Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ afurasí 19 to lọ́wọ́ sí rògbòdìyàn tó wáyé nílùú Owo

Aworan Oga Ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Ondo Police

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Kọmisọna ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo Wilfred Afolabi sọ pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi mọkandinlogun to lọwọ ninu rogbodiyan to waye ni ọjọ Aje n'ilu Owo ti n se olu-ilu ijọba ibilẹ Owo.

Afolabi sọrọ yii di mimọ lasiko to sabẹwo si awọn agbegbe ti rogbodiyan ti waye nibiti eeyan mẹrin ti padanu ẹmi wọn.

Kọmisọna Ọlọpaa tuntun naa sọ pe ohun ṣe abewo si ilu Owo lati lọ ṣe imuṣẹ isede ti ijọba Ipinlẹ Ondo kede latari ikọlu to waye naa.

Ọgbẹni Afolabi fi idunnu rẹ han pe alaafia ti jọba n'iluu Owo ati agbegbe rẹ, to si kilọ fun awọn to n fa rogbodiyan lati ki ọwọ ọmọ wọn b'ọsọ.

Kọmisọna Ọlọpaa naa ṣeleri pe gbogbo awọn ti wọn fi panpẹ ọba mu naa yoo foju wina ofin.

Lara awọn agbegbe ti Afolabi ṣabẹwo si ni Eyin-Ogbe, Ijebu-Owo, agbegbe Aafin to fi mọ awọn agbegbe miran.

Hílàhílo ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn gbòde nílùú Owo, èèyàn mẹ́rín kú, ìjọba kéde ìséde

Aworan bi igboro ilu Ọwọ ṣe da paroparo.

Eniyan mẹrin lo ti gbemi mi lasiko ti rogbodiyan bẹ silẹ ni ilu Owo ti n se Olu ilu Ijọba ibilẹ Owo.

Iroyin sọ pe awọn ẹgbẹ okunkun meji to n ta kangbọn lo wa ni idi rogbodiyan naa eleyi to ti kọkọ ṣe iku pa Ọgbẹni kan ti orukọ rẹ n jẹ Fisayọ Ọladipupọ, ẹni ti wọn tọkasi gẹgẹ bi ẹni to ti fi igba kan ri jẹ olori ẹgbẹ ọdọ fun ẹgbẹ oṣelu APC nibẹ.

Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo Funmilayo Odunlami-Omisanya ẹni to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ salaye pe, eniyan mẹrin ni wọn ṣi ni akọsilẹ rẹ pe wọn gbẹ̀mí mi lasiko ti awọn ẹlẹgbẹ okunkun kọju ija si ara wọn lọjọ aje.

Ọpọlọpọ ile itaja ati dukia lo bajẹ, ti ọpọ eniyan si farapa lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.

Ki lo fa rogbodiyan yii?

Aworan bi igboro ilu Ọwọ ṣe da paroparo.

Iwadii ti asojukoroyin BBC ṣe safihan rẹ pe wahala yí bẹrẹ leyin ti awọn kan sekupa Olori awọn ọdọ teleri lẹgbẹ Oṣelu APC, Fisayo Oladipupo, tí awọn eniyan si gbagbọ pe iku oloogbe naa ni ọwọ Oṣelu ninu.

Oloogbe Oladipupo ẹni ọdun 52 jẹ gbajugbaja oloselu ni ilu Ọwọ, tí iroyin iku rẹ si jẹ kayefi nla fun gbogbo ara ilu.

Rogbodiyan to waye yi bẹrẹ ni ọjọ Aiku leyin ti awọn agbebon yinbon pa oloogbe Oladipupo.

Iṣẹlẹ naa wa di iṣu-ata yan-an yan-an lọjọ Aje bi awọn ọdọ kan ṣe wọ aarin ilu Ọwọ lati da omi alaafia ilu naa ru.

Ṣugbọn ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo ati awọn esọ alaabo miran ti ko awọn ikọ wọn lọ ilu Ọwọ lati ri daju pe opin deba iṣẹlẹ naa.

Ijọba ipinlẹ Ondo kede isede

Aworan bi igboro ilu Ọwọ ṣe da paroparo.

Lẹyin ti rògbòdìyàn yi di eyi to n mu ẹ̀mí lọ, ijọba Ipinlẹ Ondo labẹ idari Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa, kede ofin konile gbele lati asale si owurọ.

Ninu atejade latọwọ Akọwe eto iroyin si Gomina Aiyedatiwa, Ebenezer Adeniyan, ijọba pasẹ pe enikeni ko gbọdọ jade sita yàtọ̀ si awọn to n ṣiṣẹ to ṣe koko ati awọn agbofinro.

Gomina Aiyedatiwa pàṣẹ fáwọn agbofinro lati se imuṣẹ ase naa daradara lati le dabo bo ẹmi ati dukia awọn ara ilu, ki alaafia si le jọba n'ilu Ọwọ.