Tinubu búrawọlé fún Ibok-Ete Ibas bíi alákòso ìpínlẹ̀ Rivers

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti búra wọlé fún Vice Admiral Ibok-Ete Ibas gẹ́gẹ́ bí alákòso ìpínlẹ̀ Rivers.
Ní ilé ààrẹ tó wà ní ìlú Abuja, olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ìbúrawọlé náà ti wáyé lọ́jọ́rú lẹ́yìn ìpàdé ráńpẹ́ láàárín àwọn méjéèjì.
Lára àwọn tó wà níbi ètò ìbúrawọlé náà ni olórí òṣìṣẹ́ ilé ààrẹ, Femi Gbajabiamila, agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà, Lateef Fagbemi àti akọ̀wé sí ààrẹ, Hakeem Muri Okunola.
Ìbúrawọlé náà ló ń wáyé lẹ́yìn tí ààrẹ kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers tó sì ní kí gómìnà Siminalayi Fubara, igbákejì rẹ̀, àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà.
Ta ni Ibokette Ibas, ọ̀gágun ti Tinubu fi ṣe alakoso ipinlẹ Rivers?

Oríṣun àwòrán, @EmekaOjadi
Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti kede ọgagun Ibokette Ibas, gẹge bii ẹni ti yoo maa ṣakoso ipinlẹ Rivers fun oṣu mẹfa gbako.
Ikede naa lo waye lasiko ti Aarẹ kede ilu o fararọ nipinlẹ naa latari rogobodiyan oṣelu to n waye nibẹ.
Aarẹ paṣẹ ki gomina Siminalayi Fubara, igbakeji rẹ, arabinrin Ngozi Nma Odu ati ile igbinmọ aṣofin ipinlẹ naa lpe ki wọn lọ rọọkun nile.
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa ọgagun Ibas ree
Ohun to yẹ ki o mọ Ibokette Ibas
- Ibokette Ibas ni ẹnikejilelogun ti yoo di ipo olori ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi Naijiria mu, ori ipo naa lo wa titi di ọdun 2021, ki Aarẹ fi kede rẹ gẹgẹ bii alakoso ipinlẹ Rivers.
- Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹsan an, ọdun 1960 ni wọn bi ni Nko, nipinlẹ Cross River.
- O lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ Nko Primary School ati Big Qua Primary School, Calabar, ni 1971.
- Lati ibẹ o kẹkọọ ni Hope Waddell Training Institute, Calabar, laarin ọdun 1972 si ọdun 1976 ko to tun lọ si School of Basic Studies, Ogoja, ni 1977 si 1979.
- Ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 1979 lo darapọ mọ ileeṣẹ ọmọ ogun, o si kẹkọọ jade gẹgẹ bii 'sub-lieutenant' lọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 1983.
- O kẹkọọ ọmọ ogun ni Nigerian Defence Academy ko to tẹsiwaju nile ẹkọ Quaid-i-Azam University, ni Islamabad, Pakistan.
- Ibas tun kawe nipa ẹkọ Sub-Lieutenant Technical Course ni INS Venduruthy, India, laarin ọdun 1983 si 1984.
- Laarin ọdun 1997 si 1998, oun ni adari ile ẹkọ ologun Nigerian Navy Underwater Warfare School.
- O di oniruru ipo mu nileeṣẹ ọmọ ogun ki Aarẹ Tinubu to kede rẹ lanaa gẹgẹ bii alakoso ipinlẹ Rivers tuntun.















