Lẹ́yìn tí iléẹjọ́ fún un ní béèlì, Oriyomi Hamzat gbàlejò akọrin Fuji, Saheed Oṣupa

Oríṣun àwòrán, Free World TV
Gbajugbaja olorin Fuji, Saheed Oṣupa ṣe abẹwo atilẹyin si olokiki agbohunsafẹfẹ, Oriyọmi Hamzat niluu Ibadan lẹyin ọjọ diẹ ti wọn gba beeli rẹ nile ẹjọ.
Aworan to fọn kiri ori itakun ayelujara ṣe afihan abẹwo naa to waye l'Ọjọbọ nile iṣẹ redio Agdigbo FM to n bẹ l'opopona Ọjọọ niluu Ibadan, gẹgẹ bi ọkan lara awọn eeyan to wa ni ibi ipejọpọ naa ṣe ṣalaye fun akọroyin wa pe abẹwo naa niiṣe pẹlu anfani ti wọn fun Hamzat lati wa maa j'ẹjọ lati ile lẹyin ti wọn gbe beeli rẹ nile ẹjọ.
Ninu ọrọ to sọ lasiko abẹwọ naa, Oṣupa ki Oriyọmi ku imoribọ, gẹgẹ bi o ṣe n gbadura wi pe Ọlọrun ko ni jẹ ko ri wahala mọ.
O tẹsiwaju wi pe gbogbo ẹni to ba ti n ja fun ẹtọ ọmọniyan ati mẹkunnu, inu awọn eniyan kii saba dun sii delẹ delẹ.
Saheed Oṣupa ni, "Mo ni ki n wa ki ẹ ni pe o ku... Ṣe o ku ewu ni maa pe e ni abi o ku imoribọ.
Ọlọrun ko ni jẹ ki a ri wahala. Ẹni to ba ti n ja fun ẹtọ ọmọniyan to dẹ n ṣe bii olugbeja mẹkunnu, inu awọn eniyan kii saba dun sii delẹ delẹ."
"Ero awọn eeyan buruku si iru eeyan bẹẹ, bii ko wọ inu wahala ki wahala ṣẹlẹ sii, oriṣiriṣi okun ni awọn aye maa dẹ."
Ki lo ṣẹlẹ saaju asiko yii?
Olori Ooni Ile-Ife tẹlẹri, Naomi Ṣilẹkunọla ṣe agbekalẹ apejẹ opin ọdun fun awọn ọmọde niluu Ibadan. Ọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024, ni eto naa yẹ ko waye, amọ gbogbo rẹ foriṣanpọn nitori i wọlukọlu to ṣẹlẹ nibi eto naa. Awọn ero to yawọ oriko eto naa pọju iye eeyan ti wọn pese aye fun, eyii si ṣokunfa bi ọmọde marundinlogogi ṣe pade iku aitọjọ gẹgẹ bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe sọ.
Lara awọn eeyan ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fi ẹsun kan lori iṣẹlẹ aburu naa ni Naomi Ṣilẹkunọla, Oriyọmi Hamzat to ṣe ipolongo eto naa lori redio ati alakoso ile ẹkọ 'Islamic Secondary School' ti iṣẹlẹ naa ti waye, Fasasi Abdullahi.
Ninu oṣu kejila ọdun 2024 kan naa ni wọn gbe awọn eeyan naa lọ si iwaju ile ẹjọ Majisireeti kan ni agbegbe Iyaganku ni ilu Ibadan nibi ti adajọ ti ni ki wọn gbe wọn ju si ahamọ ọgba ẹwọn titi di igba ti ẹka olupẹjọ nileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Ọyọ yoo fi yanju ọrọ nipa igbẹjọ wọn.
Ṣugbọn lọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun 2025 ni ile ẹjọ giga to n bẹ ni agbegbe Ring Road niluu Ibadan gba beeli awọn mẹtẹẹta to si fun wọn ni anfani lati wa maa j'ẹjọ lati ile.
Oriyọmi Hamzat ti pada si ẹnu iṣẹ rẹ lẹyin ti wọn gba beeli rẹ, o si fi omijẹ ba awọn ololufẹ rẹ sọrọ pẹlu alaye wi pe "akoko lati dakẹ jẹ niyii."
Saheed Oṣupa ni gbajumọ akọkọ ti yoo ṣe abẹwo ita gbangba si olokiki agbohunsafẹfẹ naa lati igba ti ori ti koo yọ ni ọgba ẹwọn.















