Wo ìdílé tó ń gbẹ́ sàárè lọ́fẹ̀ẹ́ fún àádọ́ta ọdún ní Nàìjíríà

Magaji Abdullahi, Aliyu ati Abdullahi

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang / BBC

    • Author, Mansur Abubakar
    • Role, BBC News, Kaduna
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Fún àádọ́ta ọdún ó lé ni ìdílé kan ti fi ara wọn jìn láti máa ṣe ìtọ́jú itẹ́ òkú tó tóbi jùlọ ní ìlú Kaduna, àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Iṣẹ́ yìí ni wọ́n yàn láàyò nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn tí kìí fẹ́ ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn nǹkan tó bá ti jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ òkú.

Kó tó di ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn, wọn kò ṣe iṣẹ́ náà láti máa fi pa owó – gbígbẹ́ sàárè, wíwẹ òkú àti ṣíṣe ìtọ́jú gbogbo ìtẹ́ òkú – iye péréte táwọn ẹbí bá fún wọn ni wọ́n ń gbà gẹ́gẹ́ bí owó ọ̀yà wọn.

Láti nǹkan bíi ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn ni àwọn aláṣẹ ti ya ite òkú Tudun Wada fáwọn Mùsùlùmí láti máa sin òkú wọn sí.

Ọdún 1970 làwọn ẹbí Abdullahi tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò – Ibrahim àti Adamu bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

Ibrahim àti Adamu ti di ẹni ilẹ̀ ní itẹ́ òkú kan náà táwọn ọmọ wọn sì ti ń ṣe àmójútó itẹ́ òkú náà báyìí.

Magaji Abdullahi, tó jẹ́ àkọ́bí Ibrahim Abdullahi sọ fún BBC pé bàbá òun, nígbà tó wà láyé, fi kọ́ àwọn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ táwọn ń ṣe àti pé àwọn máa kó èrè rẹ̀ lọ́jọ́ kan kódà bí kìí bá ṣe láyé yìí.

Ó ní èyí ló fà á tí àwọn fi ń ṣe iṣẹ́ náà láì gba owó kankan nídìí rẹ̀.

Ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta náà ló ń ṣe àmójútó ìtẹ́ òkú Tudun Wada àtàwọn òṣìṣẹ́ méjìdínlógún, tó fa ara wọn sílẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ báyìí.

Òun àtàwọn ìbátan rẹ̀ méjì – Abdullahi, ẹni àádọ́ta ọdún àti Aliyu ẹni ogójì ọdún (àwọn ọmọ Adamu) ni wọ́n jẹ́ ojúlówó òṣìṣẹ́, tí wọ́n ń wọ iṣẹ́ ní aago méje òwúrọ̀ di aago méje ìrọ̀lẹ́ ojoojúmọ̀.

Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń wà lẹ́nu iṣẹ́ nítorí, gẹ́gẹ́ bí òfin ẹ̀sìn Islam, láàárín wákàtí díẹ̀ tí òkú bá kú tán ni wọ́n gbọdọ̀ sin ín.

Ọkùnrin kan ń gbẹ́ sàárè òkú ní Tudun Wada, ìpínlẹ̀ Kaduna

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang / BBC

Àkọlé àwòrán, Ó máa ń tó wákàtí kan láti gbẹ́ sàárè

Magaji máa ń gba ìpè yálà láti ọ̀dọ̀ ẹbí tàbí Imam tó bá wà ní agbègbè ibi tí èèyàn bá ti ṣaláìsí – gbogbo àwọn olórí ẹ̀sìn ní ìlú náà ló ní nọ́mbà ìpè Magaji lọ́wọ́.

"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ní nọ́ḿbà fóònù wa lọ́wọ́, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí iṣẹ́ bá ti wà ni wọ́n máa ń pè wá," ó sọ.

Ọ̀kan nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yóò máa ṣe ìtọ́jú òkú nípa wíwẹ̀ àti fífi aṣọ wé òkú, táwọn yòókù yóò sì máa gbẹ́ sàárè lọ.

Ó le gbà wọ́n tó wákàtí kan láti fi gbẹ́ sàárè, èyí tó máa ń jìn tó ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà míràn tí ilẹ̀ ọ̀hún bá jẹ́ ibi tó ní òkúta.

Wọ́n máa ń gbẹ́ tó sàárè méjìlá lójúmọ́.

"A ti gbẹ́ sàárè mẹ́jọ lónìí nìkan tí ọ̀sán kò ì tíì pọ́n, ó máa ń rí bẹ́ẹ̀ nígbà miran," Abdullahi tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sàárè gbígbẹ́ nígbà tó wà ní ogún ọdún sọ fún BBC.

Àwọn ẹbí náà ti là ìṣòro kọjá lórí iṣẹ́ wọn, pàápàá lásìkò tí ìjà ẹ̀sìn bá ń wáyé láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi àtàwọn Mùsùlùmí tó wà ní agbègbè náà.

Àwọn tó ń kírun sí òkú lára

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang / BBC

Àkọlé àwòrán, Ọjọ́ tí òkú bá jáde láyé ní wọ́n sábà máa ń sin wọ́n tó sì máa ń òkú méjìlá tí wọ́n máa ń sin lójúmọ́ ní Tudun Wada

"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjà ẹ̀sìn láàárín àwọn Mùsùlùmí àti àwọn Kristẹni ló ti wáyé àmọ́ èyí tí mi ò le gbàgbé ni ti èyí tó wáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1990," Magaji sọ.

"Níṣe ni a lọ ń ṣa àwọn òkú kúrò ní ojú títì láti sin wọ́n.

"Ìgbà tó lágbára gidi gan ló jẹ́ fún mi nígbà náà nítorí kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà náà àmọ́ ó fún mi ní ìpinnu láti tẹ̀síwájú."

Imam àdúgbò ló máa ń kéde ní mọ́ṣáláṣí lẹ́yìn ìrun tí èèyàn bá jáde láyé.

Àwọn olùjọsìn máa lọ síbi tí òkú náà bá wà láti lọ kírun sí òkú náà lára, lẹ́yìn náà ni wọ́n máa gbé òkú lọ sí itẹ́ láti lọ sin ín.

Lẹ́yìn tí wọ́n bá sin òkú náà tán ni àwọn tó ń ṣàmójútó itẹ́ náà yóò tọrọ kí wọ́n dá nǹkan jọ fáwọn.

Inuwa Mohammed
BBC
They were amazing people who loved what they did and have imbibed their children with this altruistic behaviour"
Inuwa Mohammed, 72, about his old bosses Ibrahim and Adamu Abdullahi

Bàbá kan, Inuwa Mohammed, ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin, òṣìṣẹ́ tó dàgbà jùlọ ní itẹ́ náà ló máa ń gba owó náà, tó sì sọ pàtàkì ẹbí Abdullahi fún ìlú náà.

Inuwa Mohammed ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Adamu àti Abdullahi kí wọ́n tó jáde láyé tó sì júwe bí ẹni tó ṣiṣẹ́ takuntakun, tí wọ́n tún fún ìlú, tí wọ́n tún fi kọ́ àwọn ọmọ wọn.

Owó díẹ̀ tí wọ́n bá rí gbà jọ ní wọ́n fi máa ń jẹun lọ́sàn-án àmọ́ tí kì í tó láti ṣe nǹkan míì.

Èyí ló mú àwọn òṣìṣẹ́ náà láti tún máa dá oko.

Aliyu ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun èlò iṣẹ́ ni àwọn kò ní àti pé kò sí ààbò tó péye ní itẹ́ náà báyìí nítorí apá kan odi rẹ̀ tó ti wó.

Ó ní èyí máa ń fún àwọn tó máa ń ṣa ilẹ̀ láàyè láti wọ inú ọgbà náà láti ṣa àwọn orin àlòkù lọ.

Sàárè òkú

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang / BBC

Àkọlé àwòrán, Ogójì ọdún ni wọ́n fi máa ń fi sàárè òkú sílẹ̀

Nígbà tí BBC ṣe àbẹ̀wò sí itẹ́ òkú náà láìpẹ́ yìí, a ri pé àwọn àyípadà ọ̀tun kan ti wáyé níbẹ̀.

Alága ìjọba ìbílẹ̀ tó ń mójútó agbègbè náà ti fi orúkọ àwọn ẹbí náà sínú àwọn òṣìṣẹ́ tí yóò máa gba owó oṣù lápò ìjọba.

Rayyan Hussain sọ fún BBC pé iṣẹ́ ńlá ni àwọn ẹbí náà ń ṣe lójúmọ́, tó sì tọ́ láti máa san owó fún wọn.

"Sàárè ni ilé ìkẹyìn fún gbogbo èèyàn, àwọn tó bá sì ń ṣe iṣẹ́ tó lágbára báyìí yẹ láti máa gba owó, wọn yóò máa gba owó oṣù níwọ̀n ìgbà tí mo bá ṣì jẹ́ alága."

Magaji fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gba owó oṣù

  • Àwọn márùn-ún tó dàgbà jùlọ ń gba ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógójì náírà (₦43,000)
  • Awon yòókù, tó fi mọ́ Abdullahi àti Aliyu ń gba ẹgbẹ̀rún ogún náírà (₦20,000)
Àwọn òṣìṣẹ́ itẹ́ méjì tó ń jẹun

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang / BBC

Àkọlé àwòrán, Iye tí ìjọba ń san fún àwọn òṣìṣẹ́ náà kéré sí owó oṣù tó kéré jùlọ ní Nàìjíríà

Iye yìí kéré sí ẹgbẹ̀rún àádọ́rin náírà (₦70,000) owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ tí ìjọba Nàìjíríà buwọ́lu fáwọn òṣìṣẹ́ lọ́dún 2024 àmọ́ Hussain ní ìrètí wà láti fi kún owó náà lọ́jọ́ iwájú.

Ó ní ó jẹ́ ohun tó ṣeni láàánú pé àwọn alága tó ti kọjá kò ṣe nǹkankan sí itẹ́ òkú náà.

Ó fi kun pé àwọn máa tún odi tó ti wó ọ̀hún kọ́, fi iná tó ń lo oòrùn síbẹ̀ àti ẹ̀ṣọ́ ààbò tí yóò máa ṣọ́ ibẹ̀.

"Mo ń gbèrò láti kọ́ yàrá kan sí itẹ́ náà láti fi máa wẹ òkú níbẹ̀ dípò bí wọ́n ṣe ti máa ń wẹ òkú wá láti ilé tẹ́lẹ̀.

Fún àwọn ẹbí Abdullahi, àwọn ìgbésẹ̀ tó da ni. Magaji ní òun gbà á lérò pé ọ̀kan nínú àwọn ọmọ mẹ́tàlélógún tí òun bí yóò máa mójútó itẹ́ náà lọ́jọ́ iwájú.