Ẹ má bá àwọn iléeṣẹ́ 58 yìí dòwòpọ̀, wọ́n yóò lù yín ní jìbìtì – EFCC kìlọ̀

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, ti kede ileeṣẹ idokoowo mejidinlọgọta ti yoo lu araalu ni jibiti ti wọn ba ṣowo pẹlu wọn.
EFCC lo fi orukọ awọn ileeṣẹ naa lede ninu atẹjade kan loju opo ayelujara rẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ileeṣẹ naa yoo tan awọn eeyan pe ki wọn wa dowopọ pẹlu wọn pẹlu owo perete lọna ati gba ere gọbọi lẹyin akoko diẹ.
Ajọ naa sọ pe ẹnikẹni to ba dowopọ pẹlu awọn ileeṣẹ bẹẹ yoo jẹ ika abamọ ni ikẹyin nitori ni ṣe ni wọn yoo padanu owo wọn.
EFCC sọ pe ko si eyikeyi ninu awọn ileeṣẹ naa to forukọsilẹ pẹlu banki apapọ Naijiria, CBN, tabi ajọ o n bojuto idokoowo ni Naijiria, iyẹn Security Exchange Commission, SEC.
O sọ siwaju si pe pupọ ninu awọn ileeṣẹ naa loun ti gbe lọ sile ẹjọ, nigba ti marun un ninu wọn jẹbi ẹsun to fi kan wọn, awọn marun un mii sọ fun ile ẹjọ pe awọn gba pe awọn jẹbi bo tilẹ jẹ pe idajọ wọn ko tii waye.
Orukọ awọn ileeṣẹ ti EFCC kilọ faraalu lati ma ba dowopọ
- Wales Kingdom Capital
- Bethseida Group of Companies, AQM Capital Limited
- Titan Multibusiness Investment Limited
- Brickwall Global Investment Limited
- Farmforte Limited & Agro Partnership Tech
- Green Eagles Agricbusiness Solution Limited
- Richfield Multiconcepts Limited
- Forte Asset Management Limited,
- Biss Networks Nigeria Limited
- S Mobile Netzone Limited, Pristine Mobile Network
- Letsfarm Integrated Services
- Bara Finance & Investment Limited
- Vicampro Farms Limited
- Brooks Network Limited
- Gas Station Supply Services Limited
- Brass & Books Limited
- Annexation Biz Concept & Maitanbuwal Global Venturescrowdyvest Limited
- Crowdyvest Limited
- Jadek Agro Connect Limited
- Adeeva Capital Limited
- Oxford International Group and Oxford Gold Integrated
- Skapomah Global Limited
- MBA Trading & Capital Investment Limited
- TRJ Company Limited
- Farm4Me Agriculture Limited
- Quintessential Investment Company
- Adeprinz Global Enterprises
- Rockstar Establishment Limited
- SU.Global Investment
- Citi Trust Funding PLC
- Farm Buddy
- Eatrich 369 Farms & Food
- Globertrot Farmsponsors Nigeria Limited
- Farm Sponsors Limited
- Cititrust Credit Limited
- Farmfunded Agroservices Limited
- Adamakin Investment & Works Limited
- Cititrust Holding PLC
- Green Eagles Agribusiness Solutions Limited
- Chinmark Homes & Shelters Limited
- Emerald Farms & Consultant Limited
- Ovaioza Farm Produce Storage Limited
- Farm 360 & Agriculture Company
- Requid Technologies Limited
- West Agro Agriculture & Food Processing Limited
- NISL Ventures Limited & Estate of Laolu Martins
- XY Connect Investment Limited
- River Branch Unique Investment Limited
- Hallmark Capital Limited
- CJC Markets Limited
- Crowd One Investment
- Farmkart Foods Limited
- KD Likemind Stakeholders Limited
- Holibiz Finance Limited
- Ifeanyi Okpe Oil & Gas Services
- Servapps Nigeria Limited
- Barrick Gold Mining Company
- 360 Agric Partners Limited
Yatọ si awọn ileeṣẹ wọnyii, EFCC tun kilọ faraalu lati maa ṣe iwadiii eyikeyi ileeṣẹ ti wọn ba fẹ dowopọ pẹlu ki wọn to ko owo wọn le irufẹ ileeṣẹ bẹẹ lori.











