Wo àwọn ọ̀nà tí o lè fi dáàbò bo ara à rẹ lọ́wọ́ ooru àmújù tó gbòde

Ọkùnrin tó ń mu omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Láìpẹ́ yìí ni àjọ tó ń rí sí ojú ọjọ́ ní Nàìjíríà, ìyẹn Nigerian Meteorological Agency, NiMET ti ṣèkìlọ̀ pé ooru àmújù yóò wáyé láwọn ìpínlẹ̀ mọ́kàndínlógún.

NiMET nínú àtẹ̀jáde kan sọ pé ìpínlẹ̀ Kwara, Oyo, Kogi, Kebbi, Nasarawa, Niger, Benue, Enugu, Anambra, Abia, Ebonyi, Cross River, àti Abuja ni ooru àmújù náà yóò ti wáyé jùlọ.

Bákan náà ni wọ́n tún ka Taraba, Adamawa, Plateau, Sokoto, Kaduna àti Zamfara.

Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìnira ni ooru àmújù yìí máa ṣokùnfà, tí wọ́n sì rọ àwọn èèyàn láti gbáradì fún ìpèníjà náà.

Àjọ náà sọ pé ooru yìí le fa àwọn ìpèníjà ìlera, tí wọ́n sì gba àwọn èèyàn níyànjú láti máa wà níbi tó bá tutù lásìkò yìí.

Wo àwọn ọ̀nà tó lè fi móríbọ́ lọ́wọ́ ooru àmújù

Àbọ̀ ìwádìí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ́dún tó kọjá ti fi hàn pé àyípadà ojú ọjọ́ èyí táwọn èèyàn ń ṣe okùnfà rẹ̀ ló ń fa ooru àmújù tó ń wáyé lẹ́kùn ìwò oòrùn Africa.

Àwọn onímọ̀ náà sọ pé táwọn èèyàn kò bá dẹ́kun àwọn ìwà tó ń fa àyípadà ojú ọjọ́, ooru àmújù yóò máa lékún ní ọdún méjì méjì ni ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Africa.

Àwọn nǹkan tí o lè ṣe láti dá ààbò bo ara à rẹ lọ́wọ́ ooru àmújù nìyí:

  • Máa mu omi dáadáa lóòrèkóòrè lásìkò yìí
  • Gbìyànjú láti máa sinmi sí ibi tó bá tutù
  • Má dúró tàbí fi àwọn ọmọdé sínú ọkọ̀ lábẹ́ oòrùn
  • Máa wọ àwo ojú láti dá ààbò bo ẹyinjú rẹ̀ nígbà tí o bá fẹ́ jade nínú oòrùn
  • Aṣọ tó fẹ́lẹ́ ni kí o máa wọ̀ jade lásìkò yìí láti dènà ooru àmújù
  • Ti ibi tí o bá ń lọ kò bá ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀, dènà jíjáde nílé lásìkò tí oòr]un bá fẹjú púpọ̀