Oriyọmi Hamzat àti Naomi Ṣilẹkunọla fara hàn níléẹjọ́ lonii, bí ìgbẹ́jọ́ náà ṣe lọ rèé...

Oriyomi ati Naomi

Oríṣun àwòrán, instagram/oriyomihamzat/Naomi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ agbohunsafẹfẹ, Oriyọmi Hamzat, Olori Ile-Ifẹ tẹlẹri, Naomi Ṣilẹkunọla ati alakoso ile ẹkọ girama 'Islamic High School' niluu Ibadan, Abdullahi Fasasi fi ara han nile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ l'owurọ ọjọ Iṣẹgun, lori awuyewuye to rọ mọ apejẹ opin ọdun ti Olori Naomi ṣe fun awọn ọmọde l'oṣu kejila ọdun 2024, ninu eleyii ti awọn ọmọde kan ti pade iku ojiji.

Owurọ oni lo yẹ ki ile ẹjọ ka ẹsun si awọn mẹtẹẹta leti nile ẹjọ giga to bẹ ni agbegbe Ring Road ilu Ibadan, ṣugbọn igbẹjọ naa ko ni anfani lati tẹsiwaju nitori pe awọn ẹni afẹsun kan naa ko tẹwọgba iwe ifẹsunkanni saaju ọjọ oni.

Nitori idi eyii sini ile ẹjọ fi sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹwaa oṣu kẹta ọdun yii.

Ki ni Oriyọmi sọ?

Agbẹjọro fun Oriyọmi Hamzat to ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin igbẹjọ naa, Adekunle Ṣọbaloju ṣe alaye wi pe, "Oni lo yẹ ki wọn ka ẹsun wọn si wọn leti, ṣugbọn ile ẹjọ ko le ka ẹsun yẹn nitori wọn ko tii fun wọn ni iwe ti yoo ṣe alaye ẹjọ ti wọn fẹ jẹ. Ile ẹjọ wa sun ọrọ naa si ọjọ kẹwaa oṣu kẹta, ki wọn le ni anfani lati gbọ ẹsun ti wọn fi kan wọn."

Oriyomi ati Naomi

Oríṣun àwòrán, instagram/oriyomihamzat/Naomi

Ki ni ijọba ipinlẹ Ọyọ sọ?

Bakan naa, Kọmisana fun eto idajọ to tun jẹ amofin agba fun ipinlẹ Ọyọ n'ipinlẹ Ọyọ, Abiọdun Aikọmọ fi kun ọrọ naa pe ipejọpọ ile ẹjọ waye lati fi idi ẹsun ti wọn fi kan awọn mẹtẹẹta mulẹ, ṣugbọn nitori pe beeli ni wọn gba tẹlẹ, ile ẹjọ fẹ rii daju pe awọn to gba beeli wọn ṣi fẹ tẹsiwaju lati maa jẹ oniduro fun wọn, ṣugbọn nitori awọn afurasi ko fi idi rẹ mulẹ lo mu ki ile ẹjọ sun igbẹjọ si ọjọ kẹwaa oṣu kẹta."

Igba wo ni wọn sun igbẹjọ naa si?

Oriyomi ati Naomi

Oríṣun àwòrán, instagram/oriyomihamzat/Naomi

Ile ẹjọ Majistreeti to n bẹ ni agbegbe Iyaganku niluu Ibadan lo kọkọ pasẹ wi pe ki wọn sọ awọn afurasi naa si atimọlẹ ko to di pe ọrọ naa de ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ nibi ti wọn ti gba beeli wọn ni ibẹrẹ ọdun yii.

Yatọ si igbẹjọ ti wọn sun si ọjọ kẹwaa oṣu kẹta lonii nile ẹjọ giga, awọn mẹtẹẹta yoo tun fi ara han ni ile ẹjọ Majistreeti Iyagankun lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta bakan naa, nibi ti ile ẹjọ Majistreeti yoo ti yọwọ ninu ẹjọ naa ti wọn o si fi ṣọwọ si ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ.