Wo ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ tí Mercy Chinwo fi kan VDM

Oríṣun àwòrán, Very Dark Man/ Mercy Chinwo/Facebook
Ile ẹjọ kan to n jokoo niluu Abuja ti paṣẹ pe ki awọn agbofinro lọ mu Martins Vincent Ose, ẹni ti ọpọ mọ si Very Dark Man, lẹyin to kọ lati farahan ni ile-ẹjọ lori ẹsun ti gbajumọ olorin ẹmi, Mercy Chinwo fi kan an.
Ẹsun ibanilorukọjẹ ni Mercy Chinwo fi kan VDM.
Ẹjọ naa lo wa ni iwaju Onidajọ Emmanuel Iyanna to jẹ adajọ agba magisireeti ilu Abuja, to si ransẹ pe VDM ni ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta ọdun, 2025 pe ko farahan ni ile-ẹjọ lati wa wi tẹnu rẹ.
Agbẹjọro rẹ, Deji Adeyanju sọ fun ile-ẹjọ pe onibaara oun ko si ni orilẹede Naijiria lọwọ yii ni ko fi yọju si ile ẹjọ.
Saaju ijoko ile ẹjọ, Adeyanju sọ fun akọroyin BBC pe, VDM wa ni orilẹede China, ti ko si ni yọju si ile-ẹjọ rara.
Bakan naa ni o fẹsun kan agbẹjọro Mercy Chinwo, Pelumi Olajengbesi pe oun n se mọdaru lori aisi nile VDM bẹẹ lo si mọ pe VDM ko si ni ile lọwọ yii.
Lasiko igbẹjọ, Adeyanju sọ fun ile ẹjọ pe awọn olupẹjọ ko fi iwe to yẹ ransẹ si onibaara rẹ, to si jẹ pe nigba ti iwe ko wa yọju si ile-ẹjọ de ọwọ VDM, o ti n gbaradi fun lilọ orilẹede China
O fi iwe irinajo han adajọ to jẹ ti VDM lati fi idi rẹ mulẹ pe ko si ni orilẹede Naijiria lasiko naa.
Alaye yii ni ko dun mọ adajọ ninu, to si ni orukọ VDM ko si ninu iwe ti agbẹjọro ṣafihan ni ile-ẹjọ pe o fi rin irinajo.
Adajọ ni ẹri ọhun ko to lati sọ pe VDM ti rin irinajo kuro ni orilẹede Naijiria.
Eyi lo jẹ ki adajọ palaṣẹ pe ki awọn agbofinro lọ mu VDM, ki wọn si pese rẹ lasiko igbẹjọ to n bọ.
Adeyanju rawọ ẹbẹ si adajọ pe oun ṣetan lati mu onibaara rẹ wa fun ara rẹ ṣugbọn Adajọ Iyanna yari.
Ki lo fa yanpo-yanrin laarin VDM ati Mercy Chinwo?
Ninu iwe to kọ ransẹ si ile-ẹjọ, Mercy Chinwo sọ pe VDM fẹsun kan oun lori ẹrọ ayelujara rẹ pe, oun ko owo $345,000 to wa laarin oun ati mọnija rẹ tẹlẹ, Ezekiel Onyedikachukwu jẹ, ẹni ti ede aiyede wa laarin awọn mejeeji.
O fi ọpọ ẹri han ile-ẹjọ, eyi to ṣafihan pe gbogbo nnkan ti VDM sọ lo jẹ irọ, ti irọ naa si baa lorukọ jẹ ni igbooro aye.
Agbẹjọro rẹ, Pelumi Olajengbesi ni iwa yii tako ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 2015 nipa lilo ori ayelujara.
Eyi ni ọkan ninu ẹsun meji ti Chinwo fi kan VDM.
Ikeji lo wa niwaju ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Abuja nibi ti Chinwo ati awọn agbẹjọro rẹ ti n bere biliọnu kan naira lọwọ VDM fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.
Bakan naa ni Chinwo fẹ ki ile-ẹjọ palaṣẹ fun VDM pe ko tọrọ aforijin lọwọ oun ninu iwe iroyin, ko si ṣe e fun ọjọ mẹrinla.















