'Ariwo ọjà lásán ni ìròyìn tó n lọ nípa èmi àti Odunlade, nnkan tó pa wá pọ̀ rèé'
Gbajumọ oṣerebinrin, Eniola Ajao, ti sọrọ lori iru ibaṣepọ to wa laarin oun ati oṣerekunrin, Odunlade Adekola.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba, ni Arabinrin Ajao, ti tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ lori bi oun ati Adekola ṣe pade, bo ṣe bẹrẹ iṣẹ tiata ni ṣiṣe, ati bi irinajo rẹ ṣe ri lati igba naa.
Arabinrin Ajao sọ pe Fasiti ilu Eko, Unilag ni oun wa nigba ti oun kọkọ bẹrẹ si ni ṣe ere. Amọ, igba to kẹkọ pari lo bẹrẹ rẹ gẹgẹ bi iṣẹ oojọ.
O ni tako nnkan ti awọn eeyan ma n ro pe Odunlade Adekola lo kọ oun niṣẹ, Eniola Ajao sọ pe ọdọ oloogbe Moji Olaiya gan-an ni oun ti bẹrẹ.
"Nigba ti mo ṣetan ni fasiti, ni mo lọ ba Anti Moji, ti mo sọ fun wọn pe mo ti ṣetan lati maa ṣe ere gẹgẹ bi iṣẹ. Ibaṣepọ emi atiwọn si dabi tẹgbọn-taburo ni."

Oríṣun àwòrán, Eniola Ajao
Oṣerebinrin naa ṣalaye pe ọdọ Moji Olaiya ni oun wa ti oun ti ṣe alabapade Alagba Adekola.
Lati ibẹ si ni awọn mejeeji ti jọ n ṣiṣẹ pọ diẹdiẹ titi ti 'Odunlade fi di ọga rẹ'.
Iru ibaṣepọ wo lo wa laarin Eniola Ajao ati Odunlade Adekola?
Nigba to n tẹsiwaju ninu ifọrọwanilẹnuwo naa, Arabinrin Ajao sọ pe ibasepọ ọga ati ọmọ'ṣẹ lo wa laarin awọn.
Ibeere yii jẹyọ nitori pe lati ọpọlọpọ ọdun si asiko yii ni oriṣiriṣi awuyewuye ti ma n jade lori ayelujara pe awọn oṣere mejeeji n fẹ ara wọn.
Awọn kan ti ẹ maa n sọ pe Eniola Ajao bimọ fun akẹẹgbẹ rẹ ọun.
"Mi o ki n ri awọn iroyin naa ro rara, nitori pe ariwo ọja lasan ni wọn. Iru awọn iroyin bẹẹ ko le ṣa i ma wa, paapaa lori eeyan meji to jọ n ṣe iṣẹ papọ."
Arabinrin Ajao tẹsiwaju pe iha ti ẹbi Odunlade kọ si oun ati eyi ti oun kọ si wọn lo ṣe pataki ju.
Lori sinima rẹ, Ajakaju, to fa awuyewuye lasiko diẹ sẹyin, oṣere naa ṣalaye pe oun ko kabamọ pe oun lo Bobrisky lati polongo sinima naa nitori pe "ọna ti fiimu naa yoo fi ta, ti yoo pa owo ni oun n wa".
"O ti to ọdun mẹta ti mo ti ya sinima Ajakaju, ko to o di pe o jade sita. Idi ni pe, ko pẹ ti mo ya a tan, ni iroyin buruku kan jade nipa mi, eyi to mu ki ọpọ eeyan gbogun ti mi lori ayelujara."
Oṣere naa sọ pe koda, oun ta dukia oun lori sinima na, to si jẹ pe ọna lati pa owo oun pada, lo mu ki wọn o fi Bobrisky pariwo nipa fi fun un ni ami ẹyẹ gẹgẹ bi obinrin to mura julọ nibi ayẹyẹ ikojade sinima Ajakaju.



