Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá Rahmon Adedoyin láre lórí ọ̀rọ̀ ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ Adegoke, ilé ìtura Hilton hotels

Oríṣun àwòrán, others
Ile ẹjọ kotẹmilọrun to fi ikalẹ si ilu Akurẹ ni ipinlẹ Ondo, ẹkun iwọ oorun gusu Naijiria ti gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ kotẹmilọrun ti oludasilẹ ile itura Hilton Hotels ni ilu Ile Ifẹ ni ipinlẹ Ọṣun, Oloye Rahamon Adedoyin pe lori idajọ iku ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun da fun un lori iku akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo University, OAU kan, Timothy Adegoke to wọ si ile itura naa.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ile ẹjọ naa duro pẹlu idajọ naa pe oun faramọ idajọ iku ti wọn da fun eekan olowo ati alamojuto eto ẹkọ naa, sibẹ awọn idajọ ile ẹjọ giga to kọkọ da ẹjọ naa kan wa ti ile ẹjọ ọhun tako to si wọgile.
Pataki lara idajọ naa ni eyi ti wọn ti ni pe oloye Rahamon Adedoyin ni yoo maa mojuto idagbasoke eto ẹkọ awọn ọmọ oloogbe naa.
Gẹgẹbi ọrọ ti ọkan lara awọn amofin to gba ẹjọ ro lasiko igbẹjọ naa ṣe sọ, ile ẹjọ kotẹmilọrun naa sọ pe ile ẹjọ giga ko lẹtọ lati paṣẹ fun ọdaran naa lati gbe bukata sisan owo ileẹkọ awọn ọmọ Adegoke.
O ni o kọja ilakalẹ ojuṣe rẹ labẹ ofin lati maa wọn ianran ti ko si ninu ilana ofin fun awọn to ba wa siwaju rẹ.
Bakan naa ni ile ẹjọ naa tun wọgile idajọ ile ẹjọ giga naa to ni ki wọn gbẹsẹle ile itura Hilton Hotels to jẹ dukia Oloye Adedoyin nibi ti iṣẹlẹ iṣekupani naa ti waye
Bi wọn ṣe kọkọ da ẹjọ iku fun Oloye Adedoyin ṣaaju ni ile ẹjọ giga l'Ọṣun

Oríṣun àwòrán, @adedoyin
Lọgbọn ọjọ oṣu karun un ọdun 2023 ni ile ẹjọ da ẹjọ iku fun oloye Adedoyin atawọn oṣiṣẹ ile Itura rẹ kan.
Adajọ agba ipinlẹ Ọṣun nigba naa, Adepele Ojo lo da ẹjọ ọhun.
Ile ẹjọ naa gbẹsẹ le iwe iwadii ohun to ṣokunfa iku oloogbe Timothy Adegoke ti awọn akọṣẹmọṣẹ ayẹwo nipa oku meji lati fasiti OAU nilu Ile Ifẹ fọwọ si lori pe awọn to lọwọ ninu igbẹjọ to wa nilẹ naa jẹ ẹni mimọ wọn.
Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Adepele Ojo fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni Timothy Adegoke wọ sinu ile itura Hilton Hotel, o si sanwo sinu aṣuwọn ifowopamọsi olujẹjọ keje.
"Mo rii pe olujẹjọ akọkọ, (Ramon Adedoyin) jẹbi ẹsun igbimọ lati paniyan ati ẹsun ipaniyan."
Ile ẹjọ naa tun fi kun un pe ẹri to wa niwaju ilẹ ẹjọ ọhun fihan pe Oyetunde Kazeem wa lara awọn to ṣe iṣẹ ibi naa, nitori eyi oun pẹlu jẹbi ẹsun wọnyii.
Oloye Adedoyin di ero ile ẹjọ pẹlu awọn mẹfa lara awọn oṣiṣẹ rẹ lori ẹsun mejidinlogun to nii ṣe pẹlu ipaniyan, igbimọpọ lati ṣekupani pẹlu imulẹ atawọn ẹsun miran.
- Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fòntẹ̀ lu ìdájọ́ ikú fún Ramon Adedoyin fún ipa tó kó nínú ikú Timothy Adegoke
- Ǹjẹ́ Alaafin Oyo tuntun lè rìnrìn àjò lọ sókè òkun láì tíì wọ Ìpẹ̀bí? Àlàyé rèé
- Ẹ wo bí ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Adedoyin pè tako ìdájọ́ ikú rẹ̀ ṣe lọ ní Akure
- Raheem Adedoyin ọmọ Olóyè Rahmon Adedoyin tí di ọ̀daràn tí wọ́n wá káàkiri àgbayé títí ọwọ́ òfin yóò fi tẹ̀ẹ́!– Adájọ́

Adajo Àgbà ile ejo giga ni ilu Osogbo ipinle Osun, Onidajo Adepele Òjó, ti so pe pelu gbogbo ẹ̀sùn tí wọn fi kan ẹniti o ni ile ìtura Hilton àti ẹri to wa niwaju oun, fi han gbangba pe Dokita Adedoyin lowo ninu iku Timothy Adegoke.
Ninu idajọ to gbe kalẹ lori ẹjọ naa, ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun tu mẹta ninu awọn olujẹjọ silẹ labẹ ẹsun ipaniyan, igbimọ pọ lati ṣeku pani.
Awọn ti wọn tu silẹ naa ni Magdalene Chiefuna, Lawrence Oluwole ati Adedeji Adesola.
Amọṣa, Onidajọ Adepele Ojo ni wọn jẹbi awọn ẹsun yoku.
Amọṣa Adajọ naa ni Oloye Adegoke Adedoyin jẹbi ẹsun ikini, ikeji, ikẹta, ikeje, ikẹsanan, ikarundinlogun ati ikẹrindinlogun.
Awọn oṣiṣẹ ile itura naa mẹta ti ile ẹjọ da lẹbi pẹlu Oloye Adedoyin ni Adeniyi Aderogba, Oyetunde Kazeem ati Adebayo Kunle.
Rahmon atawọn yooku gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ

Adari ileeṣẹ ile itura Hilton Hotels ni Ile Ife nipinlẹ Osun, Dokita Ramọn Adedoyin gba ileẹjọ kotẹmilọrun lọ lẹyin ti adajọ da ẹjọ iku fun lori iṣekupani akẹkọọ fasiti OAU, Timothy Adegoke.
Ileẹjọ giga nipinlẹ Osun lo da ẹjọ pe ki wọn yegi fun nitori o lọwọ ninu iku arakunrin naa to sun si ile itura rẹ.
Ti a ko ba gbagbe, adajọ Adepele Ojo lo ran Adedoyin ati oṣiṣẹ rẹ meji ti wọn gbe oku naa kuro ni ile itura naa, Adeniyi Aderogba ati Oyetunde Kazeem pe ki wọn yẹ igi fun.
Bakan naa ni adajọ ni ijọba ti gbegile ile itura naa, ti o si ti da ti ijọba.
Adajọ tun ni ohun ini Adedoyin ni wọn yoo fi ran awọn ọmọ Adegoke lọ si ileẹkọ titi wọn yoo fi jade fasiti.
Amọ adajọ naa fi awọn oṣiṣẹ mẹta silẹ, Magdalene Chiefuna, Oluwole Lawrence ati Adebayo Kunle ki wọn maa lọ ni alaafia, ti akọwe to wa ni ibi isẹ naa si gba idajọ ẹwọn ọdun meji fi jura.
Nibayii ni Ramon Adedoyin ti ni oun ko faramọ idajọ iku naa, to si ti gba ileẹjọ naa.
Ọkan ninu awọn adajọ Adedoyin, Adajọ agba Kunle Adegoke lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Bakan naa lo ni ileẹjọ kotẹmilọrun ni ilu Akure, nipinlẹ Ondo ni wọn gbe ẹjọ naa lọ.















