Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń bú Èsúsú nínú Sinimá 'Seven doors' ni inú máa ń bí mi – Aliu Gafar tó ṣe Esusu nínú Sinimá Seven doors

Àkọlé fídíò, Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń bú Èsúsú nínú Sinimá Seven doors, àmọ́ ṣé Èsúsú jẹ̀bi ni? – Aliu Gafar
Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń bú Èsúsú nínú Sinimá 'Seven doors' ni inú máa ń bí mi – Aliu Gafar tó ṣe Esusu nínú Sinimá Seven doors

Ni oṣu diẹ ni sinima kan jade sori igba eyi ti o gbe orukọ ọkan lara awọn ipa to wa ninu rẹ soke.

Esusu ni ipa ti a n sọrọ rẹ yii, Seven doors si ni orukọ sinima naa.

Ọgbẹni Aliu Gafar to ko ipa naa ṣalaye fun BBC pe ipa naa ti sọ oun di olokiki kaakiri gbogbo agbaye.

O ni orilẹede Canada loun wa nigba ti wọn pe oun fun ere naa. O ni igba ti oun de ibudo ti wọn ti fẹ ṣe ere ọhun ni oun rii pe ohun to ga gidi ni.