''Mo máa ń ná tó N300,000 fún oúnjẹ ajá mi lóṣù torí ìṣepàtàkì ajá''

Àkọlé fídíò, Olowo aja
''Mo máa ń ná tó N300,000 fún oúnjẹ ajá mi lóṣù torí ìṣepàtàkì ajá''

Oju ọtọọtọ lawọn eeyan fi maa n wo nnkan ọsin, fun ọpọlọpọ awọn eeyan, ohun ọsin jẹ bii ọrẹ ati orisun ayọ nigba ipọnju.

Fun awọn miran, nnkan ọsin kan dabi ohun ini lasan ninu ile.

Amọ, si awọn eeyan kan, nnkan ọsin dabi eeyan ẹlẹran ara bi ti wọn naa ni pẹlu bi wọn ṣe maa n kẹ wọn gẹgẹ.

Ọkan lara iru awọn eeyan bayii ni Ọgbẹni Iyke Elueze to n sin aja nile rẹ.

Elueze sọ pe nnkan ọsin oun daabo bo oun nigba ti oun ni arun irẹwẹsi ọkan.

Elueze ni aja oun ti orukọ rẹ n jẹ Hennessy ṣe iranwọ nla foun lasiko naa tori oun lo jẹ bii oogun foun lasiko naa.

O ni oun ko le jẹ ki ebi pa aja oun laelae tabi jiya.

''Ounjẹ ti mo maa n ra ni N30,000 fun aja mi tẹlẹ ti di N165,000 bayii.

Mo maa n na to N280,000 si N300,000 lori ounjẹ awọn aja mi nikan loṣu,'' Elueze lo sọ bẹẹ.

Arabinrin Jackie Idumogu to jẹ ọlọsin aja to da ileeṣẹ kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni ''My Dog & I'' sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ko tii bimọ toun, o ni oun ko ri iyatọ laarin ara oun gẹgẹ bi iya fun aja ati gẹgẹ bii eeyan.

Idumogu ni ''bi ounjẹ aja ṣe wọn gogo lọja bayii lo jẹ koun maa se ounjẹ funra oun fawọn aja.

Ọdọbinrin Mistura Ibrahim ni ifẹ oun si nnkan ọsin gbilẹ si nigba toun doola ologbo meji bi ọdun meji sẹyin.

Mistura ni awọn eeyan kan lo fẹ sọ oko pa awọn ologbo ọhun koun to gbe wọn wọle.

O ni lẹyin naa loun gbe awọn ologbo ọhun fawọn to fẹ maa sin wọn.

Mistura ni ni bo tilẹ jẹ pe ounjẹ nnkan ọsin ti gbowo lori, o ni ounjẹ toun ba n jẹ lawọn nnkan ọsin oun naa maa n jẹ.

Awọn eeyan yii gbagbọ pe iha ti ọpọ eeyan n kọ si awọn nnkan ọsin buru jai.