Ilé ẹjọ́ fún Oriyomi Hamzat àti olorì Naomi ní ọ̀nà àbáyọ láti tètè yanjú ìgbẹ́jọ́ wọn

Oriyomi Hamzat/Olori Naomi

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/Olori Naomi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igbejọ lori ẹsun mejidinlogun ti ijọba fi kan Olori tẹlẹri ni aafin Ile Ifẹ, Naomi Shilekunela, ati gbajumọ sọrọsọrọ lori redio, Oriyomi Hamzat, ọga ile ẹko Islamic High School to wa ni agbegbe Bashorun ni ile ẹjọ ti sun si iwaju fun ọsẹ meji.

Adajọ agba Ladiran Akintola sun igbejọ naa fun ọsẹ meji nitori awọn ti wọn fẹsun kan ti ṣetan lati san ọwọ gba mabinu fun awọn idile ti wọn padanu awọn ọmọ wọn ninu ijamba to sẹlẹ nibi ayẹyẹ ipari ọdun ti olori Naomi ṣe agbeteru rẹ lodun to koja.

Wọlu-kọlu to waye ni ibudo ti wọn ti fẹ ṣe eto naa lo fa iku awọn ọmọde marundinlogoji ti wọn si dero ahamọ ọlọpaa ki ile ẹjọ to gba oniduro wọn.

Noomi Silekunola

Agbejoro fun ijọba Oyo, Abiodun Aikomo ni lootọ lo ye ki igbejọ bẹẹrẹ lonii ṣugbọn awọn ti ọrọ naa kan rọ ijọba lati jẹ ki wọn san owo gba mabinu fun awọn idile ti awọn ọmọ wọn padanu ẹmi wọn, to fi mọ awọn to ṣeṣe nibi iṣẹlẹ ọhun.

Abiodun Aikomo tẹsiwaju wi pe mi ijọba Oyo yoo ni suuru fun ọsẹ meji, ti awọn ti wọn fẹsun kan naa baa kọ lati san owo gba mabinu fun awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ati awọn to farapa igbejọ naa yoo tesiwaju.

Ninu ọrọ rẹ, Musibau Adetunmbi (SAN), to jẹ agbẹjọro fun Naomi Silekunola ṣalaye wi pe lootọ ni awọn rọ ile ẹjọ lati fi aye ọsẹ meji silẹ lati jẹ ki awọn yanju ọrọ naa lai wa si ile ẹjọ.

O ni iṣẹlẹ to bani loju jẹ ni iṣẹlẹ naa, nitori ore ni awọn onibara ohun ṣe to pada di ibi bayii.

O fi kun pe gbogbo igba ti iroyin nipa iṣẹlẹ naa baa waye ni o n jẹ ọgbe inu fun awọn to padanu eeyan wọn, idi niyi ti awọn ṣe fẹ ki wọn yanju ọrọ naa ni itumbinubi.

Musibau ni awọn onibaara oun ti bẹrẹ igbesẹ naa ati pe laarin akoko yii si ọsẹ meji ti ile ẹjọ gbe kalẹ, ọrọ naa yoo ti ni iyanju.

Ti ẹ ko ba gbagbe ọmọde marundinlogoji lo ku nibi eto ti wọn gbe kalẹ lati ṣe iranwọ fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ ni ipari ọdun 2024.

Awọn eeyan naa ku lasiko ti wọlukọlu waye ni gbagede eto naa nigba ti awọn ọmọde n sa ipa lati wọ ibudo eto ọhun.

Oriyomi Hamzat àti Naomi Silekunola tún fara hàn níléẹjọ́ lónìí

Oriyomi Hamzat ati Naomi Silekunola

Oríṣun àwòrán, Others

Igbẹjọ olori Ooni nigba kan, Naomi Silekunola, ati gbajugbaja agbohunsafẹfẹ, Oriyomi Hamzat, tun tẹsiwaju nile ẹjọ.

Gbajumọ agbohunsafẹfẹ, Oriyọmi Hamzat, Olori Ile-Ifẹ tẹlẹri, Naomi Ṣilẹkunọla ati alakoso ile ẹkọ girama 'Islamic High School' niluu Ibadan, Abdullahi Fasasi fi ara han nile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ l'owurọ ọjọ Aje, lori awuyewuye to rọ mọ apejẹ opin ọdun ti Olori Naomi ṣe fun awọn ọmọde l'oṣu Kejila, ọdun 2024, ninu eleyii ti awọn ọmọde kan ti pade iku ojiji.

Ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2025 ni awọn afurasi naa yọju sile ẹjọ kẹhin.

Ile-ejọ giga ti ijọba ipinlẹ Oyo to wa ni agbegbe Ring-Road niluu Ibadan ni igbẹjọ naa ti waye.

A si n ṣe akojọpọ iroyin bi nnkan ṣe n lọ nile-ẹjọ. Ẹ tẹti leko

Ki la wọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin?

O kere tan, ọmọde marunlelọgbọn lo ku, ti ọpọ si farapa, nibi apejẹ ti olori Ooni Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan.

Ọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024, ni eto naa yẹ ko waye, amọ gbogbo rẹ foriṣanpọn nitori ohun to ṣẹlẹ

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC Yoruba pe ko tii pẹ ti eto bẹrẹ, ti awọn eeyan fi bẹrẹ si ni tẹ ara wọn.

Igba akọkọ kọ ree ti Olori Naomi Silekunola Ogunwusi ṣe eto apejẹ naa.

Ọdọọdun lo maa n ṣe e labẹ ajọ ẹlẹyinju aanu rẹ to pe ni, Women in Need of Guidance and Support (WINGS).

Adajọ ju wọn si ẹwọn

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2024, ni Onidajọ Olabisi Ogunkanmi ti ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Iyaganku nilu Ibadan, ipinlẹ Oyo ti paṣẹ pe ki wọn fi Olori Ọọni Ile-Ifẹ tẹlẹ, Naomi Silekunola, Oriyomi Hamzat to jẹ alakoso agba fun ileeṣẹ redio kan nilu Ibadan pamọ si atimọle lọgba ẹwọn.

Adajọ naa tun sọ pe ki ọga agba nileẹkọ girama ti Islamic High School to wa lagbegbe Bashorun, Ibadan naa tẹle wọn lọ.

Ọgba ẹwọn Agodi to wa nipinlẹ Ọyọ ni adajọ naa sọ pe ki awọn afurasi naa ti lọ maa gbatẹgun titi di igba ti wọn yoo fi tun gbọ ẹjọ wọn.

Nibẹ ni wọn si wa titi di oṣu Kini, ọdun 2025 ti wọn gba ominira.

Lati igba naa si ni wọn ti n gba ile wọn jẹjọ.