Ẹ̀gbọ́n àti àbúrò jóná mọ́lé, bàbá di èrò ilé ìwòsàn l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Ayodele Popoola
Ọjọ buruku esu gbomi mu ni Ọjọru ọsẹ yi jẹ lagbegbe Oluwatuyi n'ilu Akure bi egbọn ati aburo ṣe jo mọle.
Ijamba ina naa to waye ni deedee ago kan abọ ọsan ana jo yara ti awọn ọmọ naa ha si di eeru.
Awọn ọmọde naa Jenson, ẹni ọdun mẹta ati Jenlite, ẹni ọdun marun-un ni wọn jo mọle bi o ti ẹ jẹ pe gbogbo awọn olugbe agbegbe naa sa gbogbo ipa wọn lati doola ẹmi awọn ọmọ naa, sugbọn yara ti wọn wa lo wa ni titi pa.
Ohun to fa ijamba ina yi ni ko ti di mimọ si ẹnikẹni.

Oríṣun àwòrán, Ayodele Popoola
Gẹgẹ bi awọn olugbe agbegbe naa se sọ, iya awọn ọmọ naa lo ti wọn mọ yara, to si lọ si ọjọ lai bikita ipo ti awọn ọmọ naa yoo wa titi yoo fi de lati ọja naa.
Wọn salaye pe enikan lo kọkọ ri ina naa sugbọn ko lero pe awọn ọmọde le wa ninu ile ti ijamba naa ti waye lasiko ti o ri ina naa.
Ọkan lara awọn aladugbo Ibrahim salaye pe ṣe ni wọn dede gbọ ariwo awọn ọmọ naa lati inu yara, sugbọn gbogbo akitiyan lati pa ina yi ki wọn le doola ẹmi awọn ọmọ naa lo jasi pabo.
Ibrahim sọ pe o se n se ki iya awọn ọmọ naa tan gas silẹ ki o to kuro nile.
" A sa gbogbo ipa wa lati wọ inu ile naa, sugbọn pabo lo jasi, lẹyin eyi la pe Ajọ panapana lati ran wa lọwọ, sugbọn pabo naa ni gbogbo rẹ jasi.
Iṣẹlẹ yi lo jẹ iyalẹnu nla fun gbogbo awọn olugbe Oluwatuyi, bi wọn ṣe ba baba awọn ọmọ naa kẹdun.
Awọn olugbe agbegbe naa salaye pe baba awọn ọmọ naa daku ni kete to ri oku awọn ọmọ rẹ, ti wọn si gbe lọ ile iwosan fun itọju.















