Èyí ni àgọ́ ikú ọ̀pọ̀ èèyàn ní Mexico, pẹ̀lú bata ẹsẹ wọn tó pọ̀ lọ jàra

Bata rẹpẹtẹ ree ninu idọti, ko sẹni to ri awon to ni wọn mọ

Oríṣun àwòrán, GBJ

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ bata ẹsẹ awọn eeyan ni wọn ṣawari rẹ ni Rancho Izaguirre
    • Author, Dario Brooks
    • Role, BBC News Mundo
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Awọn egungun to ti jona ku, bata, baagi,aṣọ ati iwe idagbere kan ni awọn ajafẹtọọ kan to n wa awọn eeyan to sọnu latari rogbodiyan to n ṣẹlẹ ni Mexico, ba pade nibi kan laipẹ yii. Ohun ti wọn ṣalabapade naa si mi Mexico tìtì, o ya ilu lẹnu.

Ikọ to ṣawari awọn nnkan yii ni a mọ si Guerreros Buscadores de Jalisco (Jalisco Warriors Searchers).

Awọn ni wọn ṣawari agọ kan ti wọn lo wa fun ki wọn gba eeyan wọle sinu ibẹ ki wọn si pada pa a, eyi to wa nibujẹ ẹran Izaguirre, labule kan to wa nita ibi ti wọn n pe ni Guadalajara, ni Iwọ-Oorun Mexico.

Agbegbe yii ni wọn mọ bii adugbo awọn ileeṣẹ oloogun oloro to tobi ju ni Mexico. Jalisco New Generation Cartel (CJNG) ni wọn n pe awọn ileeṣẹ ọhun.

Loṣu Kẹsan-an ọdun to kọja ni awọn alaṣẹ ilu gba agbegbe naa ti wọn si ṣe iwadii ohun to n lọ nibẹ, ṣugbọn ẹẹkan naa ti awọn ajafẹtọọ ṣe iwadii ibẹ ni wọn ri oku awọn eeyan to ti pari aye wọn si koto nibẹ.

"A ti wọ awọn ibi to jẹ pe oogun oloro ni wọn n ṣe nibẹ ri, ṣugbọn ki i ṣe ibi ti wọn ti n kọ awọn eeyan lẹkọọ ti wọn yoo waa pada pa wọn bi eyi"

Indira Navarro, agbẹnusọ Guerreros Buscadores de Jalisco, lo sọ bẹẹ fun ẹka iroyin AFP .

Báwo ni wọ́n ṣe ṣàwárí àgọ́ ìpànìyàn?

" A ṣawari ibẹ nitori a gba ọpọlọpọ ipe latọdọ awọn ti ki i darukọ ara wọn...

A si ri oku ọpọ eeyan ti wọn ti dana sun sinu awọn sààréè.

Ọkunrin kan, Navarro, to ti n wa aburo rẹ, Jesus Hernan Navarro, to di awati ni 2015 nipinlẹ Sonora lo sọ bẹẹ.

Ninu ọrọ to ti ọfiisi olootu ijoba wá ni Jalisco, wọn sọ fun BBC pe awọn ri egungun oku awọn eeyan nibudo naa.

Awọn kan tilẹ ri àmì pe wọn dana sun wọn" ṣugbọn wọn ko ti i le sọ pato iye awọn oku naa.

Ṣugbọn ṣaa, bi wọn ṣe ri ọgọrun-un bata, aṣọ ati baagi ti wọn n gbe sẹyin ti jẹ ki ọpọ eeyan ni Mexico maa bẹru pe o ṣee ṣe ki agọ naa jẹ ibi ti ipaniyan rẹpẹtẹ ti waye.

Àlàyé ìjọba

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹnusọ ipinlẹ Jalisco , Salvador González, ṣalaye pe ẹṣọ ijọba apapọ ni Mexico ti kọkọ gbe igbesẹ to le dena iwa ọdaran lagbegbe naa loṣu Kẹsan-an, lẹyin ti wọn gba ifisun pe iwa ọdaran n lọ nibudo naa.

Eeyan mẹwaa lo ni ọwọ ofin ba nigba naa, awọn si da eeyan meji ti wọn gbe pamọ sigbekun silẹ pe ki wọn maa lọ.

Awọn yoku to wa nibẹ sa lọ gẹgẹ bo ṣe wi, nigba ti wọn koju awọn alaṣẹ ijọba.

Ikọ ẹṣọ alaabo ijọba naa tun ri oku kan, eyi to mu ki wọn tẹsiwaju ninu itọpinpin ti wọn ṣe wọ oṣu Kẹwaa.

González sọ pe ṣugbọn awọn ko ri oku kankan mọ.

Ko too waa di pe awọn ajafẹtọọ bẹrẹ iwadii tiwọn, ti wọn si ri ọpọ oku ati nnkan ara wọn nibudo naa.

"Bi a ba wo ohun ti wọn ṣẹṣẹ tu jade yii, o fi ye wa yeke pe iṣẹ ti wọn ṣe tẹlẹ ko to.

Fun idi eyi, a ti bẹrẹ iwadii kan to le jẹ ka mọ ohun to le fa ikuna, a si maa pin iṣẹ ti kaluku maa ṣe fun un." González lo sọ bẹẹ.

González fi kun un pe ko ti i si nnkan to n ṣẹlẹ nibudo naa lati ọdun to kọja tawọn ti kọkọ ṣabẹwo sibẹ. O ni o ṣee ṣẹ ko jẹ pe awọn oku to ti ku tipẹ ni awọn ajafẹtọọ naa ri

Ni bayii saa, Aarẹ Claudia Sheinbaum ti paṣẹ pe ki olootu tẹwọgba iṣẹ iwadii agọ naa ko si maa dari rẹ lọ.

Aworan ibẹ ni kikun. O ṣafihan awọn ibi ti wọn n da idọti si pẹlu awon ile kan to ta kete ti wọn fi ogiri yipo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ile kan wa Izaguirre, ṣugbọn ilẹ̀ to ṣófo lo pọ ju

Àlàyé àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́

Awọn ajafẹtọọ to ṣawari ibẹ ṣalaye pe bawọn ṣe wọle lawọn ri ọpọlọpọ awọn nnkan eelo tawọn eeyan kan lo, awọn bii bata, aṣọ ati baagi ti wọn maa n pọn sẹyin - Eyi to n tọka si pe o ṣee ṣe ki ọpọ eeyan ti gba ibẹ kọja.

"Lati ibẹrẹ, a ri ọpọlọpọ aṣọ, a ri bata, gbogbo ẹ lo si pada n ja ran-in lori ayelujara, nitori awọn eeyan fi wọn we ti atijọ, wọn fi wọn we ti oju ogun ati tibudo ipaniyan. Ibi ti wọn ti n paayan gan-an ni agọ yii, wọn si maa n gba awọn eeyan wọle sibẹ lati pa aye wọn run ni, nitori wọn ti fopin si aye awon eeyan kan nibi"

Indira Navarro lo sọ bẹẹ fun ẹka iroyin AFP.

Wọn tun ri iwe ajakọ ti wọn kọ orukọ inagijẹ awọn eeyan si, o ṣee ṣe ko jẹ orukọ awọn ti wọn ṣẹṣẹ gba wọle, wọn ri awọn fọto kan pẹlu. Bakan naa ni wọn fẹrẹ ri to ọgọrun-un apo ti wọn maa n ko ọta ibọn si.

Lafikun, ikọ ajafẹtọọ naa ri lẹta ifẹ kan ti ẹnikan kọ, eyi to ka bayii pe: "Ifẹ mi, to ba di ọjọ kan ti mi o ba de mọ, ohun kan ti mo beere fun naa ni pe ki o ṣaa maa ranti bi mo ṣe fẹran rẹ to. Ko o si maa sọ pe ibinu ati owú jijẹ mi ti lọ."

Ẹni to kọ lẹta ọhun buwọ lu u, o si kọ ọjọ ibi kan si i ati ibi ti wọn ti bi i.

Ọfiisi to n ṣoju ijọba pada fidi ẹ mulẹ, pe ẹni to kọ lẹta naa ṣi wa laye, ati pe o ti pada sọdọ awọn ẹbi rẹ lati oṣu Kẹwaa ọdun 2024.

Awọn ikọ to ri awọn egungun oku naa ree lẹnu iṣẹẹ wọn, nibudo naa ti i ṣe Izaguirre

Oríṣun àwòrán, GBJ

Àkọlé àwòrán, Awọn ikọ to ri awọn egungun oku naa ree lẹnu iṣẹẹ wọn.
Awọn baagi naa ni wọn to kalẹ yii.

Oríṣun àwòrán, FGJ

Àkọlé àwòrán, Ọfiisi Olootu ijọba Jalisco, ṣalaye pe baagi to to irinwo, bata, aṣọ lawọn ba nibudo naa
Ede Spain ni wọn fi kọ lẹta ọhun, ijọba sọ pe ẹni to kọ ọ ṣi wa layeA fragment of

Oríṣun àwòrán, GBJ

Àkọlé àwòrán, Lẹta ifẹ ti ẹnikan kan ti wọn ni ẹni ọdun mọkanlelogun ni, kọ si ololufẹẹ rẹ.

Àgọ́ ìwà ọ̀daràn

Awọn ajafẹtọọ naa sọ pe ipagọ yii ko si fun nnkan mi-in ju iwa ọdaran lọ.

Wọn ni wọn lo ibẹ fun igbaniwọle si iwa ọdaran ni.

Ibujẹ ẹran ni wọn tun pe ibẹ , ṣugbọn iwa laaabi ni wọn ni wọn n lo ibẹ fun ju.

Fun ọpọ ọdun, Guerreros Buscadores de Jalisco ati awọn ileeṣẹ mi-in ni Mexico ti tọka pe wọn maa n tan awon ọdọ wọ agọ naa, iyẹn awọn ileeṣẹ ologun oloro bii CJNG. Wọn ni iṣẹ ti yoo la owo nla lọ ni wọn fi n tan wọn wọle.

Ẹnikan to la ibudo naa kọja, to si kan si Navarro, ṣalaye pe o le lọgọrun-un awon ọdọ ti wọn ti tan wọ agọ naa ti wọn si ti fi oju wọn wina gidi.

Titi kan pe ki wọn maa ba ara wọn ja, ki wọn doju ija kọ ara wọn.

Awọn alaṣẹ sọ pe awọn ko le fidi eyi mulẹ, awọn ko si le sọ pe irọ ni, ṣugbọn wọn gba pe ibudo kan wa nibẹ lootọ to wa fun ẹkọ kikọ to si ni awọn nnkan kan ti eeyan yoo la kọja.

Awon nnkan ija wa nibẹ, aṣọ awọtẹlẹ ara wa nibẹ,ibi ti wọn n ko ọta ibọn si wa nibẹ pẹlu.

Gonzalez sọ pe akoyawo ati otitọ yoo foju han ninu iwadii agọ yii, ati pe ọfiisi oun ti gbe onka jade pẹlu fọto awọn nnkan tawọn ri, ki ẹbi awon eeyan to padanu ẹmi naa le da wọn mọ.

Ibi ti wọn to awọn èèkàn si loju ọna,ni Rancho Izaguirre

Oríṣun àwòrán, FGJ

Àkọlé àwòrán, Wọn ri ibi kan to da bii ibudo igbẹkọ ologun nibẹ.

'Kò ṣeé gbàgbọ́ pé ìjọba kò tí ì rí àṣírí yìí tẹ́lẹ̀'

Olootu ijọba Mexico, Alejandro Gertz, sọ pe ko ṣee gbagbọ pe ijọba ibilẹ ko ti i ṣawari agbegbe yii kawọn ajafẹtọọ too ri i.

"Ko see gbagbọ pe iru nnkan bayii ko ti ni i de etigbọọ awọn alaṣẹ ipinlẹ yii tẹlẹ" .

Gomina Jalisco, Pablo Lemus, naa sọ pe "Ko ti i sẹni ti yoo yọwọ ninu ọrọ yii, a maa wadii ẹ a si maa tuṣu desalẹ ikoko nipa bawọn eeyan ṣe n sọnu ni Mexico. O gbọdọ jẹ ohun to jẹ ijọba Mexico logun."

Iwe iroyin El Universal ti gbe e jade ri, pe ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin, awọn alaṣẹ Mexico ṣawari, o kere tan, iru ibudo bayii to to marun-un, ti wọn n lo lati pa awon eeyan ati fun iṣẹ laabi gbogbo, ti wọn yoo si ju oku wọn nu.

Ni 2009, Santiago Meza López, ọkan lara awọn olori Tijuana Cartel, ya awọn eeyan ilu naa lẹnu nigba to jẹwọ pe eeyan to to ọdunrun (300) ni wọn ti pa ti wọn si ti ju ara won sinuu soda to jẹ won run ni ni igberiko Tijuana.

O ti ju ọdun mẹsan-an lọ ti eyi ti ṣẹlẹ, gẹgẹ bi iwe iroyin naa ṣe sọ.

Orilẹede Mexico ti n ba a yi tipẹ, pẹlu eeyan to le lọgọrun-un kan, (110,000) ti wọn ti di awati.

Ipinlẹ Jalisco lo ni onka awọn eeyan to sọnu ju, o le ni ẹgbẹrun mẹẹẹdogun (15,000) ti wọn di awati, gẹgẹ bi akọsilẹ ijoba ibilẹ ibẹ ṣe sọ.

Ni bayii, awọn eeyan ti n wo fọto ati akosilẹ awọn eyi ti wọn gbe jade lati Izaguirre, boya wọn yoo gbabẹ tọpasẹ awọn ẹni wọn to ti lọ.

"A n bẹbẹ pe ki wọn ba wa ṣe iwadii yii bo ṣe yẹ. Iṣẹlẹ yii ya wa lẹnu pupọ, awa nikan si kọ lo ya lẹnu, mo ro pe gbogbo aye ni yoo jọ loju."

Navarro lo sọ bẹẹ.