègbè náà, Kenneth Ozioma sọ pé àwọn ti lọ wo ọmọ náà ní ilé ìwòsàn, tí àwọn sì tún ti ṣàbẹ̀wò sí àgọ́ ọlọ́pàá tí bàbá náà wà.

Ó ní òun ń sa gbogbo ipá òun láti ri dájú pé àwọn ọ̀dọ́ kò dá wàhálà sílẹ̀ ní agbègbè náà nítorí pé ọ̀pọ̀ wọn ni ìṣẹ̀lẹ̀ ń bí nínú púpọ̀.

Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ?

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Imo, Henry Okoye sọ pé Donald Mbamah, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ti wà ní àhámọ́ àgọ́ ọlọ́pàá New Owerri Police Command.

Okoye sọ pé àwọn máa fa Mbamah lé àwọn ọlọ́pàá tó máa ń ṣe ìwádìí àwọn ọ̀daràn lọ́wọ́ fún ìwádìí tó péye lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó fi kun pé àwọn ń ṣiṣẹ́ láti ri ìbọn tí Mbamah yìn lu ọmọ náà gbà, tí àwọn sì máa gbe ló sílé ẹjọ́ láìpẹ́.