Natasha Akpoti gbé ẹjọ́ Akpabio àti àwọn aṣofìn yòókù lọ sí àjọ àwọn obìnrin l'ágbàyé

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti Uduaghan/FACEBOOK
Senetọ Natasha Akpoti-Uguaghan ti wọn da duro nile igbimọ aṣofin agba ni Naijiria ti gbe ẹjọ naa lọ si ọdọ ajọ Iṣokan Agbaye, (United Nations), niluu New York.
Aṣofin to n ṣoju Aarin-gbungbun ipinlẹ Kogi ṣaaju idaduro rẹ naa n beere fun idasi ajọ Iṣokan Agbaye lati gbeja rẹ ja lori ẹsun fifi ilọlukọ lọ ọ lọna ifẹ, to ni Godswill Akpabio, olori ile igbimọ aṣofin agba ni Naijiria fi lọ oun.
Natasha sọ pe nitori iwadii kikun lori ọrọ naa ti oun beere ni wọn ṣe n dunkooko mọ oun, ti wọn da oun nipo aṣofin.
Nigba to n sọrọ nibi ipade ajọ naa to jẹ tawọn obinrin, eyi to waye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta ọdun 2025 yii, Natasha sọ pe:
" Gbogbo agbaye ko gbọdọ dakẹ lori ọrọ yii, nitori dẹmokresi ati ẹtọ awọn obinrin ti di atẹmẹrẹ ni Naijiria".
Tẹ o ba gbagbe, ọrọ ijokoo Natasha to ni wọn paarọ lasiko ti ile n ṣepade lọwọ lo kọkọ bi wahala.
Eyi lo pada di ti ẹsun ifẹkufẹẹ ara ti obinrin naa fi kan Akpabio.
Latigba naa ni ọrọ ọhun ti n ran bii ina inu ọyẹ.
Ile pada paṣẹ ki Natasha Akpoti lọọ sinmi foṣu mẹfa, iyẹn lọjọ kẹfa oṣu kẹta yii, pẹlu alaye pe o gbọdọ kọwe lati tọrọ aforiji ki oṣu mẹfa naa too pe.
Bo tilẹ jẹ pe amofin tẹlẹ naa ti ni oun ko ni i kọ iwe kankan, ko sẹni to mọ pe yoo gbe ọrọ naa de ọdọ ajọ UN.
Fun oṣu mẹfa ti yoo fi wa nisinmi apapandodo yii, ile igbimọ ko ni i sanwo oṣu fun Natasha, wọn ti ti ọfiisi rẹ pa pẹlu, wọn si ti paṣẹ fun un pe ko gbọdọ pe ara rẹ ni aṣofin to ba n ba awọn akọroyin sọrọ.
Iṣẹlẹ to n waye laaarin Natasha, Akpabio ati ile igbimọ aṣofin agba yii ti pin ero awọn eeyan si ọtọọtọ.
Ẹ o ranti pe ifẹhonuhan ti waye nile igbimọ naa lori rẹ.
Bawọn kan ṣe n sọ pe Akpabio gbọdọ fi ipo rẹ silẹ, bẹẹ lawọn kan n sọ pe ko maa ba iṣẹ rẹ lọ.














