Nọ́ọ̀sì tó gùn Mohbad ní abẹ̀rẹ̀ ṣàlàyé ohun tó wáyé fún Ilé ejọ̀

Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Nọọsi to fun gbajugbaja olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba, ẹni ti ọpọ mọ si Mohbad ni abẹrẹ ṣaaju ko to jade laye, Feyisayo Ogedengbe, ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri nigba to de si ile oloogbe naa pe ko wa fun ounni abẹrẹ.

Ogedengbe sọ fun adajọ ile ẹjọ Taofikat Adedayo Shotobi pe oun kawe gboye ni ile ẹkọ nọọsi ti ile iwosan Cornerstone, Akute, nipinlẹ Ogun State laarin ọdun 2014-2017, to si tun sisẹ fun ile iwosan kan fun ọdun kan ko to di pe oun kuro ni agbegbe naa.

O ni lọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023, ọkan lara awọn onibaara rẹ, Ayobami Sodiq, ti wọn n pe ni Spending ransẹ pe oun lati wa fun eeyan kan ni abẹrẹ kokoro 'Tetanus' to ri pe o ṣeṣe ni ọwọ.

Ogedengbe ni oun ko ri aye lati darapọ mọ awọn to ransẹ pe oun nitori sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to pọ lọjọ naa ṣugbọn oun lọ ni ọjọ keji, ti oun si lọ pade Mohbad ni Orchid to wa ni agbegbe Lekki.

Nọọsi naa jẹ ko di mimọ pe oun ko mọ pe Mohbad ni oun fẹ lọ ba titi toun fi de ile naa, toun si ri pe ile Mohbad ni.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ri Mohbad ninu yara ni ile naa pẹlu awọn eeyan mii bii iyawo oloogbe ati ọrẹ rẹ Ayobami.

O jẹri pe abẹ ọwọ ọtun Mohbad wu, ti oun si fun ni abẹrẹ tetanus ni apa rẹ.

Ogedengbe ni oun bere lọwọ Mohbad pe ṣe o ni aisan ọgbẹ inu, to si dahun pe bẹẹni, oun si pinnu lati ma fun ni abẹrẹ 'diclofenac,' ti oun si fun ni abẹrẹ paracetamol.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ogedengbe ṣalaye pe "Mo fun Mohbad ni abẹrẹ 4ml paracetamol ati 1ml omi, ti apapọ rẹ si jẹ 5ml, eyi to jẹ pe ohun lo dara fun agbalagba, mo tun fun ni abẹrẹ intravenous (lati ibi iṣan rẹ).

"Mo po abẹrẹ ceftriaxone 10ml pọ, ti mo si n fun ni diẹdiẹ."

Nọọsi naa ṣọ siwaju si pe "Mo ṣalaye fun Mohbad ati iyawo rẹ pe abẹrẹ paracetamol ati ceftriaxone wa fun ara riro ti yoo si koju awọn kokoro ara rẹ amọ ara Mohbad ko balẹ mọ nitori ọwọ rẹ ti wu.

"Nigba to n gba abẹrẹ ceftriaxone – o ti gba to 2ml – Mohbad ni oun fẹ bi. O ya mi lẹnu ṣugbọn bi o ṣe n ṣe niyẹn, mo yọ abẹrẹ naa, to si lọ bi, o pada de, to si jokoo si ilẹ ninu yara.

"Nigba ti Mohbad pada de lati ile igbọnsẹ, nibi to ti lọ bi, o jokoo si ilẹ, mo ri pe ara rẹ n dide. Eyi ya mi lẹnu, ti mo si fi han iyawo rẹ, to si ni bi o se ma n ṣe niyẹn to ba ti gba abẹrẹ, pe ti a ba da omi si lori, ara rẹ yoo balẹ.

"Iyawo mu lọ sinu ile iwẹ, to si bẹrẹ si ni da omi si lori, asiko yii ni o sọ fun ọrẹ rẹ Ayobami pe ki awọn wa bi ti wọn ti n ta oogun nitosi.

"Ko si ọkọ kankan ninu ile naa lati gbe iyawo ati Ayobami lọ si ibi ti wọn ti n ta oogun."

O ṣalaye pe nigba ti awọn de ibi ti wọn ti n ta oogun, awọn ko ri abẹrẹ hydrocortisone ati Normal Saline infusion, ti awọn si ni lati sa lọ si ile oogun mii pẹlu Ayobami nigba ti awọn o rira nibi ti akọkọ.

"Nigba ti a de si bi ile itaja oogun keji, a ri abẹrẹ hydrocortisone ati Normal Saline infusion, ni bayii, aago mẹta ti lu. Ayobami n gba ipe, ti mo si gbọ nigba to ni wọn ni Mohbad n gbọn. Mo sọ fun ko sọ fun ẹni to pe lasiko naa pe ki awọn ma gbe Mohbad lọ si ile iwosan,"

"Nigba ti emi ati Ayobami de pada si ile Mohbad, wọn ti gbe Mohbad sita, ti a ko si le fun ni abẹrẹ hydrocortisone ati Normal Saline infusion mọ.

"Ni bayii, n ko le pada si ile Mohbad mọ nitori gbogbo eeyan ti wa ni ita, ti wọn si ti fẹ gbe lọ si ile iwosan ni kiakia."

"Mohbad ko gbọn nigba ti mo wa nibẹ tabi nigba ti mo de pada si ile naa"

Nọọsi naa tẹsiwaju pe "Mohbad ko gbọn nigba ti mo wa nibẹ tabi nigba ti mo de pada si ile naa. Ko si ọkọ ni ile Mohbad lati gbe wa lọ si ile iwosan, ti eeyan kan to n gbe pẹlu Mohbad si ya wa ni ọkọ lati gbe lọ si ile iwosan,"

"Sunkẹrẹfakẹrẹ wa loju ọna ni ọjọ naa, ti a si ni lati gbe sori ọkada pe ko fi le tete de ile iwosan. Mo ni lati bọ silẹ, ma saare tẹle wọn. O gba wa ni ogun isẹju lati de si ile iwosan akọkọ.

"Nigba ti a de si ile iwosan akọkọ, awọn oṣiṣẹ ilera to wa nilẹ ko fẹ da wa lohun, ti eyi si fẹ fa ija ṣugbọn wọn pada fun ni CPR. Lẹyin eyi ni dokita ni oku Mohbad ni wọn gbe wọle. Eyi bami lẹru."

Ogedengbe ni lẹyin eyi ni bi ago mẹsan an alẹ, wọn lọ si agọ ọlọpaa lati lọ fi iṣẹlẹ naa to wọn leti, ti wọn si bere lọwọ agbẹjọro Mohbad ati Ayobami pe se wọn fẹ pe mi lẹjọ abi wọn fẹ ki wọn se iwadii. Wọn dahun pe wọn ko ti le sọ lasiko naa.

Lẹyin to ro ẹjọ tan ni agbẹjọro idile Mohbad, Wahab Shittu, agbẹjọro iyawo Mohbad, Kabir Aakingbolu ati agbẹjọro ijọba bere awọn ibeere lọwọ rẹ.

Ile ẹjọ ti sun igbẹjọ naa si ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2025.