Oriyomi Hamzat padà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n Agodi pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹ̀bún lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjí tó kúrò níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Agidigbo FM
Gbajumọ agbohunsafẹfẹ nilu Ibadan, Oriyomi Hamzat ti se abẹwo si ọgba ẹwọn Agodi nilu Ibadan lẹyin to jade kuro ni ọgba ẹwọn naa ni ọsẹ meji sẹyin.
Ni asiko yii, Oriyomi ko lọ si ọgba ẹwọn naa gẹgẹ bii ẹni to wa ni ahamọ, amọ o lọ gẹgẹ bii ẹni to ni ominira.
Oriyomi si lọ si ọgba ẹwọn Agodi naa lati sami ọjọ ibi Seyi Akinbohun, tii se ọga agba fun ileesẹ Redio Agidigbo ti Oriyomi da silẹ.
Abẹwo naa si ni o wa lati sajọyọ igbe aye ọga agba funleesẹ redio naa nipa riranti awọn to wa ni ahamọ, ti wọn ko si ri ọwọ họ ori.

Oriyomi ko lọ si ọgba ẹwọn naa gẹgẹ bii ẹni to wa ni ahamọ, amọ o lọ gẹgẹ bii ẹni to ni ominira
Gbajumọ agbohunsafẹfẹ nilu Ibadan, Oriyomi Hamzat ti se abẹwo si ọgba ẹwọn Agodi nilu Ibadan lẹyin to jade kuro ni ọgba ẹwọn naa ni ọsẹ meji sẹyin.
Ni asiko yii, Oriyomi ko lọ si ọgba ẹwọn naa gẹgẹ bii ẹni to wa ni ahamọ, amọ o lọ gẹgẹ bii ẹni to ni ominira.
Oriyomi si lọ si ọgba ẹwọn Agodi naa lati sami ọjọ ibi Seyi Akinbohun, tii se ọga agba fun ileesẹ Redio Agidigbo ti Oriyomi da silẹ.
Abẹwo naa si ni o wa lati sajọyọ igbe aye ọga agba funleesẹ redio naa nipa riranti awọn to jẹ wa ni ahamọ, ti wọn ko si ri ọwọ họ ori.
Ki lo gbe Oriyomi de ọgba ẹwọn saaju?
O kere tan, ọmọde marunlelọgbọn lo ku, ti ọpọ si farapa, nibi apejẹ ti olori Ooni Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan.
Ọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024, ni eto naa yẹ ko waye, amọ gbogbo rẹ fori ṣanpọn nitori ohun to ṣẹlẹ
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC Yoruba pe ko tii pẹ ti eto bẹrẹ, ti awọn eeyan fi bẹrẹ si ni tẹ ara wọn.
Idi ree ti ileesẹ ọlọpa ipinlẹ Oyo se gbe Olori Silekunola ati agbohunsafẹfẹ to fọnrere eto naa, Oriyomi Hamzat tileese Agidigbo FM.
Onidajọ Olabisi Ogunkanmi ti ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Iyaganku nilu Ibadan, ipinlẹ Oyo ti paṣẹ pe ki wọn fi Olori Naomi Silekunola ati Oriyomi Hamzat pamọ si atimọle lọgba ẹwọn.
Adajọ naa tun sọ pe ki ọga agba nileẹkọ girama ti Islamic High School to wa lagbegbe Bashorun, Ibadan naa tẹle wọn lọ.
Ọgba ẹwọn Agodi to wa nipinlẹ Ọyọ ni adajọ naa sọ pe ki awọn afurasi naa ti lọ maa gbatẹgun titi di igba ti wọn yoo fi tun gbọ ẹjọ wọn.
Amọ ni ọsẹ meji sẹyin ni ile ẹjọ giga to wa nilu Ibadan gba beeli awọn olujẹjọ naa, ti ẹjọ ọhun si n tẹ siwaju.

Oríṣun àwòrán, Agidigbo FM