Ológun gbé ìjà ká agbébọn mọ́lé, Ṣọ́jà 22 àti agbébọn 70 dèrò ọ̀run

Aworan awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, BBC/BOKO HARAM

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti fidi ẹ mulẹ pe ko din ni ọmọ ogun mejilelogun (22) to papoda ninu ikọlu awọn ṣọja ati awọn agbebọn to n lọ lọwọ nipinlẹ Borno.

Bakan naa ni wọn ni awọn agbebọn paapaa padanu ẹmi, aadọrin ni wọn lo ba ija ajaku akata naa lọ.

Atẹjade ti Adari ẹka iroyin nileeṣẹ ologun ilẹ wa, Ọgagun Edward Buba fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 yii, ṣalaye pe aginju Timbuktu, nipinlẹ Borno ni ija naa ti n waye.

Wọn ṣalaye pe Timbuktu jẹ ibi ti awọn agbesunmọmi fi ṣe ibuba, o si ti di ẹru jẹjẹ lati wọ.

Igbiyanju lati tu awọn ikọ apaayan naa ka lo fa a ti awọn ologun fi wọ ibẹ, labẹ eto ifọlumọ ti wọn pe ni Operation Hadin Kai, eyi to fẹẹ wo ogun awọn apaayan naa lulẹ patapata.

Àwọn tó bá ìkọlù náà lọ

Nigba to n ṣalaye nipa awọn ṣọja to ba ikọlu yii lọ, Ọgagun Buba rọ awọn akọroyin lati ma ṣe gbe orukọ awọn mejilelogun to di oloogbe naa sita.

O ni eyi wa ni ibamu pẹlu ilana ti awọn yoo gba lati fi to awọn ẹbi wọn leti, ti awọn yoo si to o lẹsẹẹsẹ bo ṣe yẹ labẹ ofin.

Nipa ti aadọrin awọn ẹruuku to ni awọn ṣọja pa ninu ija naa, Ọgagun Buba darukọ awọn mẹta to ni ọga agba ni wọn ninu ikọ apaayan naa.

Olori ogun wọn , Talha, apaṣẹ Mallam Umar ati Abu Yazeed toun naa jẹ apaṣẹ ikọ naa wa ninu awọn to ba ogun lọ bi Ọgagun Buba ṣe sọ.

''Ikọ ologun Hadin Kai ti bẹrẹ si i wọ igbo Timbuktu lati ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025, a tẹsiwaju titi di ọjọ karundinlọgbọn, bẹẹ ni iṣẹ naa ṣi n lọ lọwọ.

''Oriṣiiriṣii ọgbọn ija la ri latọwọ awọn agbebọn, wọn tun lo ado oloro pẹlu awọn nnkan ija miran.

''Erongba wa ni lati tu ogun wọn ka.

''Ninu ikọlu naa ni a si ti pa awọn ọga wọn mẹta, ti ọpọlọpọ wọn tun farapa. O le ni aadọrin ninu wọn ti ikọ ologun Naijiria pa lapapọ, a si padanu ọmọ ogun mejilelogun''

Bayii ni Ọgagun Edward Buba ṣalaye ninu atẹjade naa.