Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Àkójọpọ̀ àwọn ìròyìn káàkiri Nàìjíríà tí kò ṣe é má gbọ̀ ọ́.
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Ídajọ tiwa naa ni pe, ẹ lọ yẹgi fun un

Yẹgi fun ta a ni?

Bẹẹ la a bini o, ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Akure lo fọntẹ lu idajọ iku t'ileẹjọ giga ipinlẹ Osun ti da tẹlẹ fun Oloye Ramon Adedoyin lori iku Timothy Adegoke akẹkọọ fasiti OAU

Ẹkunrẹrẹ wa loju opo BBC.Com/Yoruba

''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Ẹyin obinrin eti yin meloo?

Maa wi, awọn naa n gbọ ẹ.

Ẹ tete bẹsẹ yin sọrọ niniu igbeyawo to ba ti mu iwa ipa dani

Kọmiṣọna fọrọ awọn obinrin nipinlẹ Anambra lo sọrọ yii lẹyin ti ọkunrin kan danu sun iyawo rẹ nipinlẹ naa

Haha ki lo to bẹẹ, ki lo ṣẹlẹ gan an?

Alaye wa lori ikanni BBC Yoruba

'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Gomina Abba Yusuf Ipinlẹ Kano ti ṣalaye idi to fi pin ẹran ọsin ewurẹ to le lẹgbẹrun meje fawọn obinrin ipinlẹ ọhun

Ṣo fẹ dawọn lokowo iṣẹ alapata ni?

Rara o, Gomina ni oun ṣeto yii fun ironilagbara awọn obinrin ati lati mu adinku ba iṣẹ to n bawọn eeyan finra nipinlẹ Kano ni

fun ẹkunrẹrẹ.