Aráàlú àti ọlọ́pàá mọ ẹni tó pa èèyàn mẹ́rin ní Owo, kìí ṣe látọwọ́ wa - Àwọn Afunrasí

Ọrọ ileeṣẹ Ọlọpaa ati awọn afurasi tako ara wọn lori boya wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ to waye n'ilu Ọwọ tabi wọn ko mọ ohunkohun nipa rẹ.
Eniyan mẹrin lo ku nibi rogbodiyan to waye lopin ọsẹ to kọja.
Saaju ni Kọmisọna Ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Wilfred Afolabi fi oju awọn afurasi to lọwọ ninu iṣẹlẹ ọhun han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa naa to wa ni Igbatoro n'ilu Akure.
Ọga agba na sọpe ọwọ tẹ Olamide Ogunseyila ẹni ọdun mejidinlọgbon, ẹni to jẹwọ pe ẹlẹgbẹ okunkun ni ohun.
Ẹlomiran ti ọwọ tun tẹ ni Gbenga Bisi aya Stephen Dada ẹni to na papa bora nibiti wọn fara pamọ si, ti wọn si ba ibọn ati awọn ohun ija miran ninu ile naa.
Kọmisọna ọlọpaa naa sọpe ọwọ tun tẹ Ijarotimi Taye ẹni ọdun mọkanlelọgọta ti wọn ba ọgbẹ lara rẹ ti ko si le salaye bi ọgbẹ naa se de ara rẹ, eyi lo mu ko di afunrasi ninu iṣẹlẹ to waye naa.
Ọgbẹni Afolabi sọ pe ọwọ tun tẹ Bero Adeola ẹni ọgbọn ọdun ati Olabode Ojo ẹni ọgbọn ọdun bakanaa to sọ pe iyawo egbọn rẹ ati ọmọ egbọn rẹ gbẹmi mi ninu akọlu naa.
Ọga agba naa sọ pe iwadi n lọ lọwọ lati fi panpe ọba mu awọn afunrasi to ku ti wọn yoo si fi wọn jofin.
Kini awọn afuras naa sọ?
Lasiko ifọrọwerọ pẹlu meji lara awọn afurasi naa, Olamide Ogunseyila ati Olabode Ojo, wọn sọ pe awọn ko lọwọ ninu akọlu to waye.
Wọn salaye rẹ pe, ni kete ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ , awọn gbọ iroyin pe molẹbi wọn meji wa lara awọn ti wọn gbẹmi mi ninu rẹ, eyi lo mu ki wọn lọ si Aafin Ọlọwọ lati fi aidunnu wọn han lori iṣẹlẹ naa.
Wọn sọ pe ni kete ti awọn de Aafin Ọlọwọ, awọn ọlọpaa to wa nibẹ ko gba wọn laaye lati wọle, lasiko naa si ni wọn ya aworan wọn pe wọn lọwọ ninu akọlu ohun.
Lori ẹsun pe wọn jẹ ẹlẹgbẹ okunkun, wọn salaye pe wọn ti ṣe ẹgbẹ okunkun nigba kan ri, sugbọn wọn ti bura ni Ileẹjọ pe wọn ko se ẹgbẹ okunkun mọ ti eda ibura naa si wa ni Aafin Ọlọwọ.
Wọn sọ di mimọ pe ọlọpaa ko ri ibọn ni ọwọ wọn lasiko ti wọn mu wọn tako ọrọ ti ọlọpaa sọ pe wọn ba ibọn ni ọwọ awọn.
Ogunseyila ati Olabode sọ pe awọn olugbe ilu Ọwọ ati awọn Ọlọpaa mọ awọn to ṣe isẹ laabi naa ti wọn si darukọ ẹni naa.
Wọn wa ra ọwọ ẹbẹ si awọn Ọlọpaa lati se isẹ wọn ni isẹ ki wọn si mu awọn to sekupa awọn eniyan nibi wahala to waye naa.














