Amẹrika ṣètò áàpù fún àwọn tí kò ní ìwé ìgbélùú, tó sì fẹ́ ẹ̀ já padà s'orílẹ̀èdè wọn

CBP One app

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ilẹ Amẹrika ti n gbe igbesẹ lati ṣeto aapu kan ti awọn to n gbe nilẹ naa lai ni iwe igbelu yoo ti maa fi orukọ ara wọn silẹ ko le rọrun fun ijọba ilẹ naa lati le wọn pada si orilẹede wọn.

Aapu ọhun ni wọn kọkọ ṣe fun iforukọsilẹ awọn aṣatipo tẹlẹ.

Orukọ aapu naa ni CBP Home, yoo si fun awọn ọmọ ilẹ okeere ti ko ni iwe igbelu lati fi ara wọn le ijọba lọwọ lati le wọn pada silẹ wọn lai si pe wọn fi imu wọn danrin.

Ṣaaju ni ijọba Amẹrika ti kọkọ ke si awọn eeyan ti ko ni iwe igbelu nibẹ lati maa fi ilẹ naa silẹ funra wọn lai ṣe pe oun fi tipa tikuuku le wọn kuro nibẹ.

Igbesẹ tuntun yii jẹ ọkan lara awọn ọna ti ijọba Amẹrika n gba lati le awọn ti ko ni iwe igbelu kuro nilẹ ọhun lẹyin ti Aarẹ Donald Trump pada gba ọpa aṣẹ ijọba.

Ọdun 2020 ni wọn kọkọ ṣeda aapu CBP ki wọn to tun fẹ ẹ loju si lasiko ijọba Biden lati maa lo o fun awọn aṣatipo lati mu ọjọ ti wọn yoo farahan lẹnu ibode Amẹrika.

Lasiko naa, ijọba sọ pe aapu ọhun n mu adinku ba iye awọn eeyan ti ijọba yoo sọ si ọgba ẹwọn latari pe wọn wọ ilẹ awọn lọna ti ko ba ofin mu, ti wọn ko si ni iwe igbelu.

Ni bayii, awọn ti ko ni iwe igbelu le maa lo o lati kede pe wọn ko ni iwe igbelu ati lati fi orukọ ara awọn silẹ pe awọn fẹ fi ilẹ Amẹrika silẹ wọrọwọ.

Ninu atẹjade kan ti olori ileeṣẹ eto abo abo Amẹrika, Kristi Noem, fi lede, o ni awọn to ba lo aapu naa lati fi Amẹrika silẹ yoo lanfaani lati pada wọ Amẹrika.

Nipa awọn ti ko ni iwe igbelu ti wọn si fẹ lati maa gbe l'Amẹrika lọna ti ko ba ofin mu, Noem sọ pe "Ti wọn ba kọ lati lo o, a maa wa wọn ri, a o si maa le wọn pada silẹ wọn, wọn ko si ni lanfaani lati wọ Amẹrika mọ."

Awọn to ba fẹ fi Amẹrika silẹ tun le sọ lori aapu naa boya wọn ni owo to to lati kuro l'Amẹrika.