Alukoro ọlọ́pàá Naijiria ní agbófinró lè já wọlé afurasí láì ní ìwé àṣẹ, ariwo ta

Alukoro ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi

Oríṣun àwòrán, MUYIWA ADEJOBI/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lọjọ Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 yii ni ariwo ta loju opo ayelujara X, lẹyin ọrọ kan ti Alukoro ọlọpaa ilẹ Naijiria, Olumuyiwa Adejobi, sọ.

Adejobi sọ pe ofin faaye gba ọlọpaa lati ja wọle afurasi lai tilẹ ni iwe aṣẹ iyẹlewo.

Alukoro ni bi ẹri to daju ba ti wa pe iwa ọdaran ni wọn n hu ninu ile naa, dandan kọ ni ki ọlọpaa mu iwe iyẹlewo dani ki wọn too le wọ iru ile bẹẹ, nigba ti awọn to wa nibẹ ko ba fẹẹ fun wọn lanfaani lati wọle.

Kí ló fà á tí Adejobi fi sọ̀rọ̀ yìí?

Ẹnikan loju opo X, Somto Okonkwo, lo fi fidio ibi ti awọn ọlọpaa kan to fi àwọ̀n bo oju ti n fo iganna wọnu ile kan.

Fidio naa ṣafihan bawọn ọlọpaa ṣe n yinbọn nigba ti awọn to wa ninu ile naa ko ṣilẹkun fun wọn lati wọle.

Awọn ọlọpaa yii pada wọle sinu ọgba ile naa lẹyin ti wọn fo fẹnsi wọle.

Fidio yii ni awọn eeyan bẹrẹ si i sọrọ nipa rẹ loju opo naa, ti wọn si n bu ẹbu atẹ lu bi awọn ọlọpaa ṣe fipa wọle sile onile.

Eyi ni Alukoro ọlọpaa fi da wọn lohun pe:

" Ọlọpaa lagbara lati já wọ ile yoowu ko jẹ, bi wọn ba ti ri aridaju pe iwa ọdaran n lọ lọwọ nibẹ"

"Ilana nikan ni wọn nilo lati tẹle. Agbara lati wọle ati lati jade, ki i ṣe ni Ila Oorun nikan, ofin Ilẹ ni."

Ariwo ta nÍ X

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ben Samuel, ọkan ninu awọn eeyan loju opo X, tako alaye Adejobi.

Ọkunrin naa sọ pe alaye Alukoro ko ye eeyan rara.

O ni ọlọpaa ko lẹtọọ lati ja ilẹkun wọle onile labẹ ofin, lai jẹ pe wọn ni iwe aṣẹ iyẹlewo. (Search warrant)

Ben Samuel sọ pe iwa ti awọn ọlọpaa to fo iganna wọle naa hu ko yatọ si tawọn adigunjale, o si yẹ ki wọn koju ijiya to yẹ labẹ ofin.

"Bawo ni iru iwa yii ṣe ba ofin mu? Ọlọpaa fi àwọ̀n boju, lai ni iwe aṣẹ iyẹlewo, wọn n yinbọn, wọn tun fo iganna wọle onile, ẹ si ni bo ṣe yẹ ki wọn ṣe niyẹn? Araalu to ba nibọn lọwọ yoo ti pa ọlọpaa yii danu"

Bẹẹ ni ẹnikan to pe ara rẹ ni 'Great Oracle Extraordinary & Plenipotentiary', tako Alukoro ọlọpaa Naijiria lori ọrọ naa.

" Wiwọ aṣọ ọlọpaa nikan ko to ẹri ti a fi le mọ agbofinro mọ, nitori awọn ọdaran, ajinigbe, agbesunmọmi ti n wọ aṣọ naa ṣiṣẹ wọn. Iwa akọṣẹmọṣẹ gidi nikan la fi le da agbofinro gidi mọ"

Bayii ni ẹlomi-in loju opo naa torukọ rẹ n jẹ Dipo, tun tako awijare ọlọpaa.

Ṣugbọn Olumuyiwa Adejobi naa da wọn lohun pada, o ni

" Bo ti wu ki wọn ṣe agbyẹwo ofin to, bi a o ṣe maa lo o nikan naa ni wọn le tun yẹ wo.

''Ẹ si lọọ mọ, pe ki i ṣe gbogbo igba la nilo iwe aṣẹ ka too le yẹ ile wo tabi mu eeyan.

" Ẹ ka ofin ko ye yin yeke. Ọpọ ofin lo de iṣẹ ọlọpaa, wọn ko si ki n yipada, wọn duro titi.'

Bẹẹ Alukoro ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi, wi.