Ọ̀rọ̀ Trump nípa akọ àti abo kò kàn mí, obìnrin ni mí, mo sì ní ẹ̀rì tó dájú – Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky
Gbajumọ ọkunrin to maa n mura bii obinrin, Idris "Bobrisky" Okuneye ti sọ pe ọrọ ti Aarẹ Amẹrika tuntun, Donald Trump sọ nipa ẹya akọ ati abo kan oun.
Bobrisky lo sọ ọrọ naa loju opo Instagram rẹ nibi to si sọ pe oun yoo fi ẹri han pe obinrin ni oun lọjọkọjọ ti irinajo bag be oun lọ silẹ naa.
Ṣaaju ni Aarẹ Trump ti kọkọ sọ lọjọ iburawọle rẹ pe ẹya akọ ati abo nikan ni ofin orilẹede naa yoo da mọ lati ọjọ naa lọ.
Ikede Trump ọhun wa lara awọn aṣẹ tuntun to ṣẹṣẹ buwọlu pe ko ni si iṣakọ-ṣabo tabo iṣabo-ṣakọ mọ nilẹ ọhun.
O ni "Lati asiko yii lọ, yoo jẹ aṣa ijọba ilẹ Amẹrika pe ẹya meji pere ni a ni, ọkunrin ati obinrin."
Lẹyin ikede ọhun ni ọpọ ọmọ Naijiria bẹrẹ si n woye pe nibo ni Bobrisky yoo ya si ninu ẹya mejeji naa.
Eyii ko ṣẹyin pe bo tilẹ jẹ pe ọkunrin ni Bobrisky gẹgẹ bii iwadii awọn ọga ẹlẹwọn lasiko to ṣẹwọn lọdun to kọja, ṣugbọn o maa n mura, o si maa n pe ara rẹ ni obinirn.
Nigba to n fesi si ibere awọn eeyan, o ni obinrin ni oun, nitori oun ti lọ ṣe awọn iṣẹ abẹ to yẹ lati parada lati ẹya ọkunrin si obinrin.
O sọ ninu atẹjade rẹ ọhun pe "Mi o ni idunadura kankan pẹlu Trump. Ṣebi Trump ti sọ pe ẹya ọkunri ati obinrin nikan kan ṣoṣo lo wa abi?"
"Mo dẹ ti sọ ṣaaju pe obinrin ni mi bayii lẹyin ti mo ti ṣe awọn ohun to yẹ ki n ṣe. Ti wọn ba bere ẹri, mo maa fun wọn ni ẹri pe obinrin ni mi, ko ju bẹẹ lọ."
Bobrisky pari ọrọ pe ki awọn eeyan sinmi agbaja lori ọrọ ti Aarẹ Amẹrika naa sọ.
O fi kun pe ko si ewu loko longẹ niwọn igba ti Trump ko tii fi opin si igbeyawo laarin akọsakọ tabi abosabo.















