Ọkùnrin tó dáná sun ìyàwó rẹ̀ ṣàlàyé ìdí abájọ

Oríṣun àwòrán, Anambra State police
Ọkunrin kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Nwanna ni abule Abagana nipinlẹ Anambra ti sọ idi to fi dana si iyawo rẹ Chioma lara ti obinrin naa si gba ibẹ ku.
Ọjọ Iṣẹgun ọjọ kọkanlelogun oṣu Kinni ọdun yii ti iṣẹlẹ yii ni abule Abagana nipinlẹ Anambra eyi ọkunrin naa ti sọ pe oun kabamọọ rẹ bayii.
Ọgbẹni Nwanna to wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa Anambra bayii ṣalaye wi pe iṣẹlẹ ọhun waye lasiko toun ati iyawo oun n ja.
Ọgbẹni Nwanna sọ fawọn ọlọpaa wi pe nigba tawọn mejeeji n ja ni iyawo oun lọ mu nnkan lati fi ṣe oun leṣe.
O ni eyi lo jẹ koun da epo si i lara ti oun si ṣana si i lara pẹlu.
Nwanna ni oun gbiyanju lati fi omi pa ina lara iyawo oun, amọ, ina naa ti jo Choima pupọ.
Ohun to fa ija laarin Nwanna ati Chioma iyawo to dana sun
Nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa beere ohun to fa ija laarin Nwanna ati iayawo rẹ, o ṣalaye pe Chioma maa n kuro nile lai sọ ibi to n lọ foun, o si tun maa n pada sile nigba ti ilẹ ba ti ṣu.
''Ni gbogbo igba ni Chioma maa n jade lọ lai sọ ibi ti o n lọ fun mi, ti o si maa n pẹ ki o to pada de.
Nigba mii, aago mọkanla si mejila lalẹ ni iyawo mi maa n pada wọle to ba ti jade lọ,'' Nwanna ṣalaye.
Nwanna ni oun ko gbero lati pa Chioma tori oun ni ifẹ rẹ, koda, o tọrọ idarijin fun nnkan ti o ṣe.
Ọjọru ọjọ kejilelogun oṣu Kinni ni Chioma pada ku nitori ina to jo lara pọju.
Kọmiṣọna fun ọrọ awọn obinrin ni ipinlẹ Anambra, Ify Ibinabo, sọ pe iwadii ti fi han pe kii ṣe igba akọkọ niyi ki ọkunrin naa ti maa n dunkoko lati pa iyawo rẹ.
Kọmiṣọna ni awọn ọmọ rẹ ṣalaye pe baba awọn ti fi igo lu mama awọn ri.
Awọn alabagbe wọn naa ṣalaye wi pe ni gbogbo igba ni awọn tọkọ taya naa maa n ja.
Kọmiṣọna wa rọ awọn lọkọ laya lati fi ọgbọn ṣe e, o ni o san ki eeyan kuro ninu igbeyawo lọ ju ki ẹmi rẹ bọ sibẹ.















