Kí ni ìwúlò ẹ̀ka ayélujára 'Deepseek AI' ti China ṣe , èyí to ń gba iyì mọ́ t'America lọwọ

Aworan ẹka DeepSeek ati ChatGPT.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lasiko yii, ẹka ayelujara AI kan ti a mọ si Deepseek, eyi ti orilẹede China ṣẹṣẹ gbe jade, ti gba iyi mọ ẹya iru ẹ , ChatGPT ti wọn ṣe l'America lọwọ.

Awọn ileeṣẹ to n ri si ẹka igbalode fidi ẹ mulẹ pe lọwọlọwọ yii, Deepseek ti gba ori mọ awọn to ku lọwọ, ati pe America gan-an dakẹ fun un ni.

Loju opo X, agbaọjẹ Marc Andreessen, kọ ọ sibẹ lọjọ Aiku, pe "DeepSeek-R1 AI' lo gba ori afẹfẹ kan lasiko yii.

Ni gbogbo opin ọsẹ to kọja, ẹka DeepSeek to jẹ ọfẹ lawọn eeyan bẹrẹ si i gba ju (download).

Nigba ti yoo fi di ọjọ Aje, ẹka tuntun yii ti kọja ohun ti awọn ẹka ikansiraẹni yooku le gboju kuro nibẹ.

Ẹru si ti bẹrẹ si i ba awọn kan pe boya ni America to n leke tẹlẹ ko ti jabọ bayii.

Fun apẹẹrẹ, ileeṣẹ Nvidia toun naa n ṣe AI, ja walẹ ninu ìdá owo to n wọle, o padanu owo to to $600bn.

Owo to padanu yii lo pọ ju ninu itan ipin idokowo ni US, gẹgẹ bi ẹka Bloomberg, ṣe sọ.

Aarẹ Donald Trump lasiko to ba awọn ọga ileeṣẹ AI ṣepade laipẹ yii.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Donald Trump lasiko to ba awọn ọga ileeṣẹ AI ṣepade laipẹ yii.

Kí ló sọ Deep Seek di olúborí?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi awọn to gbe ẹka DeepSeek kalẹ ṣe wi, aṣeyọri nla yii ko ṣẹyin owo ti wọn fi gbe e kalẹ.

Nigba ti awọn to ṣe 'ChatGPT OpenAI' na biliọnu marun-un naira lọdun to kọja nikan, awọn to ṣe DeepSeek ni awọn ko na ju $5.6m lọ.

Owo ti DeepSeek na yii kere pupọ ti a ba wo iye ti awọn agbaọjẹ bii OpenAI, Google, ati Anthropic maa n na lati gbe tiwọn kalẹ.

DeepSeek ṣalaye pe imọ ẹrọ to wa nilẹ lawọn lo, ẹnikẹni lo si le lo ẹka awọn lọfẹẹ, ko si tun pin in sibi to ba fẹ.

Eyi ti fa ariyanjiyan laaarin awọn onileeṣẹ AI miran, awọn kan n sọ pe irọ ni DeepSeek n pa.

"Mo ro pe otitọ ko ti i foju han nipa ohun to n lọ". Gene Munster to jẹ agbaọjẹ lẹka yii lo sọ bẹẹ lọjọ Aje. O ni boya nitori wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.

"Bi DeepSeek ṣe jẹ iyi nla fun China lo gba iyi mọ America lọwọ lẹka imọ ẹrọ" Gene Munster lo sọ bẹẹ.

Ọsẹ to kọja yii ni Sam Altman ati Larry Ellison tawọn naa jẹ alaṣẹ AI, ṣepade awọn akọroyin pẹlu Aarẹ Donald Trump, bẹẹ ko ju ohun ti wọn kan le fi atẹjade sita lori rẹ lọ.

Wọn kede ajọṣepọ to le pa to $500bn lẹka AI ni Texas ati awọn ibo mi-in, ti yoo si tun pese iṣẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un (100,00).

Ṣé America yóò padà gba orí mọ́ DeepSeek lọwọ?

Latilẹ, orilẹede America lo foju han bii agba lẹka AI, pẹlu bi China ṣe mọ nipa agbekalẹ naa to.

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan ti sọ ọ ri pe America ko le maa gba ipo naa lọ, ero awọn kan ni pe wọn yoo pada sipo naa , ṣugbọn wọn gbọdọ mura lasiko yii.

Wọn ni DeepSeek yii yoo mu wọn lomi gan-an bi wọn ko ba ṣọra.

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Donald Trump rọ awọn tọrọ kan, lati ri ohun to n ṣẹlẹ yii bii itaniji.

O ni ki ẹka imọ ikansiraẹni l'America mọ pe bi wọn ba n ṣe AI to dinwo, ohun to daa ni.

Trump sọ pe ki wọn lọọ mọ pe ẹka imọ ẹrọ nikan kọ ni ọrọ yii kan, o ni o kan ẹka agbara pẹlu.