Wo bí ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìkówójẹ tí wọ̀n fi kan gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara tẹ́lẹ̀, Ahmed, ṣe lọ n'Ilorin

Abdulfatah Ahmed

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbẹjọ Gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed ati kọmisọnna fun eto iṣuna labẹ isejọba rẹ, Ọgbẹni Demọla Banu, tẹsiwaju loni Ọjọru, ni ile-ẹjọ giga to wa niluu Ilorin, olu-ilu ipinlẹ Kwara.

Abdulfatah Ahmed ṣe gomina nipinlẹ Kwara laarin ọdun 2011 si 2019.

Ajọ to n ri si iwa jẹgudujẹra, EFCC lo wọ awọn mejeeji lọ sile ẹjọ fun ẹsun sise owo Universal Basic Education Commission (UBEC), iyẹn ajọ to n mojuto eto ẹkọ alakọbẹrẹ, to to N5.78 billion mọkumọku laarin ọdun 2013 si 2019 ti wọn wa ni ijọba.

Ni ibẹrẹ igbẹjọ naafun , Akọwe Agba Kwara State Universal Basic Education Board (SUBEB) ni asiko naa, Ọgbẹni Dasuki to jẹ ẹlẹri fun ajọ EFCC, sọ pe, Gomina Abdulfatah Ahmed, ya owo UBEC lati san owo osu osisẹ laarin awọn ọdun yii.

O sọ eyi nigba ti agbẹjọro awọn olujẹjọ, ọgbẹni Jimoh Mumini (SAN) n fọrọ waa lẹnu wo.

O ni awọn ohun ti awọn salaye fun ajọ UBEC lati fi owo naa se ni kikọ yara ikẹkọọ to le ni ogoji pẹlu ọfisi, kikọ ile igbọnsẹ igbalode to jẹ ogoji, ati pipese aye fun imọ ẹrọ (ICT Centers) kaakiri ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ ati girama ipele kinni de ẹkẹta to wa ni ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni ipinlẹ Kwara.

Ọgbẹni Dasuki fi kun-un pe, o ṣe , nitori pe ọpọ ninu awọn ohun elo yii ni ko jẹ sise nitori pe wọn ti gbe owo naa gba ibomii lọ

Dasuki ni koda, ọpọ agbasẹse ni wọn fẹhonu han fun airowogba lori isẹ ti wọn ti ṣe pari.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Dasuki sọ pe awọn olujẹjọ mejeeji fi da awọn loju pe wọn yoo san owo naa pada sugbọn wọn o mu ileri wọn sẹ.

O ni awọn o gbe owo naa jade fun gomina ana ọun ati Kọmisọnna naa, sugbọn awọn gbee jade lati san owo awọn osisẹ ni gẹgẹ bi wọn ṣe see lalaye.

Dasuki ni SUBEB ni igbimọ, ti oun si si jẹ ara Igbimọ naa, gẹgẹ bii Akọwe Agba SUBEB.

O ni gomina ana naa ati kọmisọnna rẹ kii se ara igbimọ naa, pe wọn ko lee jẹ ara wọn gẹgẹbi bi o se wa ninu ofin to gbe SUBEB kalẹ.

Lẹyin naa ni awọn olujẹjọ mejeeji sọ fun ile-ẹjọ pe awọn o jẹbi ẹsun naa.

"Owo to le ni bilionu kan naira ni ọdun 2013, N952 million, N869 million and N973 million ni ọdun 2015 ati 2016, ni ajọ SUBEB, san si akanti asayan kan ni ile ifowopamọ si Skye.

Ẹlẹri naa to tun jẹ afurasi si ajọ EFCC sọ pe ijọba Kwara nigba naa bere fun gbigba owo naa kuro ni akanti ile ifowopamọsi Skye naa gẹgẹ bi ẹyawo (loan) lati fi san owo osu awọn osisẹ.

"Nigba ti wọn beere fun owo naa lati fi san owo osisẹ, a o gba lakọkọ sugbọn nigbati ti a ri aridaju sisan nipasẹ owo to n wọ Kwara lati apo ijọba apapọ ni Abuja, a gba lati fun wọn.

"Alaga SUBEB, nigba naa, Ọgbẹni Lanre Daibu beere fun akọọle gẹgẹ bi iwe adehun, ọfisi kọmisọnna si se bẹ gẹgẹ, lẹyin naa la fi owo naa ransẹ si akanti ijọba, ilana yii si tẹsiwaju ni awọn ọdun to tẹ lee"

"Ni ọdun 2016, lotitọ ni ajọsọ wa laarin UBEC ati ijọba Kwara, sugbọn a o gba esi kankan lori bi wọn ṣe na owo naa"

Abdulfatah Ahmed sọ pe awọn san owo naa pada sugbọn akọwe agba naa tako ọrọ yii.