Ẹ gbé èsì àyẹ̀wò ikú ọmọ wa, Olatunji Jimoh tó kú s'átìmọ́lé ọlọ́pàá síta - Mọ̀lẹ́bí rọ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Aworan lati ibi iwọde awọn mọlẹbi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lẹyin osu kan ati ọjọ mẹrin ti Olatunji Jimoh, ẹni ọdun marundinlogoji (35), ku si atimọle awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, awọn ẹbi ati agbegbe Balogun Fulani ni iluu Ilorin ti beere pe ki ajọ ọlọpaa gbe esi ayẹwo iku oloogbe naa ti wọn se sita ni kiakia.

Nigba to n ba awon oniroyin sọrọ niluu Ilorin lọjọ Ẹti, Onigbọwọ fun Idajọ Ododo fun Olatunji Jimoh (Justice for Olatunji Jimoh) Ọgbẹni Owolabi Olumuyiwa Tayo, tun rawọ ẹbẹ si ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lati gbe awọn to lọwọ ninu iku oloogbe naa re ileẹjọ ni waransesa.

Tẹ o ba gbagbe, Olatunji ku si atimọle ile-iṣẹ ọlọpaa Naijiria ni Ilorin, ipinlẹ Kwara ni ogunjọ Oṣu kejila, ọdun 2024 lẹhin ti wọn mu u fun ẹsun jijẹ ọga rẹ nibi iṣẹ, Gabriel Sunday ni owo N220.

Olugbọwọ fun Idajọ Ododo fun Ọlatunji Jimoh sọ pe wọn ko fun ẹbi Olatunji ni ẹda esi idanwo iku Olatunji lati igba ti awọn gbọ pe wọn ti fi sọwọ si Ileesẹ ọlọpaa ni ọsẹ meji sẹhin.

"Irọ kan ni wọn n pa, ti won si n dari wa sọdọ dokita, ti ohun naa si da wa pada si ọdọ wọn, wọn si ti mọ daju pe, abajade esi naa ko fi han rara pe oloogbe Olatunji pokunso ni atimọle gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Ẹbi oloogbe naa ati agbegbe Balogun Fulani ti Ilorin wa rọ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lati da si ẹjọ naa, "gẹgẹ bi baba ati gẹgẹ bi olori aabo ti ipinle naa".

Wọn ni bakanna ni awọn ti kọ iwe ranse si Emir llorin, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari, lati da si oro naa pẹlu.

"A n pe Ile Igbimọ Asofin, Orilẹ-ede Naijiria lati ṣe iranlọwọ nipa iwadii to peye lori ọrọ naa ti o gba omije loju ẹni to si tun sọ ọpọ eniyan sinu laasigbo.

"Nitoripe ti a ba fi wọn silẹ laisi ijiya, Naijiria n sun lori bombu akoko kan ti yoo bu gbamu laipẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ti ko kun oju osuwọn".

Idile naa sọ pe oloogbe Ọlatunji fi awọn ọmọde meji ati awọn obi ti o ti dagba, ti wọn si n gba itọju lọwọ

ni ileewosan gbogbogbo ti ipinlẹ Kwara saye lọ.

Wọn ni lọwọ bayii, awọn ẹbi naa n ṣọfọ, ni irora ati ibanujẹ, wọn si n kegbe pe, ijiya awọn ara ilu ati alaiṣẹ gbọdọ dopin lọwọ awọn ọlọpaa eke.

Ki ni idahun Ọlọpaa?

BBC News Yoruba kan si agbẹnusọ ọlọpaa ni Kwara, SP Ejire Adeyemi Adetoun lati fesi si ẹsun ti wọn fi kan wọn.

O ni ohun ti o kan ni ki awọn gbe awọn ọlọpaa to lọwọ ninu ọrọ naa re ileẹjọ.

Adetoun ni idi ti awọn fi ṣe ayẹwo iku ọkunrin naa kii se tori nkan mii to kọja ileẹjọ.

O ni awọn mọ wi pe ileẹjọ yoo bere esi ayẹwo iku rẹ nigba ti ẹjọ ba de ipele kan, lawọn se mura kalẹ ki igba naa to ko.