Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde pàdánù ẹ̀gbọ́n rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/x
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi makinde ti pàdánù ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Sunday Makinde.
Àtẹ̀jáde kan tí olùbádàmọ̀ràn gómìnà Seyi Makinde lórí ètò ìròyìn, Sulaimon Olanrewaju fi léde lọ́jọ́ Ẹtì ní ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin ni olóògbé kó tó jáde láyé.
Olanrewaju ṣàlàyé pé ẹbí olóògbé náà, tó tún jẹ́ Bada Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan àti olórí ẹbí ìdílé Aigbofa ní Oja'ba, Ibadan, Olumuyiwa Makinde ló kéde ikú náà.
"Pẹ̀lú ọkàn tó gbọgbẹ́ ni mo fi kéde ikú ẹ̀gbọ́n mi, onímọ̀ ẹ̀rọ Sunday Makinde tó dágbére fáyé lónìí, ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kìíní, 2025.
"Ní nǹkan bí aago méjì kọjá ogún ìṣẹ́jú òru ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ilé rẹ̀ tó wà ní ìlú Ibadan.."
Àwọn ọmọ, ọmọọmọ àti ẹbí èyí gómìnà Seyi Makinde jẹ́ ọ̀kan lára wọn ló gbẹ̀yìn olóògbé gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ.
Atẹjade naa ko sọ oun to ṣe okunfa ipapoda rẹ.











