AFCON 2025: Naijiria yóò kojú Tunisia àti àwọn mí-ìn ní ìsọ̀rí kẹta

Aworan ife-ẹyẹ AFCON.

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Aworan ife-ẹyẹ AFCON.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi idije ere bọọlu alafẹsẹgba ti ilẹ Africa, iyẹn Africa Cup of Nations (AFCON) yoo ṣe waye lorilẹede Morocco ni 2025 yii, iṣọri kẹta ti wn n pe ni C, ni orilẹede Naijiria wa.

Ikọ Super Eagles ilẹ Naijiria yoo koju Tunisia, Uganda ati Tanzania.

Ni ti Cameroon, ẹka F lawọn wa, wọn yoo si maa wa a ko pẹlu Côte d'Ivoire to gba ife ẹyẹ naa gbẹyin, Gabon ati Mozambique.

Gbogbo orilẹẹde mẹrinlelogun (24) to peregede lati kopa ninu idije yii ni wọn ti mọ ilu ti awọn yoo maa ba ta ayo.

Orilẹede Morocco to fẹẹ gbalejo idije naa lọdun yii ti fi ọpọ ọdun sinmi, ọdun 1988 ni wọn ti gbalejo idije naa gbẹyin.

Idije ọhun yoo bẹrẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila ọdun 2025, yoo si pari lọjọ kejidinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Wo ìṣọ̀rí tí wọ́n pín àwọn orílẹ̀èdè sí fún ìdíje AFCON 2025

Aworan iṣori awọn agbabọọlu fun AFCON 2025.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Aworan iṣori awọn agbabọọlu fun AFCON 2025.

Iṣori A: Morocco, Mali, Zambia, Comoros

Isọri B: Egypt, South Africa, Angola, Zimbabwe

Isọri C: Nigeria, Tunisia, Uganda, Tanzania

Isọri D: Senegal, DR Congo, Benin Republic, Botswana

Isọri E: Algeria, Burkina Faso, Equatorial Guinea, Sudan

Isọri F: Cote d'Ivoire, Cameroon, Gabon, Mozambique

Èyí ni bí àjọ CAF ṣe to àwọn ikọ̀ náà

Ikọ agbabọọlu mẹrinleogun lo peregede lati kopa ninu idije yii, eyi si ni ipo ti wọn wa bi ajọ elere bọọlu; CAF, sẹ to o ṣaaju idije naa.

Ìpín 1: Morocco (to n gbalejo), Senegal, Egypt, Algeria, Nigeria, Côte d'Ivoire.

Ìpín 2: Cameroon, Mali, Tunisia, South Africa, DR Congo, Burkina Faso.

Ìpín 3: Gabon, Angola, Zambia, Uganda, Equatorial Guinea, Benin.

Ìpín 4: Mozambique, Comoros, Tanzania, Sudan, Zimbabwe, Botswana.