Ìdí táwọn Afọbajẹ fi kọ ìwé sí Makinde tako ìkéde Ọmọọba Abimbola Owoade gẹ́gẹ́ bíi Alaafin Oyo tuntun

Aworan Omooba Abimbola Akeem Owoade

Oríṣun àwòrán, Prince Abimbola Akeem Owoade/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awuyewuye to ti n waye lori apere Alaafin Oyo fun bi ọdun meloo kan bayii tun ti gba ọna miran yọ, lẹyin ti marun un ninu awọn afọbajẹ meje Oyo tako ikede Omooba Abimbola Akeem Owoade gẹgẹ bii Alaafin Oyo tuntun.

Lọjọ Ẹti ọjọ kẹwaa oṣu kinni ọdun 2025 yii ni ijọba ipinlẹ Oyo labẹ alaṣẹ Gomina Seyi Makinde kede Omooba Owoade gẹgẹ bii Alaafin Oyo tuntun.

Atẹjade kan ti Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ipinlẹ Ọyọ buwọlu ṣalaye pe , ijọba buwọlu orukọ Ọmọọba Owoade lẹyin ti awọn Ọyọmesi fa orukọ rẹ kalẹ lẹyin igbesẹ iwadii gbogbo lọna iṣẹmbaye.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni ikede yii ti fopin gbogbo awuyewuye to n waye to fi mọ ọrọ ofin nihin-lọhun to n kaakiri lati igba ti Alaafin Ọyọ Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta ti waja lọdun 2022.

Afọbajẹ marun kọ lẹta si Makinde tako ikede Ọmọọba Abimbola Owoade gẹgẹ bii Alaafin tuntun

Ninu iwe kan ti marun un ninu awọn afọbajẹ meje kọ si Gomina Makinde ipinlẹ Oyo ni wọn ti sọ pe ikede Ọmọọba Owoade lodin sofin, ko si lee fẹsẹ mulẹ.

Awọn afọbajẹ naa fi aidunnu wọn han ninu iwe ti agbẹjọro wọn, Adekunle Sobaloju, kọ si gomina ipinlẹ Oyo.

Wọn ṣalaye ninu iwe ọhun wi pe Ọmọọba Luqman Gbadegesin lawọn afọbajẹ fọwọ si wi pe ko jọba kii ṣe Ọmọọba Owoade.

Awọn afọbajẹ naa ṣalaye wi pe yiyan ẹni ti yoo jẹ Alaafin gbọdọ wa ni ibamu pẹlu agbekalẹ ofin oye Alaafin ọdun 1967.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọn kii ṣe nipa iwadii gbogbo lọna iṣẹmbaye gẹgẹ bii Makinde ṣe sọ.

Awọn afọbajẹ naa ni Bashorun nikan to jẹ olori awọn Oyemesi lo lagbara lati dari ipade ati yan Alaafin tuntun, nitori naa, wọn ni ipade ti Makinde pe ko le fẹsẹ mulẹ tori o lodin sofin.

Awọn Afọbajẹ marun un ọhun ni Yusuf Akinade (Bashorun), Wakeel Akindele (Lagunna), Hamzat Yusuf (Akinniku), Wahab Oyetunji, Oloye to n duru fun Asipa ati Gbadebo Mufutau, Oloye to n duro fun Alapinni.

Awọn Afọbajẹ naa ṣalaye ninu iwe ti wọn fi ṣọwọ si Makinde pe ''ti ẹ o ba gbagbe, ọgbọnjọ oṣu Kẹsan an ọdun 2022 lawọn Afọbajẹ yan Ọmọọba Lukman Adelodun Gbadegesin gẹgẹ bii Alaafin Oyo tuntun lẹyin ti ọpọ awọn Afọnajẹ dibo fun un ni ibamu pẹlu alakalẹ oye Alaafin Oyo ọdun 1967.

Lẹyin tawọn Afọbajẹ dibo yan an tan ni a fi orukọ Ọmọọba Gbadegesin ṣọwọ si gomina ipinlẹ Oyo fun ibuwọlu, ṣugbọn Makinde kọ lati ṣe bẹẹ lai sọ idi.

Lẹyin naa ni awọn Afọbajẹ mori le ile ẹjọ lati da Makinde lọwọ kọ ati da eto jijẹ Alaafin tuntun ru, eyi to jẹ ki ọrọ naa de ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Bashorun to jẹ olori Oyomesi ko pe ipade kankan, bakan naa, ipade kankan ko waye laafin Oyo gẹgẹ bi aṣa ati iṣe wa ti ijọba fi kede Ọmọọba Owoade gẹgẹ bi Alaafin tuntun.

Ipade tawọn Afọbajẹ atawọn Oloye kan ba ṣe lọfiisi gomina lọjọ kẹsan an oṣu kinni ọdun 2025 lati yan Alaafin tuntun tako alakalẹ ofin oye Alaafin, ati pe o lodi sofin, ko si le fẹsẹ mulẹ.

Nitori pe kii ṣe ojuṣe gomina lati dari ipade ati yan Alaafin tuntun pẹlu awọn Afọbajẹ kan.''

Awọn Afọbajẹ marun un yii wa kepe gomina ipinlẹ Oyo lati fagile ikede Ọmọọba Owoade gẹgẹ bii Alaafin tuntun, bi bẹẹ kọọ, awọn yoo mori le ile ẹjọ.