Ta ni Rasaq Okoya tọ́rọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ ń fa awuyewuye lórí ayélujára?

Rasaq Okoya

Oríṣun àwòrán, SHADE.OKOYA/INSTAGRAM

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ní bí ọjọ́ méjì sẹ́yìn báyìí ni awuyewuye ti ń lọ lórí ayélujára lórí àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ èèkàn oníṣòwò nnì, olọyè Rasaq Okoya.

Èyí kò ṣẹ̀yìn fídíò kan táwọn ọmọkùnrin náà, Wahab àti Raheem fi sórí ayélujára léyìí tó ṣàfihàn ọlọ́pàá kan tó báwọn gbé owó dání, tí wọ́n sì ń ná owó náà.

Rasaq Okoya jẹ́ èèyàn tó gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá àti Nàìjíríà fún iléeṣẹ́ rẹ̀, tí wọ́n ń pèsè ohun èlò ilé.

Ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ òde òní mọ́ mọ ẹni tí Rasaq Okoya títí di ìgbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣàfihàn ara wọn nínú fídíò tí wọ́n ti kó ọ̀bítíbitì owó dání.

Ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó gba ẹnu àwọn èèyàn lórí ayélujára lẹ́yìn tí fídíò náà gbòde ni pé kí ló fà á tí ọlọ́pàá fi máa gbé owó dání fáwọn ọmọ ọ̀hún.

Èyí ló mú wa tọná wádìí ẹni tí Rasaq Okoya jẹ́ gan-an.

Ọlọ́pàá tó báwọn ọmọ Okoya gbówó dání nínú fọ́nrán tó ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ń tàbùkù owó náírà dèrò àhámọ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti kede pe awọn ti mu ọlọpaa to wa ninu fọnran kan to lu sita lori ayelujara nibi ti o ti ba awọn ọmọ ọkunrin gbajugba onisowo, Oloye Razaq Okoya gbe owo dani.

Bo ti le jẹ pe wọn ko kede ọrọ orukjọ ọlọpaa naa sita.

Ikede yii lo wa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Olumuyiwa Adejobi gbe soju opo ikanni X rẹ lọjọ Ẹti.

Gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye, o ni ohun ti ọlọpaa naa se ni ko ba ofin mu, to si tabuku si ilana ti ileeṣẹ ọlọpaa n tẹle.

O jẹ ko di mimọ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati fi iya to yẹ jẹ ọlọpaa naa.

"Ọlọpaa to wa ninu fọnran kan ti awọn ọmọ onisowo Eko, Oloye Okoya gbe sita nibi ti wọn ti n tabuku naira ni a ti ri, ti a si ti fi si ahamọ.

"Pe ọlọpaa naa wa nibẹ lasiko ti iwa yii waye ni ko bojumu, ti a ko si ni tẹwọgba rara."

Lọsẹ to kọja ni fọnran awọn ọmọ Okoya lu sita lori ayelujara, ti ọpọ si bu ẹnu atẹlu ihuwasi awọn ọmọ naa, pẹlu igbagbọ pe ko si nnkan ti ofin le se fun nitori ipo baba wọn.

Ninu fọnran naa, Wahab ati Raheem Okoya wọ agbada funfun, ti wọn fi owo han lati fi gbe wọn tuntun sita.

Bakan naa, Ọlọpaa wa ninu fọnran naa to ba wọn gbe owo naa dani, ti awọn ọmọ mejeeji si n jo si orin ti wọn kọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ọmọde lo n se wa - Raheem Okoya tọrọ aforijin fun ẹsun tita abuku si owo naira

Raheem Okoya, ọkan ninu awọn ọmọ onisowo Razaq Okoya to wa ninu fọnran to lu sita lori ayelujara ti tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun tita abuku si owo naira.

Ninu atẹjade to fi sori ayelujara X, o ni oun ko mọ pe iwa oun yoo da wahala silẹ, ti oun ko si ero buburu si owo naira .

"SI awọn ọmọ Naijiria, n ko mọ pe iwa mi yoo fa rogbodiyan bayii, mo se pẹlu ọkan mimọ.

"Mo n tọrọ fun aforijin ati atilẹyin yin lọwọ yii. Nko mọ pe iwa mi yoo lẹyin bayii."

Ta ni Razaq Okoya?

Aworan Razaq Okoya

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ògbóǹtarigì oníṣòwò, tó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Eleganza Group of Companies ni Rasaq Okoya.

Ti a ba n sọrọ nipa onisowo to lamilaka lorilẹede Naijiria, ọkan gboogi ni Razaq Okoya.

O jẹ alaga ati oludari ileeṣẹ Eleganza to wa niluu Eko.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tó dàgbà sí Nàìjíríà ní ìbẹ̀rẹ̀ 1990 ni yóò rántí dáadáa nípa àwọn ohun èlò ilé bíi àga oníke, ike ìpọnmi tàbí kúlà tó jẹ́ ti iléeṣẹ́ Eleganza.

Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni Okoya da iléeṣẹ́ náà sílẹ̀, tó sì ní ẹ̀ka káàkiri.

Wọn bi Okoya si ilu Eko ni ọjọ kejila oṣu kinni ọdun 1940 ni ile Tiamiyu Ayinde ati Idatu Okoya.

Ọdún 2025 yìí ni Okoya máa pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún lókè èèpẹ̀, tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Eko.

O lọ si ile ẹkọ alakobẹrẹ ni Absar-un-deen ni Oke Popo ni Isalẹ Eko.

O bẹrẹ lati kọ iṣẹ ransọransọ pẹlu Baba rẹ, to si ti mọ nipa iṣẹ naa ko to pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ.

Okoya ni ọpọ iyawo, to si bi ọpọ ọmọ.

Ní 1999 ni ó fẹ́ Shade Okoya tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ tó kéré jùlọ, òun sì ni ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ mọ̀-ọ́n.