Ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn Ààrẹ pa aráàlú, awakọ̀ sá lọ

Aworan awọn to n lọ loju popo

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọmọ orilẹede Gẹẹsi kan lo ti pade iku ojiji nigba ti ọkan ninu ọkọ to n tẹle Aarẹ Kenya, William Ruto, gba a, ti awakọ naa si tun ṣalọ.

Ọkunrin oloogbe naa to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgọrin, Edgar Charles Frederick, lo padanu ẹmi rẹ lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye ni oju ọna kan niluu Nairobi to jẹ olu ilu orilẹede Kenya.

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ dẹrẹba ọkọ naa, ti wọn si tun ti gba beeli rẹ pe ko ma lọ si ile.

Wọn ni o n wa ọkọ to n pese iranlọwọ fun irinajo aarẹ Ruto.

Gẹgẹ bii ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, awọn ọkọ to n gbe aarẹ ti lọ saaju ki iṣẹlẹ naa to waye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Michael Muchiri sọ fun BBC pe oloogbe Frederick ti ma n wa si orilẹede Kenya lati wa ri ọmọ iya rẹ obinrin to n gbe ni ilu naa pẹlu ọmọ rẹ.

Iṣẹlẹ yii ni wọn ti fi to awọn ẹbi oloogbe leti, ti gbogbo eto yoo si waye ni ọjọ Ẹti.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni dẹrẹba naa to kọ lati duro lẹyin iṣẹlẹ naa yo foju ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.

Iṣẹlẹ yii lo ti fa ọpọ rogbodiyan lori ayelujara, ti ọpọ si n bu ẹnu atẹ lu bi ọkọ to n tẹle aarẹ se pọ ni apọju.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ọkọ to n tẹle aarẹ tabi igbakeji yoo sekupa eeyan koda igba kan wa ti awọn eeyan to n tẹle aarẹ padanu ẹmi wọn.

Awọn eeyan kan gbagbọ pe iṣẹlẹ yii ni o ri ọpọ ariwo nitori oloogbe naa jẹ ajoji, paapaa lati orilẹede Britain.