Alábàṣiṣẹ́ Mukaila Ṣẹnwẹlẹ ṣàlàyé ohun tó ṣe kẹ́yìn kó tó jáde láyé

Mukaila Senwele

Oríṣun àwòrán, Mukaila Senwele Fans

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹni to n ṣe akoso olorin ẹfẹ lati ilu Ilorin to di oloogbe, Alaaji Mukaila Ẹsinrogunjo ti ṣalaye bi igba ikẹyin rẹ ṣe ri ko to jade laye.

Alakoso oloogbe naa, Ibrahim Toebb ṣalaye fun BBC Yoruba pe lẹyin ti oloogbe ọhun kinrun tan lo gbẹmi mi.

O ni "Ori ijoko naa ni wọn wa. Bi a ṣe kinrun tan, wọn dẹ joko lori aga ni nnkan bii aago marun un kọja iṣẹju diẹ ni irọlẹ.

"A ko lọ si ibikankan, nitori awọn kan n gbe iroyin kiri pe ori itage ni wọn ti ku."

Toebb sọ pe ko si aarẹ kankan to ṣe oloogbe ọhun ṣaaju iku rẹ.

O sọ siwaju si pe oloogbe naa kọ orin meji lalẹ ana pẹlu ileri pe aarọ oni to jade laye ni wọn yoo gbe orin naa si ori itakun agbaye ki iṣẹlẹ ọhun to waye.

O ni "A sọ pe a n lọ si Eko laarọ yii o, wọn kan ṣe 'Ah,' Ah yẹ naa nikan ni wọn ṣe ti wọn si dakẹ bẹẹ.

"A dẹ gbe wọn digba digba lọ sile iwosan ijọba apapọ, amọ ki a to de ibẹ wọn ti ku."

Mukaila Ṣẹnwẹlẹ, olórin ẹ̀fẹ̀ ti jáde láyé

Oloogbe Mukaila Senwele
Àkọlé àwòrán, Oloogbe Mukaila Senwele

Gbajugbaja olorin ẹfẹ lati ilu Ilorin, Alaaji Mukaila Ẹsinrogunjo, ti gbogbo eeyan mọ si Mukaila Senwele ti jade laye.

Ana, ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni Oloogbe Mukaila papoda.

Ohun ti a gbọ ni pe Mukaila Senwele ko ṣe aisan rara ki ọlọjọ too de, ile la gbọ pe o wa pẹlu awọn ololufẹ rẹ.

Ọkan lara awọn ọrẹ Oloogbe to ba BBC sọrọ, sọ pe Mukaila ṣeleri pe ohun yoo yọju si ile mọlẹbi awọn bi ohun ba ti ṣetan.

O ni ṣadeede ni wọn pe awọn lati ile to wa, igba ti awọn yoo si fi debẹ, olorin ẹfẹ naa ti jade laye.

''Mukaila ṣì kọrin lọ́jọ́ tó ku ọ̀la tó máa kú''

Lasiko to n ba aṣojukọroyin BBC sọrọ, ọkan lara awọn aburo oloogbe Mukaila, Ọgbẹni Kehinde, sọ pe Mukaila kọrin niluu Ilọrin lỌjọbọ, iyẹn ọjọ tu ku ọla to maa jade laye.

O ni lẹyin to de lati ode orin ọhun lo bẹrẹ si i gbaradi fun ere to ni niluu Eko lalẹ oni ọjọ Satide.

Lojiji ni ẹnikan pe e lori ẹrọ ibanisọrọ bi aburo rẹ ṣe wi, bo ṣe ba ẹni naa sọrọ tan lo bẹrẹ si i ṣubu diẹdiẹ ti wọn si sare gbe e digba-digba lọ sile iwosan Jẹnẹra ilu Ilọrin.

Ile iwosan naa ni wọn ti fi diẹ mulẹ pe Mukaila Senwele ti jade laye.

Àwọn abanikẹdun ti kun ile awọn obi Mukaila ni Pakata, ile Ẹsinrogunjo, Ilọrin.

Awon abanikedun
Àkọlé àwòrán, Awon abanikedun

Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti n ya lọ si ile awọn obi Oloogbe Mukaila Senwele, lati ba wọn kẹdun.

Ile naa to wa ni Adabata ni a mọ si ile Ẹṣinrogunjo.

Lasiko to n sọrọ, ọkan lara awọn mọlebi Oloogbe, Ọgbẹni Wasiu, juwe iku Mukaila Senwele gẹgẹ bi ohun to ba a lojiji pupọ.

Tẹ o ba gbagbe, Mukaila Senwele jẹ gbajugbaja olorin ẹfẹ, ti orin rẹ maa n pa ọpọ eeyan lẹrin-in.

Ọmọ bibi ilu Ilorin, nipinlẹ Kwara ni, ṣugbọn ilu Eko lo fi ṣe ibugbe.